Ìwó
Iwo jẹ́ ìlú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ará Ìwó, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Yorùbá mìíràn ṣẹ̀ wá láti Ile-Ife, tí wọ́n ṣí kúrò ní sẹ́ńtúrì kọkànlá, gẹ́gẹ́ bí Alademomi kenyon àti Prince Adelegan Adegbola (2009) ṣe sọ.[1][2] Ìlú náà fìgbà kan wà lára ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí wọ́n wá padà yọ kúrò, tó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ìlú tó ṣe pàtàkí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Ìwó | |
---|---|
Ìlú | |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iwo Ìwó Odíderé | |||
---|---|---|---|
LGA and city | |||
Nickname(s): Iwo Olodo Oba | |||
Motto(s): Iwo Olodo Oba, Iwo Ateni Gbola Ateni Gbore. | |||
Coordinates: 7°38′N 4°11′E / 7.633°N 4.183°E | |||
Country | Nigeria | ||
State | Osun State | ||
Founded by | Oluwo | ||
Government | |||
• Oluwo of Iwo | HRM Oba Abdulrosheed Akanbi | ||
• Local Government Chairman | Raji Kamoru Abiodun | ||
Area | |||
• Total | 7,543 km2 (2,912 sq mi) | ||
Population (2006 Census) | |||
• Total | 191,377 | ||
(central city/Local Government) | |||
Time zone | UTC+1 | ||
3-digit postal code prefix | 232 | ||
ISO 3166 code | NG.OS.IO | ||
National language | Yorùbá | ||
|
Àwọn Ọba tí wọ́n ti jọba lórí ìlú yìí ju ọgbọ̀n lọ, lábẹ́ Oluwo ti ìlú Ìwó, HRM Oba Abdulrosheed Akanbi, gẹ́gẹ́ bí i aláṣẹ ìlú náà. Ìlú yìí tóbi ní ìwọ̀n 245 km2, pẹ̀lú iye ènìyàn tó tó 191,348. Èyí sì jẹ́ ìlú tó ní ènìyàn tó pọ̀ jù lọ ní àsìkò ìka iye ènìyàn tó wáyé ní ọdún 2006, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mìíràn tó wà níbẹ̀ ni; agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Aiyedire, tó tóbi pẹ̀lú ìwọ̀n 265.783 km2, tó sì ní iye ènìyàn 76,309, àti agbègbè ìjọba ìbílè Ola-Oluwa, tó tóbi pẹ̀lú ìwọ̀n 332.117 km2, tí ó sì ni iye ènìyàn 76,227. Olú-ìlú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yìí wà ní; ààrin gbùngùn Iwo (Central), Iwo; Aiyedire, Ile Ogbo; àti Ola-Oluwa, Bode-Osi. Iwo ti ní àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin si, àwọn ni: Iwo East, Olomowewe; Iwo West, Agberire; Ọla Oluwa South East, Ilemowu; Ayedire South East, Oluponna.
Ètò ẹ̀kọ́
àtúnṣeOrísun ètò ẹ̀kọ́ ní ìlú Ìwó ni àwọn ajíhìnrere tí wọ́n mú ẹ̀sìn kìrìsìtẹ́ẹ̀nì wá.[3] Àwọn ìjọ Baptist sì ló kọ́kọ́ ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lóríṣiríṣi, lára wọn ni: Aipate Baptist Day School, Olukotun Baptist Day School, Feesu Baptist Day School, Oke-Odo Baptist Day School. Ìjọ Baptist yìí bákan náà ni wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ girama, tí wọ́n pè ni, Baptist High school, Iwo, tó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo tó ń fúnni ní ìwé-ẹ̀rí West African School Certificate pẹ̀lú O level. Wọ́n sì tún ní Baptist Modern school (tí kò sí mọ́ ní ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà òde-òní) tó wá padà di Baptist Grammar school – tó sì ń fúnni ní ìwẹ́-ẹ̀rí O level bí i àwọn ilé-ẹ̀kọ́ girama mìíràn. Bákan náà ni wọ́n ní Teacher Training College. Kọ́lẹ́ẹ̀jì yìí ni Bowen University wà báyìí, tó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìjọ Baptist.[4] Lẹ́yìn àọn Baptist ni àwọn Methodist dé, tí wọ́n sì ṣe ìdásílẹ̀ Methodist Primary School ní ìlú náà, àti ilé-ẹ̀kọ́ girama, tó ti wá di United Methodist High School.
Àwọn Catholic náà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama, tó ti wá di Catholic Grammar School, àti ilé-ẹ̀kọ́ fún àwọn obìnrin nìkan, ìyẹn St. Mary's High School.
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ìjọba lọ́wọ́ sí ètò ẹ̀kọ́, tí wọ́n sì ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lóríṣiríṣi, ilé-ẹ̀kọ́ girama, Teacher Training College, LATCO, tó yí padà ní ọdún 1964 di Iwo Grammar School.
Àwọn ajíhìnrere ti ẹ̀sìn Mùsùlùmí náà ò gbẹ́yìn nínú ètò ẹ̀kọ́ ìlú Ìwó. Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ Ansar-U-deen Primary School, Ansar-U-deen Modern School tó yí padà di Ansar-U-deen Grammar School, àti Anwar-ul-Islam Grammar School. Ilé-ẹjọ́ Mùsùlùmí àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà wà ní ìlú Iwo.[5] Púpọ̀ nínú àwọn ará Iwo jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, ní àwọn ọdún 1655 síwájú, nígbà tí wón kọ́ Mọ́ṣáláṣí àkọ́kọ́ tó wà ní ilẹ̀ Yorùbá síbẹ̀.[6] Lára àwọn ilé-ẹ̀kọ́ girama tó gbajúmọ ní Ìwó ni Iwo Grammar School, United Methodist High School, Baptist High School, St. Mary's High School, L.A. Commercial Grammar School, Islahudeen Grammar School àti Anwar-ul-Islam Grammar School. Iwo gbajúmọl fún ẹ̀kọ́ Lárúbáwá. Oríṣiríṣi ilé-ẹ̀kọ́ Lárúbáwá ló wà ní Ìwó, lára wọn ni Islamic youth center (morkaz shabaab), èyí tí onímọ̀ Islam kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sheikh Ahmad Muhally Adedimeji Aroworeki ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀, Islahudeen Arabic School, Obatedo, tí Sheikh Abdulbaaqi Muhammad dá sílè ní 1960. Amin Training Center, Araromi náà tún jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ mìíràn tí Sheikh Badrudeen Al-Amin dá sílẹ̀. Islamic cultural center (Markaz Abdul Razaq Abdul Rahman), Sheik Adam ilory Villa, Agbowo, Iwo.
Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga wà ní ìlú yìí bákan náà, lára wọn ni: BOWEN University,[7] Wolex Polytechni,[8] Baptist Teachers' Training College tó wà ní Oke Odo ní Ìwó, àmọ́ tí wọ́n wá ń lò bí ọgbà Bowen University báyìí, Westland University,[9] Iwo city polytechnic,[10] Royal College of Public Health and Technology,[11] Empire College of Health Technology, Al Ummah College of Education,[12] Federal College of Education,[13] Offer[14] center institute of Agriculture.[15] Òmíràn tó dà bí i rẹ̀ ni Shariah College of Nigeria, tó fìgbà kan wà ní Ibadan, kí wọ́n tó wá gbe wá sí Oke-Afo, Iwo.[16]
Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni ní ìlú náà ni Islamic Model College, Muslim International School, Agbaje Memorial Comprehensive College, Aipate Baptist School, Vico-Hope Comprehensive College, A-1 Grammar School, Crowey Schools, Regina Mundi Girls Secondary School,[17] The wings school,[18] Innayatullah muslim academy, ICC Model school, Our Lady of Fatima academy (OLFA).
Ìmọ̀ ẹ̀rọ
àtúnṣeIwo ni wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán àkọ́kọ́ tó jẹ́ ti ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdẹ̀ Nàìjíríà, ní ọdún 1982, ìyẹn Reality Television Service (RTS),[19] ibẹ̀ sì ni Reality Radiovision Services (RRS) wà, tí a tún mọ sí odidere fm tàbí 96.3Fm. Bákan náà, Ìwó ni Ilè Isẹ Agboun sá fe fé Bowen Radio 101.9fm wà àti ilé-iṣẹ́ rédíò àtijọ́ ní ori eru Iwo Am, èyí tí ìjọba ìbílẹ̀ Òṣun pa tì. Wọ́n ti ní ilé-iṣẹ́ rédíò tuntun, ìyẹn Ayekooto Fm, 88.3fm àti Akorede Radio 98.9Fm
Iṣẹ́ àgbè
àtúnṣeIwo ni Osun State Agricultural Development Programmes (OSSADEP) wà, bákan náà ni selema farm[20], shabeeb agro[21] àti àwọn mìíràn wà níbẹ̀.
Community based organisations
àtúnṣeLara awọn ẹgbẹ ti o da lori agbegbe ni Ilu Iwo ni: Igbimọ Alakoso Iwo (IBOT), Igbimọ Iwo Action (IWAC), Iwo Progressive Union (IPU), Iwoland Development Coalition (IDC), Guildance Community Development Foundation, Charitable Youth for Nation Building Initiative, Iwo Odidere Leo Club. Iwo Action Council (IWAC) jẹ agboorun ti gbogbo awọn ajo ni Iwo. A ti mọ IWAC fun wiwa ni iwaju bi eto idojukọ idagbasoke.[22]
Iwoland Development Coalition (IDC) was formed on 29 August 2014 to champion development of Iwo, Aiyedire and Ola Oluwa Local Government. IDC currently have members in countries like: Kuwait, Saudi Arabia, Qatar, Côte d'Ivoire, France, United States of America, United Kingdom.[23] IDC though is still a new organisation but has succeeded in establishing health clinic at Akinbami in Aiyedire Local Government, reconstructed culvert at Ojude Oba in Iwo, staged schools tour in Iwo, Aiyedire and Ola Oluwa Local Governments, award scholarship to students in need, rehabilitate Yidi Oba culvert, organised lectures on burning issues, distributed over 8,000 health books (containing useful information on how to take care of pregnant and Children), organised widows empowerment programme, provide nutritional support to orphans and vulnerable children, take care of people with disabilities, researched the history of Iwoland, administered Vitamin A and Abendazole for the benefit of children of ages 0 and 5 years, patched pot holes from Adeeke and Kajola road, cleaned and painted Iwo roundabout, organised health outreach, assisted Local Authority Grammar School to transport chairs from Iwo Grammar School and payment of WAEC examination of 6 students two each from Iwo, Aiyedire and Ola Oluwa Local Government.[24]
Iwo Chamber of Commerce and Industry Limited/GTE
àtúnṣePeople who are interested in economic development of Iwoland came together in 2018 to form Iwo Chamber of Commerce and Industry Limited/GTE. The organization was registered with Corporate Affairs Commission in 2021 which is completely different from the defunct one established in 1989. Iwo Chamber of Commerce and Industry was established for the promotion and protection of trade and industry and to represent and express the opinion of the business community on matters affecting trade and industry in Iwoland which consists of the three local government areas in the federal constituency (Iwo, Ayedire and Ola Oluwa) Iwoland Federal constituency and where applicable, the whole State of Osun and the Federation. It is a non–profit–sharing organization and its income and properties are applied solely for the promotion of ICCI's objectives. Among those people that made it happen then are: Olusegun Dada (Esq), Kudaisi Ismaila (Esq), Olawale Rasheed, Senator Adelere Oriolowo, Alhaji Mokanju Musibau FCA, Professor Waheed Hassan, Otunba Jire Ayinla, Akogun Olaposi Adiatu, Adebayo Lasisi PhD, FCA, Kabiru Adisa FCA, Lanre Omotayo PhD, Princess Funmi Lamuye[25]
Ojú-ọjọ́
àtúnṣeÌwó ní ojú ọjọ́ tó máa ń tutù, tó sì máa ń gbẹ, níwọ̀n bí ojú ọjọ́ bá ṣe rí. Ìwọ̀n bí ojú ọjọ́ ṣe rí ní ọdọọdún ni 29.66 °C (85.39 °F), tí ó ga níwọ̀n 0.2% ju ti orílẹ̀-èdè lọ. Ìwó lápaapọ̀ máa ń ní ọjọ́ tó tutù 248.57 (68.1% of the time) lọ́dọdọdún.[26]
Àtòjo àwọn alága ilbílẹ̀ Ìwó láti ọdún 1989 títí di òní
àtúnṣe- Chief Blarinwa 1989-1989
- Chief Ganiyu Iromini 1993-1994
- Barrister Gbadegeshin Adedeji 1994-1996
- Mr Kamilu Adio 1996-1997
- Honourable Mutiu Kareem 1999-2002
- Honourable Moshood Adeoti 2002-2003
- Honourable Rasaki Ajadi Salwu 2003-2006
- Engineer Lasun Olaniyi 2006-2007
- Honourable Sulaimon Bello 2007-2010
- Honourable Kamo Olabisi Alao 2010-2016
- Honourable Kamorudeen Raji 2017-2021
- Honourable Ishola Kamar Adeniyi since 2021
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Tomori, Lola (22 February 2018). "THE FOUNDATION OF IWO TOWN AND ITS MIGRATION HISTORY FROM ILE-IFE" (PDF). www.macosconsultancy.com. Archived from the original (PDF) on 18 August 2022. Retrieved 23 September 2022. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Hub, Iwoland (2019-07-22). "Short History of Iwo land: The Knowledge of Iwo You Must Know". Iwoland Hub (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-22.
- ↑ Hub, Iwoland (2019-07-23). "History and Background of Education in Iwo land". Iwoland Hub (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-22.
- ↑ "Bowen University Iwo - Home". Archived from the original on 2017-01-21. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Islam came to South, before Northern Nigeria - Isa Yuguda | Premium Times Nigeria". 26 April 2013.
- ↑ "Analytical Study of Rijāl Al-'Ilm of Shaykh Tajudeen Al-Umari Al-Iwowi".
- ↑ "The Official Website of the State of Osun". Archived from the original on 2022-02-10. Retrieved 2024-05-20.
- ↑ "Wolex Polytechnic". Wolex Polytechnic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-21.
- ↑ "Westland University, Iwo – Technology is Power" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-21.
- ↑ "welcome to Iwo City Polytechnic Feesu, Iwo". www.iwocitypolytechnic.com. Archived from the original on 2020-11-26. Retrieved 2020-11-21.
- ↑ Royal college of public health technology, Technology (2020). "Education". Royal college of public health technology. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "Welcome to Al-Ummah College of Education". www.al-ummahcollege.com. Archived from the original on 2019-09-05. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "FEDERAL COLLEGE OF EDUCATION IWO – IWO, OSUN STATE" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-29.
- ↑ "OFFERCentre — Institute of Agriculture". offercentre.edu.ng. Archived from the original on 2020-11-30. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "::OFFAR FOUNDATION". www.offercentre.org. Archived from the original on 2020-11-23. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "Buy a Domain Name - World's Best Domains For Sale". Archived from the original on 2023-11-10. Retrieved 2024-05-20.
- ↑ "THE SCHOOL OF QUEENS". www.reginamundi.sch.ng. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "thewingsschools.com". www.thewingsschools.com. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ rrsiwo. "Reality Radiovision Services". Reality Radiovision Services. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "Selemafarms – Nigeria's Foremost Livestock Farmhouse" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-11-29. Retrieved 2020-11-21.
- ↑ "Shabeeb integrated service Ltd". www.shabeeb.com.ng. Archived from the original on 2020-11-29. Retrieved 2020-11-21.
- ↑ "Iwo indigenes want Aregbesola to approve journalism institute". The Nation Newspaper. 22 October 2016. http://thenationonlineng.net/iwo-indigenes-want-aregbesola-approve-journalism-institute/.
- ↑ https://www.facebook.com/groups/1457000667917000/?ref=group_header Àdàkọ:User-generated source
- ↑ "Home". Archived from the original on 2023-03-27. Retrieved 2024-05-20.
- ↑ "Home". 7 February 2022. Archived from the original on 19 August 2022. Retrieved 20 May 2024.
- ↑ "Iwo, Osun, NG Climate Zone, Monthly Averages, Historical Weather Data". tcktcktck.org. Retrieved 2023-09-26.