Yinka Quadri
Alhaji Àkàní Ọláyínká Quadri tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kọkànl, ọdún 1959 ( 6-9-1959). jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, Olùgbéré jáde àti adarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n bi tí ó sì dàgbà sí àdúgbò Lagos Island ní ìpínlẹ̀ Èkó. Àmọ́ tí ọ́ jẹ́ baba àti Ìyá rẹ̀ wá láti ìlú Òró ní Ìpínlẹ̀ Kwara. Òun ni wọ́n fi jẹ oyè Àgbà Akin ti Ìlú Òró. Òun ni Olùdásílẹ̀ Ilé-ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ni ní eré oníṣe tí wọ́n pè ní (Ọdúnfá Caucus) tí ó kalẹ̀ sí Ìlú Ebute-Meta ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Yinka Quadri | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Akanni Olayinka Quadri 6 Oṣù Kẹ̀sán 1959 Lagos Island, Lagos State, Nigeria[1] |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 1976–present |
Gbajúmọ̀ fún | Kura Matete |
Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí yínká nínú ẹbí kòlàkò-ṣagbe tí àwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìgbómìnà-Owóméje ní Ìpínlẹ̀ Kwara. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti St. Catoliic, tí ó wà ní Ìdúmàgbò, Ilé-ẹ̀kọ́ Girama tí ó wà ní Èbúté Ọlọ́fin ní Ìpínlẹ̀ Èkó kan náà.
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Òṣèré
àtúnṣeYínká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré orí-ìtàgé ní ọdún 1976, Òun àti Taiwo Ọláyínká àti àwọn mìíràn tí wọ́n jọ bẹ̀rẹ̀ eré nígbà náà lábẹ́ Ilé iṣẹ́ ìgbéré-jáde Àfòpiná lẹ́yìn tí wọn Ko lè tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn mọ́.[2] Yínká ti kópa nínú eré oníṣe orí ìtàgé tí ó ju àádọ́rùún lọ, àti eré àtìgbà-dégbà ọlọ́sọọ̀sẹ̀ tí oríṣiríṣi, àmọ́ èyí tí ó gbajúmọ̀ jùlọ niAgbódórogun.[3][4]
Lára fíímù tó ti kópa
àtúnṣe- Ọláníyọnu
- Kutupu
- Kúrá
- Ẹkùn
- Agbódórógun'
- Òjìji
- Egbìnrìn Ọ̀tẹ̀
- Àràbà
- Ìlàrí
- Ọdún nbákú
- Bólóde Ò'kú
- Èébúdọlá Tèmi
- Abẹ̀ní
- Àpáàdì
- Ọjọ́ Ìdájọ́
- Abulẹ̀ṣowó
- Níwòyí Ọ̀la
- Ilẹ̀kùn Ọlọ́run
- Okini
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeYear | Award ceremony | Prize | Result |
---|---|---|---|
2007 | 3rd Africa Movie Academy Awards | Best Actor in a Supporting Role | Wọ́n pèé |
2010 | 2010 Best of Nollywood Awards | Best Indigenous Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé |
2012 | 2012 Nollywood Movies Awards | Best Actor in an Indigenous Movie (Non-English speaking language) | Wọ́n pèé |
2013 | 2013 Best of Nollywood Awards | Best Supporting Actor in a Yoruba film | Wọ́n pèé |
2014 | 2014 Best of Nollywood Awards | Best Actor in Leading Role (Yoruba) | Wọ́n pèé |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ BUKOLA BAKARE. "Nnebue produced 27 Yoruba films before Living in Bondage - nigeriafilms.com". nigeriafilms.com. Retrieved 5 February 2016.
- ↑ Alabi, Ajibade (10 May 2014). "Why I dropped out of school – Yinka Quadri". Newswatch Times. http://www.mynewswatchtimesng.com/dropped-school-yinka-quadri/. Retrieved 4 February 2016.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Yinka Quadri: What people don’t know about me and Ogogo". Per Second News. 29 April 2014. Archived from the original on 5 February 2016. https://web.archive.org/web/20160205021113/http://www.persecondnews.com/index.php/sport/item/994-yinka-quadri-what-people-dont-know-about-me-and-ogogo. Retrieved 4 February 2016.
- ↑ "ENCOMIUMS, AS YINKA QUADRI LAUNCHES BIOGRAPHY, CELEBRATES 36 YEARS ON STAGE". Ecomium Magazine. 12 May 2014. Archived from the original on 11 June 2017. https://web.archive.org/web/20170611102056/http://encomium.ng/encomiums-as-yinka-quadri-launches-biography-celebrates-36-years-on-stage/. Retrieved 4 February 2016.