Àjẹsára ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A jẹ́ àjẹsára tó má a n dènà ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A.[1] A má a ṣiṣẹ́ lára iye àwọn ènìyàn tó fẹ́rẹ̀ tó 95% nínú àwọn tó gbàá, agbára rẹ̀ a sì má a wà fún ìgbà tó tó, ó kéré jù, ọdún mẹ́ẹ̀dógún, tó bá sì ṣeé ṣe, jálẹ̀ ìgbé-ayé ènìyàn.[2][1] Bí a bá fifúnni, ìwọ̀n egbògi náà méjì ni a dámọ̀ràn, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ènìyàn bá ti ju ọmọ ọdún kan lọ. À n fúnni gẹ́gẹ́ bí abẹ́rẹ́ tí a gún sínú ẹran ara.[1]

Àjẹsára ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gba ni nímọ̀ràn láti fún gbogbo ènìyàn tí n gbé agbègbè ibití àrùn náà ti wọ́pọ̀ díẹ̀ ní àjẹsára náà. Níbití àrùn náà ti wọ́pọ̀ púpọ̀, a kò gbani nímọ̀ràn láti fún àwọn ènìyàn ní àjẹsára náà nítorí tí gbogbo ènìyàn ibẹ̀ a má a sábà ní agbára àti kojú àrùn náà nípasẹ̀ àkóràn àrùn náà tí wọ́n ti ní nígbàtí wọ́n jẹ́ ọmọdé.[1] Ilé-iṣẹ́ fún Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn (CDC) gba ni nímọ̀ràn láti fún àwọn àgbàlagbà tó wà lábẹ́ ewu nlá láti ní àrùn náà, àti gbogbo àwọn ọmọdé, ní àjẹsára náà.[3]

Àtúnbọ̀tàn tó ní ipá kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ìnira ní ojú ibi àbẹ́rẹ́ náà a má a wáyé lára àwọn ọmọdé tó tó 15% àti lára ìdajì nínú àwọn tó gbàá. Púpọ̀ lára àwọn àjẹsára ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A ni wọ́n ní kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti pa nínú, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn díẹ̀ mìíràn ní kòkòrò afàìsàn náà ti a ti sọ di aláìlágbára nínú. Àwọn tó ní kòkòrò afàìsàn náà ti a ti sọ di aláìlágbára nínú ni a kò gbani nímọ̀ràn láti fún aboyún tàbí àwọn tí agbára àti kojú àìsàn wọn kò bá múnádóko. Díẹ̀ lára àwọn àgbéjáde egbògi yìí jẹ́ àdàlù àjẹsára ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A pẹ̀lú àjẹsára ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B tàbí àjẹsára ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀.[1]

A fọwọ́sí àjẹsára ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ọdún 1991, àti ní ilẹ Amẹ́ríkà ní ọdún 1995.[4] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[5] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ láàárín 50 sí 100 USD.[6]

References

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "WHO position paper on hepatitis A vaccines – June 2012."
  2. Ott JJ, Irving G, Wiersma ST (December 2012).
  3. "Hepatitis A In-Short".
  4. Patravale, Vandana; Dandekar, Prajakta; Jain, Ratnesh (2012).
  5. "19th WHO Model List of Essential Medicines (April 2015)" (PDF).
  6. Hamilton, Richart (2015).