Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Sámbíà

Àjàkálẹ̀ Àrùn rùn COVID-9 wọ orílẹ̀-èdè Zambia ní inú oṣù Kẹ́ta ọdún 2020. [2]

Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-9 ní orílẹ̀-èdè Zambia
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiZambia
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, China
Index caseLusaka
Arrival date18 March 2020
(4 years, 9 months, 1 week and 5 days)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn3,583 (as of 21 July)[1]
Active cases1,778 (as of 21 July)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá1,677 (as of 21 July)
Iye àwọn aláìsí
128 (as of 21 July)

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kíní ọdún 2020, Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí .[3][4]

Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003.[5][6]Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìtànkálé àrùn COVID-19 ń gbópọn si lójojúmọ́ tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpò ènìyàn lágbáyé. [7]

Àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan tí ó ń ṣẹlẹ̀

àtúnṣe

Oṣù kẹ́ta ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta, ìjọba orílẹ̀-èdè Zambia ti ti gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ láti obẹ̀rẹ̀ dé ibi tí ó dé, tí wọ́n sì ti fi àwọn ààlà kọ̀ọ̀kan sí ìrìn-àjò àwọn àrìnrì-àjò tí ó fẹ́ wọlé sí orílẹ̀-èdè wọn láti àwọn rílẹ̀-èdè ìlú òkèrè tàbí jáde kúrò níbẹ̀. [8]. Orílẹ̀-èdè nZambia ní akọsílẹ̀ àrùn COVID-9 méjì akọ́kọ́ lára àwọn aláàrẹ̀ méjì tí wọ́n jẹ́ tọkọ-taya ní ìlú Lusaka ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún 2020.[9]Wón tún rí àwọn ènìyàn méjìlélógún tí ó ní àrùn Kòrónà lẹ́yìn tí wọ́n darí ìrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè Pakistan.[10] Ní ọ́jọ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Zambia ọ̀gbẹ́ni Edgar Lungu fìdí àwọn ènìyàn méjìlá mìíràn tí wọ́n tún ní àrùn Kòrónà múlẹ̀ nígbà tí ó ń bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ sọ̀rọ̀.[11] Nínú oṣù kẹ́ta, àwọn ènìyàn mẹ́rìndínlógójì tí wọ́n ní àrùn Kòrónà. [12]

Oṣù kẹrin ọdún 2020

àtúnṣe

Orílẹ̀-èdè Zambia kéde ikú aláàrẹ̀ Kòrónà akọ́kọ́ ní ọjọ́ kejì oṣù kẹrin ọdún 2020.[13]Lápapọ̀, àwọn ènìyàn ogóje ni wọ́n ṣàyẹ̀wò fún tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n ní àrùn Kòrónà nínú oṣù yí, tí ó mú kí iye àwọn aláàrẹ̀ náà lápapọ̀ ó jẹ́ mẹ́fàlélọ́gọ́rùún nígbà tí àwọn mẹ́ta ṣe aláìsí. Àwọn tí ó kù tí wọn kò kú tí wọn kò sì íì rí ìwòsàn gbà jẹ́ méjìdínláàdọ́ta nínú oṣù kẹ́rin.[14]

Oṣù Karùún ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ọjọ́ Karùún oṣù Karùún, ẹlòmíràn náà tún papò dà tí ó mú kí iye àwọn àláàrẹ̀ àrùn COVID-9.[15] Nígbà tí ó fi máa di ọjọ́ kejìlélógún oṣù Karùún, iye àwọn tí wọ́n ti ní àrùn Kòrónà ti di àádọ́sàán ó lé ogún. [16][17] Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, Zambia ti ní akọsílẹ̀ tí ó ti tó ọgọ́rùún kan ati mẹ́tàlélọ́gbọ̀n láàrín ọjọ́ márùún. Tí ó mú kí gbogbo rẹ̀ ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́tàdínlọ́gọ́ta. Akọ̀wé àgbà fún orílẹ̀-èdè Zambia Dr. Simon Miti náà fẹnu si wípé ọgọ́rùún mẹ́rin ati mẹ́tàlélógójì ènìyàn ni ó ti rí ìwòsàn gbà tí wọ́n sì ti padà sí ilé wọn. Nígbà tí àwọn méje papò dà tí àwọn ọgọ́rùún méjì ati mọ́kanléláàdọ́rin ṣì ní àìsàn COVID-9 ní ìparí oṣù Karùún.[18]

Oṣù kẹfà ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà, ìjọba orílẹ̀-èdè Zambia buwọ́ lu iye owó tí ó tó bílíọ́nù mẹ́jọ Kwacha (US$439 million) owó ilẹ̀ Zambia, láti fi ṣúgbàá tu àwọn 9mọ orílẹ̀-èdè Zambia lára.[19] Iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó 437 ni wọ́n tún ṣàwárí wọn nínú oṣù yí, àwọn aláàrẹ̀ mẹ́rìnlélógún ni wọ́n papò dà, ní ìparí oṣù kẹfà. [20]

Ipa tí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-9 kó nípa ètò-ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kẹ́ta, ìjọba orílẹ̀-èdè Zambia kéde wípé kí w9n ó ti gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ pátá láti ọjó Jímọ̀ ogúnjọ́ oṣù kẹ́ta. [21] Ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ilẹ̀ Zambia (ZNBC) tí ọ̀gbẹ́ni David Mabumba ń ṣojú fún kéde wípé ilé-iṣẹ́ náà yóò gbé ìkànnì kan kalẹ̀ tí yóò wà fún kíkọ́ àwọn akẹ́kòọ́ ní ẹ̀kọ́ ní àsìkò ìséni-mọ́lé, láti dẹ́kuun ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9. Ìkanì náà yóò sì bẹ́réẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kẹtalá oṣù kẹ́rin ọdún 2020.

Ọ̀gbẹ́ni Mabumba tún fi kun wípé àwọn yóò pèsè ìlànà ìkẹ́kọ́ mìíràn fún ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tí wọn kò ní ànfaní láti lo ẹrọ amóhùn-máwòrán. Ìjọba yóò tún máa lo ẹrọ asọ̀rọ̀-mágbèsí, ẹ̀rọ ayélujára láti lè jẹ́ kí àwọn ògo wẹrẹ ó lè ní ànfaní sí ètò ẹ̀kọ́-ẹ̀fọ́ náà. [22]

Pípàṣẹ wàá

àtúnṣe

Wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn aláṣẹ ìjọba Zambia wípé wọ́n ń lo Ìbúrẹ́kẹ́ ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9 láti fi sọ ara wọn di ìjọba apàṣẹ wàá, nípa lílòdì sí òfin ìjọba ilẹ̀ Zambia tí ó sọ orílẹ̀-èdè Zambia di orílẹ̀-èdè olóṣèlú ìjọba àwa-ara wa by bí ìjọba ṣe fagilé ìjókòó àwọn ìgbìmọ̀ aṣòfin tí ó yẹ́ kí wọ́n ṣe ayípada sí òfin tí yóò fẹsẹ̀ ìjọba àwa arawa múlẹ̀ ṣinṣin , àti bí ìjọba ṣe ti ilé-iṣẹ́ amóhù-máwòrán tí ó jẹ́ ti aládáni tí kò fi ànfaní sílẹ̀ fún Pìpolongo nípa ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9 lọ́fẹ́. [23]

Ẹ tún lè wo

àtúnṣe

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Worldometers - Zambia Coronavirus Tracker". Retrieved 2020-07-18. 
  2. Chilufya, Chitalu (17 March 2020). "PRESS BRIEFINGON COVID-19". Ministry Of Health, Zambia.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus. 
  5. "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "Government shuts all schools to prevent COVID-19 outbreak". News Diggers. 17 March 2020. https://diggers.news/local/2020/03/17/govt-shuts-all-schools-to-prevent-covid-19-outbreak/. Retrieved 2020-03-17. 
  9. "Zambia Confirms 2 Covid-19 cases". News Diggers. 18 March 2020. https://diggers.news/breaking/2020/03/18/zambia-confirms-2-covid-19-cases/. Retrieved 2020-03-18. 
  10. "Zambia confirms third coronavirus case". News Diggers. 22 March 2020. https://diggers.news/breaking/2020/03/22/zambia-confirms-third-coronavirus-case/. Retrieved 2020-03-22. 
  11. "Lungu's full address: Zambia confirms 12 COVID-19 cases as lock down looms". News Diggers. 25 March 2020. https://diggers.news/local/2020/03/25/lungus-full-address-zambia-records-12-covid-19-cases-as-lock-down-looms/. Retrieved 2020-03-25. 
  12. "Broken economy and the Coronavirus, a double tragedy for Zambia". The Mast. 3 April 2020. https://www.themastonline.com/2020/04/03/broken-economy-and-the-coronavirus-a-double-tragedy-for-zambia/. Retrieved 2020-06-30. 
  13. "Ministry of Health Zambia". www.facebook.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-04-02. 
  14. "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 102" (PDF). World Health Organization. 1 May 2020. p. 6. Retrieved 30 June 2020. 
  15. Lusaka Times (5 May 2020). "Fourth COVID-19 Death recorded in Zambia". Lusakatimes.com.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  16. Lungu, Edgar (22 May 2020). "Fifth Address To The Nation On COVID-19 By His Excellency, Dr,Edgar Chagwa Lungu, President Of Republic Of Zambia". State House Press Office - Zambia - Facebook. Retrieved 24 May 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  17. Lungu, Edgar (22 May 2020). "5th National Address On COVID-19 His Excellency,Dr Edgar Chagwa Lungu, President Of The Republic Of Zambia -22nd May 2020" (PDF). State House. Archived from the original (PDF) on 28 May 2020. Retrieved 24 May 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  18. Miti, Simon (27 May 2020). "Now it's Chilufya". Zambia Daily Mail. 
  19. "News and Insights". www.nasdaq.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-27. 
  20. "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 163" (PDF). www.who.int (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 1 July 2020. p. 6. Retrieved 2020-07-02. 
  21. "Zambia : Zambia to shut down all schools this Friday as Coronavirus outbreak looms". LusakaTimes.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-24. 
  22. "ZNBC TO OPEN EDUCATIONAL CHANNEL". znbc (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-06-08. Retrieved 2020-05-24.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  23. "In Zambia, Covid-19 has claimed democracy, not human life". The Mail & Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-06-15. Retrieved 2020-06-15. 

Àdàkọ:COVID-19 pandemic