Hafizur Rahman Wasif Dehlavi (10 February 1910 – 13 March 1987) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè India, alárìíwísí àwọn ìwé lítíreṣọ̀ lóríṣiríṣi àti akéwì èdè Urdu, tó jẹ́ olórí Madrasa Aminia láti ọdún 1955 wọ 1979. Ó kópa nínú ètò ìgbòmìnira ti ìlú India, ó sì kọ oríṣìíríṣìí ìwé bíi Adabī bhūl bhulayyān̲, Urdū Masdar Nāmā àti Taz̲kirah-yi Sā'il. Ó ṣe àtòjọ àwọn ìwé òfin ẹ̀sìn ti bàbá rẹ̀, tí í ṣe Kifayatullah Dehlawi gẹ́gẹ́ bíi Kifāyat al-Mufti sí apá mẹ́sàn-án.

Mawlāna, Mufti

Hafizur Rahman Wasif Dehlavi
4th Rector of Madrasa Aminia
In office
September 1955 – 1979
AsíwájúAhmad Saeed Dehlavi
Àdàkọ:Infobox religious biography

Ìtàn ìgbésíayé

àtúnṣe

A bí Hafizur Rahman Wasif Dehlavi ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kejì, ọdún 1910 ní ìlú Shahjahanpur.[1] Òun ni ọmọkùnrin àkọ́bí Kifayatullah Dehlawi, tó jẹ́ Grand Mufti ti ìlú India.[1][2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Madrasa Aminia pẹ̀lú bàbá rẹ̀ Kifayatullah Dehlawi àti àwọn onímọ̀ mìíràn bíi Khuda Bakhsh àti Abdul Ghafoor Aarif Dehalvi.[3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa kíkọ èdè Lárúbáwá sílẹ̀ pẹ̀lú Hamid Hussain Faridabadi àti Munshi Abdul Ghani.[4]

Wasif jẹ́ onímọ̀ èdè, alárìíwísí àwọn ìwé lítíreṣọ̀, akéwì àti akọ̀wé òfin Islam.[5][6] Láti bíi ọmọdún márùn-úndínlógún, ní ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ ewì ní Persian. Ọ̀kan lára àwọn ewì àkọ́kọ́ rẹ̀ ní èdè Urdu ni marsiya nípa Hakim Ajmal Khan, tí ó hàn ní Al-Jamiat ti ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kìíní, ọdún 1928 .[7]

Wasif bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ èdè Lárúbáwá àti ìwé lítíreṣọ̀ ní Government of Delhi's education department.[8] Ní ọdún 1936, bàbá rẹ̀ fi sípò olùdarí Kutub Khana Rahimiya.[8] Wọ́n yàn án sípò igbá-kejì rector Madrasa Aminia ní ọdún 1953.[8] Ó di rector ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 1955, ó sì dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní ọdún 1979.[9] Ó di olóògbé ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹta, ọdún 1987 ní ìlú Delhi.[2]

Àwọn ìwé lítíreṣọ̀ rẹ̀

àtúnṣe

Wasif ṣe àtòjọ àwọn ìwé òfin ẹ̀sìn ti bàbá rẹ̀, tí í ṣe Kifayatullah Dehlawi gẹ́gẹ́ bíi Kifāyat al-Mufti sí apá mẹ́sàn-án.[10] Àwọn iṣẹ́ Wasif mìíràn ni:[10]

  • Adabī bhūl bhulayyān̲: zabān-o-qawā'id aur Urdū imlā par tanqīd
  • Jamī'at-i Ulamā par ek tārīk̲h̲ī tabṣirah (A book discussing the history of Jamiat Ulama-e-Hind and its establishment)
  • Sih lisānī Masdar Nāmā (Dictionary of Urdu verbs with their Arabic and Persian equivalents)
  • Taz̲kirah-yi Sā'il (Biography of Saail Dehalvi)
  • Urdū Masdar Nāmā
  • Zar-i gul (Poetic collection)

Bibliography

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Shahjahanpuri 2005, pp. 105-106.
  2. 2.0 2.1 Adrawi 2016, p. 82.
  3. Dehlavi 2011, p. 19.
  4. Dehlavi 2011, p. 20.
  5. Amini 2017, p. 177.
  6. Dehlavi 2011, p. 22.
  7. Dehlavi 2011, p. 44.
  8. 8.0 8.1 8.2 Dehlavi 2011, p. 24.
  9. Dehlavi 2011, pp. 25-26.
  10. 10.0 10.1 Amini 2017, pp. 210-211.