Yinka Quadri

Òṣèré orí-ìtàgè
(Àtúnjúwe láti Yínká Quadri)

Alhaji Àkàní Ọláyínká Quadri tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kọkànl, ọdún 1959 ( 6-9-1959). jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, Olùgbéré jáde àti adarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n bi tí ó sì dàgbà sí àdúgbò Lagos Island ní ìpínlẹ̀ Èkó. Àmọ́ tí ọ́ jẹ́ baba àti Ìyá rẹ̀ wá láti ìlú ÒróÌpínlẹ̀ Kwara. Òun ni wọ́n fi jẹ oyè Àgbà Akin ti Ìlú Òró. Òun ni Olùdásílẹ̀ Ilé-ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ni ní eré oníṣe tí wọ́n pè ní (Ọdúnfá Caucus) tí ó kalẹ̀ sí Ìlú Ebute-Meta ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Yinka Quadri
Ọjọ́ìbíAkanni Olayinka Quadri
6 Oṣù Kẹ̀sán 1959 (1959-09-06) (ọmọ ọdún 65)
Lagos Island, Lagos State, Nigeria[1]
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́1976–present
Gbajúmọ̀ fúnKura Matete

Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí yínká nínú ẹbí kòlàkò-ṣagbe tí àwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìgbómìnà-OwóméjeÌpínlẹ̀ Kwara. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti St. Catoliic, tí ó wà ní Ìdúmàgbò, Ilé-ẹ̀kọ́ Girama tí ó wà ní Èbúté Ọlọ́fin ní Ìpínlẹ̀ Èkó kan náà.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Òṣèré

àtúnṣe

Yínká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré orí-ìtàgé ní ọdún 1976, Òun àti Taiwo Ọláyínká àti àwọn mìíràn tí wọ́n jọ bẹ̀rẹ̀ eré nígbà náà lábẹ́ Ilé iṣẹ́ ìgbéré-jáde Àfòpiná lẹ́yìn tí wọn Ko lè tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn mọ́.[2] Yínká ti kópa nínú eré oníṣe orí ìtàgé tí ó ju àádọ́rùún lọ, àti eré àtìgbà-dégbà ọlọ́sọọ̀sẹ̀ tí oríṣiríṣi, àmọ́ èyí tí ó gbajúmọ̀ jùlọ niAgbódórogun.[3][4]

Lára fíímù tó ti kópa

àtúnṣe
  • Ọláníyọnu
  • Kutupu
  • Kúrá
  • Ẹkùn
  • Agbódórógun'
  • Òjìji
  • Egbìnrìn Ọ̀tẹ̀
  • Àràbà
  • Ìlàrí
  • Ọdún nbákú
  • Bólóde Ò'kú
  • Èébúdọlá Tèmi
  • Abẹ̀ní
  • Àpáàdì
  • Ọjọ́ Ìdájọ́
  • Abulẹ̀ṣowó
  • Níwòyí Ọ̀la
  • Ilẹ̀kùn Ọlọ́run
  • Okini

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

àtúnṣe
Year Award ceremony Prize Result
2007 3rd Africa Movie Academy Awards Best Actor in a Supporting Role Wọ́n pèé
2010 2010 Best of Nollywood Awards Best Indigenous Actor in a Lead Role (Yoruba) Wọ́n pèé
2012 2012 Nollywood Movies Awards Best Actor in an Indigenous Movie (Non-English speaking language) Wọ́n pèé
2013 2013 Best of Nollywood Awards Best Supporting Actor in a Yoruba film Wọ́n pèé
2014 2014 Best of Nollywood Awards Best Actor in Leading Role (Yoruba) Wọ́n pèé

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe