Yemisi Ransome-Kuti
Yemisi Ransome-Kuti ni ó jẹ́ ọmọ kan ṣoṣo ardbìmrin Azariah Olusegun Ransome-Kuti MBE (tí wọ́n yàn sípò as Ọ̀gá agbà onímọ̀ ìpoògùn fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1956 tí ó sì ṣiṣẹ́ títí di ó fi fẹ̀yìn tì ní ọdún 1951 Member of the Most Excellent Order of the British Empire láti ọwọ́ King George VI). Bákan náà ni ó tún jẹ́ ọmọ ọmọ Rev. Canon Josiah Ransome-Kuti.[1] Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Chief Funmilayo Ransome-Kuti ni ó jẹ́ ajàfẹ́tó awọn obìnrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ó wà lára àwọn tí wọ́n lọ sọrọ̀ nípa ìgbòmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ àwọn Briteni.
Ransome-Kuti jẹ́ ìbátan obìnrin Fela Kuti, Olikoye Kuti, Beko Ransome-Kuti ati Nobel Prize for Literature Wole Soyinka, tí ìyá rẹ̀ náà jẹ́ Ransome-Kuti.[1] Yemisi bí ọmọ mẹ́rin tí Segun Bucknor jẹ́ akọ́bí rẹ̀ láti ọdọ̀ ọkọ àkọ́kọ́ rẹ̀ (Captain Frederick Oluwole Bucknor), bákan náà ni ó bí mẹ́ta fún ọkọ rẹ̀ kejì Dr Kunle Soyemi - Bola Soyemi, Seun Soyemi àti Eniola Soyemi. Látàrí wípé Fela Kuti, Beko Kuti ati Koye Kuti ti ṣaláìsí, Yemisi ni ó jẹ́ olórí ẹbí fún Ransome-Kuti.
Ó fẹ̀yìn tì gẹ́gẹ́ bí alága fún Nigerian Network of Non-Governmental Organizations (NNNGO), ajọ tí ó dá sílẹ̀ fúnra rẹ̀.[2] Àjọ irú rẹ̀ tí ó jẹ́ akọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ti ń ṣiṣẹ́ láti mú ìṣọ̀kan bá àwọn àjọ abẹ́lé ati ilẹ̀ òkèrè láti ọdún 1992. Lásìkò ọdún 1990, ó dá àjọ "Girl Watch" kalẹ̀, àjọ tí ó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2006, wọ́n yàn án sípò olùdámọ̀ràn pàtàkì Civil Society lábẹ́ àjọ World Bank. Yẹ́misí wà lára àwọn ìkan pàtàkì obìnrin tí wọ́n sapá láti mú ìdàgbà-sókè bá iṣẹ́ SDGs léte àti lé òṣì òun ìgbẹ́ sọ̀vbẹ́ láwùjọ.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Sansom, Ian (11 December 2010). "Great Dynasties: The Ransome-Kutis". Theguardian.com. Retrieved 14 February 2019.
- ↑ Carlos Moore (1 August 2011). Fela: This Bitch of A Life. Omnibus Press. p. 18. ISBN 978-0-85712-589-7. https://books.google.com/books?id=_iqFZuXyK_4C&pg=PT18.
- ↑ Kate (22 July 2016). "Yemisi Ransome-Kuti can die fighting injustice". Feminine.com.ng. Retrieved 14 February 2019.