Àjàlá Arìnrìn-àjò / Àjàlá the Traveller tí orúkọ àbísọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Moshood Adisa Olabisi Ajala àmọ́ tí gbogbo ayé mọ̀ sí àjàlá travel jẹ́ akọ̀ròyìn, òǹkọ̀wé, òṣèrékùnrin àti gbàjúmọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó jẹ́ ìlú-mọ̀n-ọ́n-ká látàri àwọn ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí Israel, Egypt, Palestine, India, Orílẹ̀ èdè America àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó tẹ̀ jáde ní àkọ́lé rè ń jẹ́ An African Abroad tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 1963. Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ìtàn nípa ìrìn-àjò rẹ̀. Wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ yìí "Aj̀àlá travel" fi bú àwọn ènìyàn tí kò kì í jókòó sójú kan, tàbí tó máa ń rin ìrìn-àjò lóòrè-kóòrè.

Olabisi Ajala
Fáìlì:Ajala on his scooter.jpg
Background information
Orúkọ àbísọMoshood Adisa Olabisi Ajala
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiAjala the traveller
Ọjọ́ìbí(1934-04-03)Oṣù Kẹrin 3, 1934
Ghana
Ìbẹ̀rẹ̀Lagos, Nigeria
AláìsíFebruary 2, 1999(1999-02-02) (ọmọ ọdún 64)
Health facility, Lagos, Nigeria
Occupation(s)Journalist, Travel Writer
Years active1957-1999

Ìgbésí ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Olabisi sí orílẹ̀-èdè Ghana ní ọdún 1929[1] tàbí 1934[2] sí ìdílé kan ní Nàìjíríà. Ìdílé olórogún ni ìdílé náà, tó kún fún ọmọ ọgbọ̀n àti ìyàwó mẹ́rin.[3] Olabisi jẹ́ ọmọ karùndínlọ́gbọ̀n.[4] Ìgbà tí ó wà ní èwé, àwọn òbí rẹ̀ kó lọ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ibẹ̀ ni ó ti lọ aí ilé-ìwé Baptist AcademyÈkó àti Ibadan Boys’ High School ní Ibadan.

Ìgbà tó wà ní ọmọdún méjìdínlógún, ó lọ sí United States láti lọ kàwé nípa ìmọ̀-ìṣègùn[5] ní University of Chicago. TNíbẹ̀, òun ní ọmọ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹgbẹ́ Delta Upsilon Pi ‘fratority’.[6] Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Roosevelt University láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ Psychology.

Àwọn orílẹ̀-èdè tó dé rí àtúnṣe

Orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínláàádọ́run (87) ni Ajala fi ọ̀kadà dé jákè-jádò àgbáyé láàrin ọdún mẹ́fà, àwọn orílẹ̀-èdè bii Israel, Egypt, Palestine, India, Orílẹ̀ èdè America, Austrálíà, Iran, Russia,Cyprus, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni Ajala dé, tó sì pàdé àwọn èèyàn ńlá-ńlá tó fi mọ́ àwọn olórí orílẹ̀-èdè náà.

Mọ̀lẹbí rẹ̀ àtúnṣe

Aya púpọ̀ ni Ajala ní, bó ṣe fẹ́ dúdú, ló fẹ́ pupa, kódà ó kọ ọmọ sí òyìnbó kan lọ́rùn, èyí tó di ọ̀rọ̀ ilé-ẹjọ́.[7][8] Lóṣù kẹta ọdún 1953 ní wọ́n tún fi ẹ̀sùn mìíràn kan Ajala, ó sì lọ sẹ́wọ̀n ọdún kan, tí wọ́n le kúrò ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, pàápàá nítorí kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó wá fún ní Amerika , tí ó sì ń ṣe ségesège. Ó kọ̀ láti kúrò, ó sì gun orí òpó kan tó gún tó ìwọ̀n ọgọ́rin ẹsẹ̀ bàtà, tó sì ń dúnkokò pé òun yóò jábọ́ sílẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ oúnjẹ láti ẹ̀họ́nú hàn tako bí wọ́n ṣe le ní orílẹ̀-èdè náà.[9] Lẹ́yìn òrẹyìn, wọ́ gbe lọ sí London.[10] Ajala padà sí Amẹ́ríkà lọ́dún (1954) pẹ̀lú aya rẹ̀ aláwọ̀ funfun, Hermie Aileen, àmọ́ obìnrin náà fẹ̀sùn kàn án torí ò ń kóbìnrin kiri, ó sì ń ṣe àgbèrè. Ní ọdún (1955) ló tún fẹ́ ìyàwó mìíràn, tó ń ṣe iṣẹ́ òṣèré orí tẹlifisan, ẹnì ọdún mọ́kàndínlógún.[11]

Ikú rẹ̀ àtúnṣe

Ajala pada si ilẹ Nàìjíríà lẹyin ọpọ ọdun loke okun, o dagba, aisan rọlapa, rọlẹsẹ si mu, amọ ko si owo fun lati tọju ara rẹ, ọjọ keji osu keji ọdun 1999 (02/02/1999) ni Ọlabisi Ajala ki aye pe o digbose nile iwosan ijọba to wa ni Ikẹja.Bi o tilẹ jẹ pe Onirese Ọlabisi ọmọ Ajala ko fin igba mọ, amọ eyi to ti fin silẹ ko lee parun, nitori a ko tii ri eeyan miran to fi Ọkada rin yika agbaye mọ bii Ajala. Ẹ jẹ ki awa naa sa ipa wa, lati fi ipa tiwa han lawujọ agbaye nitori arise ni arika, ohun ta ba si se ni oni, ọrọ itan ni yoo da, bo ba di ọla.

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Ajala The Traveller: The Man And His Journeys". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 17 May 2020. Archived from the original on 26 August 2021. Retrieved 12 Jan 2022. 
  2. "Olabisi Ajala, the Traveller: Of Fame and Penury, By Femi Kehinde - Premium Times Opinion" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-12-01. Retrieved 2021-06-10. 
  3. "The Story of Olabisi Ajala, The Popular Nigerian Traveller Who Toured The World On A Vespa". OldNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-05-02. Retrieved 2020-05-18. 
  4. "Between fame and penury: Life and times of Olabisi Ajala- the traveller". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-12-17. Retrieved 2020-05-18. 
  5. "For the Record: THE STORY OF OLABISI AJALA, AFRICA'S MOST LEGENDARY TRAVELLER". PENPUSHING (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-01-22. Retrieved 2021-06-10. 
  6. "Tourism: Ajala the greatest African Traveller of all times". ATQ News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-06-24. Retrieved 2020-05-18. 
  7. (in en) Jet. Johnson Publishing Company. 1953-01-22. https://books.google.com/books?id=XbsDAAAAMBAJ&pg=PA43. 
  8. (in en) Jet. Johnson Publishing Company. 1953-02-12. https://books.google.com/books?id=47oDAAAAMBAJ&pg=PA21. 
  9. "Olabisi Ajala, the Traveller: Of Fame and Penury, By Femi Kehinde - Premium Times Opinion" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-12-01. Retrieved 2021-06-10. 
  10. "Tourism: Ajala the greatest African Traveller of all times". ATQ News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-06-24. Retrieved 2020-05-18. 
  11. "Between fame and penury: Life and times of Olabisi Ajala- the traveller". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-12-17. Retrieved 2020-05-18.