Uche Mac-Auley
Uche Mac-Auley (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Uchechukwu Nwaneamaka ) tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ bi Uche Obi Osotule jẹ́ gbajúgbajà òṣèré, ònkọ̀wé, olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Uche Mac-Auley | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Uchechukwu Nwaneamaka Delta State, Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Actress Writer of children story books Movie producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 1991-Present |
Notable work | 5th Floor (2017) |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeMac-Auley wá láti Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà ní Nàìjíríà. Àwọn òbí Mac-Auley jẹ́ olùkọ́ tí wọ́n sì maá n ṣiṣẹ́ káàkiri. Nítorí ìdí èyí, Mac-Auley kò gbé lójú kan fún ìgbà pípẹ́. Èyí mú kí Mac-Auley lọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ó padà parí ní ilé-ìwé Osoro Primary School, ó sì lọ sí Anglican Girls Grammar School àti Idia College fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Mac-Auley gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Delta state university.[2][3]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeA lè ṣàpèjúwe Mac-Auley bi gbajúgbajà òṣèré àti ọ̀kan nínu àwọn ẹni ìṣáájú ní agbo eré sinimá ti Nàìjíríà.[4] Mac-Auley ṣe àkọ́kọ́ ìfihàn rẹ̀ lágbo eré sinimá ti Nàìjíríà pẹ̀lú kíkópa gẹ́gẹ́ bi "Nkemji" nínu eré tẹlifíṣọ̀nù kan ti ọdún 1991 tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní Checkmate, èyítí Amaka Igwe ṣe àgbékalẹ̀ àti dídarí rẹ̀, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lu àwọn òṣèré Nollywood bíi Richard Mofe-Damijo, Norbert Young, Francis Agu, Bimbo Manuel, Kunle Bamtefa, àti Binta Ayo Mogaji. Mac-Auley ní ìsinmi ọlọ́jọ́gbọọrọ nídi iṣẹ́ òṣèré[5][6][7] láti máa kọ ìwé ìtán fún àwọn ọmọdé,[8] ṣùgbọ́n ó padà sí ìdí iṣẹ́ òṣèré ní ọdún 2016 nígbàtí ó kópa nínu fíìmù kan tí àkólé rẹ̀ jẹ́ Mid-Life.[9]
Yàtò sí ṣíṣe iṣẹ́ òṣèré, Mac-Auley tún jẹ́ ònkọ̀tàn àti agbéréjáde, ó sì ti ní lórúkọ rẹ̀, àwọn fíìmù bíi; Dangerous Twins, Sins of my Mother àti In a Lifetime.[10]
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeMac-Auley ti ṣe ìgbeyàwó lẹ́ẹ̀mejì ri. Ní àkọ́kọ́ pẹ̀lú olóòtú Obi Osotule, ẹnití ó pàdé ní ọdún 1993 nígbà tí wọ́n fi ń gbaradì fún eré Unforgiven Sin. Mac-Auley padà wá pínyà pẹ̀lú Obi Osotule ní ọdún 2002[11] kí ó tó wá fẹ́ Solomon Mac-Auley ní ọdún 2006.[12]
Orúkọ tí Mac-Auley ń lò tẹ́lẹ̀ nígbà tí Osotule síì jẹ́ ọkọ rẹ̀ ni “Uche Osotule” ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí ó fẹ́ ọkọ míràn, ó yí orúkọ rẹ̀ padà sí “Uche Mac-Auley” láti máa jẹ́ orúkọ ọkọ rẹ̀ tuntun.[13]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣe- 5th Floor (2017)
- Mid Life (2016)
- Images in the Mirror (2004)
- Saving Alero (2001)
- Thunderbolt: Magun (2001)
- Obstacles (1998)
- Another Love (1996)
- Unforgiven Sin (1993)
- Checkmate (1991)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Uche Macauley: A loaded comeback for the timeless actress". guardian.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-12-28. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ Magazine, Yes International! (2016-10-11). "A FEW THINGS THAT WILL INTEREST YOU ABOUT ACTRESS UCHE MAC-AULEY". Yes International! Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-12-28. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Men can't kill my dream – Uche Mac-auley .". www.thenigerianvoice.com. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ Haynes, Jonathan (2016). Nollywood: The Creation of Nigerian Film Genres. University of Chicago Press. pp. 335. ISBN 022638795X.
- ↑ Tide, The. "Meet Veteran Nollywood Stars Missing In Action" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Uche Mac-Auley Actress reveals reason for absence, says she's fully back to acting". www.pulse.ng. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ Atoyebi, Abiola (2016-10-18). "How time flies! 18 favorite Nollywood actors we miss on screen". www.legit.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-12-28. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Uche Mac-Auley's 'Next Uche Mac-Auley's 'Next Chapter'". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-27. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Uche Mac-Auley Actress returns to Nollywood, stars in "Mid Life"". www.pulse.ng. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Actress reveals reason for absence, says she's fully back to acting". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-02-26. Retrieved 2020-05-27.
- ↑ "Men can't kill my dream – Uche Mac-auley .". www.thenigerianvoice.com. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "#Why Uche's hubby Solomon Mac-Auley is every woman's dream". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-03-09. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Uche Mac-Auley Actress reveals reason for absence, says she's fully back to acting". www.pulse.ng. Retrieved 2019-12-28.