Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Guinea
Wọ́n kéde àrùn ẹ̀rànkòrónà, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Covid-19 lórílẹ̀-èdè Guinea lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 2020.[3]
Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Guinea | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Guinea |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Index case | Conakry |
Arrival date | Ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 2020 (4 years, 8 months and 2 weeks) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 6,544 (as of 19 July)[1][2] |
Active cases | 996 (títí di ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù keje) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 5,511 (títí di ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù keje)[2] |
Iye àwọn aláìsí | 39 (títí di ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje)[2] |
Official website | |
http://www.anss-guinee.org/ |
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
àtúnṣeLọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni àjọ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) jẹ́rìí pé ẹ̀rànkòrónà, Covid-19, ni ó ń fa àìsàn èémí láàárín àwọn ènìyàn kan lágbègbè Wuhan,ní Ìpínlẹ̀ Hubei, lórílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ̀ fún àjọ WHO lọ́jọ́ kokànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019.[4][5]
Iye ìjàm̀bá ikú àrùn Covid-19 kéré sí ti àrùn SARS, Severe acute respiratory syndrome tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 2003,[6][7] ṣùgbọ́n jíjàkálẹ̀ àrùn náà lágbára ju SARS lọ, pàápàá jù lọ iye àwọn ènìyàn tí àrùn náà ń pa lápapọ̀..[8][6]
Bí ó ṣe ń jàkáalẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà
àtúnṣeMarch 2020
àtúnṣeLọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 2020 èsì àyẹ̀wò fihàn pé arákùnrin kan, ọmọ orílẹ̀ èdè Belgium, tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ European Union, tí ó wá ṣe àbẹ́wò lórílẹ̀-èdè Guinea ní àrùn Covid-19. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó ní àrùn náà ni lórílẹ̀-èdè náà.[9][10]
Nígbà tí ó yá, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn náà pọ̀ sí ní ìlọ́po méjì láti mẹ́jọ sí mẹ́rìndínlógún lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2020.[11]
Oṣù karùn-ún
àtúnṣeÌṣẹ̀lẹ̀ láabí kan ṣẹlẹ̀ lóṣù karùn-ún ní Guinea, àwọn ọlọ́pàá pa àwọn mẹ́fà nínú àwọn afẹ̀hónúhàn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ìgbòkègbodò ọkọ̀ ni ìlú Coyah àti Dubreka. Agbẹnusọ àwọn ọlọ́pàá, Mory Kaba wí àwíjàre pé àwọn afẹ̀hónúhàn náà ń fẹ̀hónú hàn nítorí ṣíṣe àyẹ̀wò ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti àwọn ènìyàn láti lè gbégi Dínà ìtànkálẹ̀ àrùn Covid-19, ṣùgbọ́n àwọn afẹ̀hónúhàn náà takò wọ́n pè èyí kò rí bẹ́ẹ̀, wípé àwọn n ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn nítorí owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá náà ń gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.[12]
Ẹ yẹ̀yí wò
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "ANSS". anss-guinee.org. Retrieved 2020-07-14.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 "Worldometer - Guinea". worldometer. Retrieved 2020-07-14.
- ↑ "Guinea reports first confirmed COVID-19 case". www.aa.com.tr. Retrieved 2020-05-25.
- ↑ Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus.
- ↑ 6.0 6.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "EU employee tests positive for coronavirus in Guinea's first case". Reuters. 13 March 2020.
- ↑ "Sudan, Guinea record first cases of coronavirus". africanews.com. 13 March 2020.
- ↑ Guinee360 (2020-03-29). "Covid-19: Des nouveaux cas enregistrés ce dimanche à Conakry". Guinee360.com - Actualité en Guinée, toute actualité du jour (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-03-29.
- ↑ "Guinea: Six protesters killed in clashes with police". Al Jazeera English. May 13, 2020. https://www.aljazeera.com/news/2020/05/guinea-protesters-killed-clashes-police-200513071249521.html?utm_source=dailybrief&utm_medium=email&utm_campaign=DailyBrief2020May13&utm_term=DailyNewsBrief.