Yemi Adesanya jẹ́ òǹkọ̀wé, oníṣirò-owó ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ The Arts & Civics Table (TACT).[1] Ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ ni Musings of a Tangled Tongue.[2][3]

Yemi Adesanya
Orúkọ àbísọJọ́láóyẹmí Doyinsọ́lá Ọlátúbọ̀sún (Ọ̀ládàpọ̀)
Ọjọ́ìbíIbadan, Oyo State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́Ondo State University, University of Leicester
Iṣẹ́Banker, writer, accountant
Parent(s)Olatubosun Oladapo

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Orúkọ àbísọ rẹ̀ ni Jolaoyemi Doyinsola Olatubosun, wọ́n sì bi sínú ìdílé elénìyàn mẹ́jọ. Ó lọ ilé-ìwé ní Ìbàdàn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àti ní Àkùngbá, ní Ìpínlẹ̀ Òndó, ní Nàìjíríà.[4][5]

Àṣààyàn ewì rẹ̀ àtúnṣe

Ewì tí Adesanya kọ́kọ́ kọ ni àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Musings of a Tangled Tongue, èyí tí wọ́nṣàgbéjáde ní ọdún 2016, láti ọwọ́ Kiibaati Resources Limited. Ìwé náà ní ewì mẹ́rìnléláàádọ́ta (54), ó sì ní ju ojú-ewé ọgófà lọ.[6]

Ìṣèdásílè géèmù oní-káàdì àtúnṣe

Ní ọdún 2014, Yemi ṣe ìdásílẹ̀ géèmù oní-káàdì méjì. Alákọ̀ọ́kọ́ ni The Game of Giants, èyí tó máa ń kọ́ ni nípa ìtàn lọ́nà tó ládùn.[7][8] Ó sì tún dábàá ọludé ní Nàìjíríà.[9]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Nigerian Satire Festival births in Abuja". The Guardian. 11 November 2017. 
  2. "Musings of a Tangled Tongue". www.goodreads.com. Retrieved 2017-11-20. 
  3. Amazon.com: Musings of a Tangled Tongue: Prittle-prattle and pickled poems eBook: Yemi Adesanya: Kindle Store. https://www.amazon.com/Musings-Tangled-Tongue-Prittle-prattle-pickled-ebook/dp/B01DS2RMFM. Retrieved 2017-11-20. 
  4. "Accountancy Careers in the Isle of Man – Find your dream job in the Isle of Man" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-08-13. Retrieved 2020-01-22. 
  5. "Request Catalogue - Online MSc International Business with Law | Robert Kennedy College". salford.rkc.edu. Retrieved 2020-01-22. 
  6. "A Witty Play on Words in Yemi Adesanya's Musings of a Tangled Tongue" (in en-US). Bagus Mutendi. 8 May 2017. Archived from the original on 2018-03-29. https://web.archive.org/web/20180329155010/http://www.bagusmutendi.com.ng/2017/05/08/a-witty-play-on-words-in-yemi-adesanyas-musings-of-a-tangled-tongue/. 
  7. "On The Game of Giants" (in en-US). ktravula – a travelogue!. 24 June 2014. Archived from the original on 2017-11-15. https://web.archive.org/web/20171115201039/http://www.ktravula.com/2014/06/on-the-game-of-giants/. 
  8. "Loading...". takeyourprizesnow3.life. Archived from the original on 2020-02-05. Retrieved 2020-02-06. 
  9. "Nigerians Need New Rituals, By Yemi Adesanya" (in en-US). Premium Times Opinion. 1 July 2017. https://opinion.premiumtimesng.com/2017/07/01/nigerians-need-new-rituals-by-yemi-adesanya/.