Kò sí oríkì kan pàtó tí ó wà fún òkè, àmọ́ ohun tí a lẹ̀ sọ ni pẹ́ òkè jẹ́ ilẹ̀ tí ó ga jùlọ ní agbègbè rẹ̀ [1] Oríṣiríṣi òkẹ̀ ló wà ní ilẹ̀ Yorùbá. Àpẹẹrẹ ni

Òkè

Òkè Olúmọ ni òkè kan tí ó wà ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá ìlú Abẹ́òkúta tí ó jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òkè Olúmọ jẹ́ ibùsálà fún àwọn ará Abẹ́òkúta ní àsìkò ogun abẹ́lé ní àsìkò nígbà láéláé. Wọ́n sì ń bọ òkè náà gẹ́gẹ́ bí Òrìṣà ttíí di òní. [2]

Òkè-Ìmẹ̀sì

àtúnṣe

Ìlú Òké-Ìmẹ̀sí wa ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òké-Ìmẹ̀sí tó 7.82° ìbú ní apá Gúsù nígbat tí ó tó 4.92° òró ní apá Àríwá tí ó sì tó 541 fífẹ́ ní iye. Coordinates: 7°49′0″N 4°55′0″EÌkóró-Èkìtì àti Ìjerò-Èkìtì ni ó pààlà pẹ́lú Òké-Ìmẹ̀sí ní apá àríwá nígbàtí òun àti Ẹfọ̀n Alààyè pààlà ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ní apá Gúsù ni Ìmẹ̀sí-Ilé wà sí Òké-Ìmẹ̀sí, tí ìlú Òké-Ìmẹ̀sí sì pààlà pẹ̀lú àwọn ìlú bíi: Ẹ̀sà-Òkè àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Bí ìlú náà ṣe ní òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ó jẹ́ kí ó dùn ún wò ati láti lọ síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àyè ìgbafẹ́. Bákan náà ni ọyẹ́ tí ó ma ń mú níbẹ̀ ní àsìkò ọyẹ́ ma ń tutù mọ́ni fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni. Àwọn ilẹ̀ ibẹ̀ gbogbo ni ó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá fún nkan ọ̀gbìn, bákan náà ni àwọn ohun alùmónì oríṣiríṣi sòódó síbẹ̀.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Molnar, Peter H. (2021-11-17). "mountain - Definition, Characteristics, Types, & Facts". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2022-05-21. 
  2. "Olumo Rock". Wikipedia. 2014-06-03. Retrieved 2022-05-21. 
  3. "THE ROLE OF FABUNMI OF OKEMESI-EKITI IN THE EKITIPARAPO/KIRIJI WAR OF 1877-1893". UNIPROJECT (07064961036 for complete project). 2015-08-30. Retrieved 2022-05-21.