Ṣúgà
Ṣúgà ni orúkọ tí a ń pe ohun oníyẹ̀fun tí ó ma ń mú oúnjẹ dùn tí wọ́n ma ń fi sí orísiríṣi oúnjẹ. Súgà lásán ni ó ní èròjà glucose, fructose, àti galactose nínú. tí wọ́n tún ń dàpè ní
Ìwúlò rẹ̀
àtúnṣeṢúgà ni wọ́n ma ń lò láti fi pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ bíi bisikíìtì, àkàrà òyìnbó àti aeọn nkan mìíràn bíi oúnjẹ inú agolo tabí ti inú ọ̀rá. Wọ́n sì tún lè lòó láti fi ṣe nkan amónjẹ ẹ̀kọ mímu tàbí tíì dùn. Ó kéré tán, ènìyàn kan ṣoṣo lè jẹ ṣúgà tí ó tó 24 kilograms (53 pounds) láàrín ọdún kan ṣoṣo. Àwọn ará gúúsù àti àwọn ènìyàn apá aríwá ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni wọ́n ma ń jẹ tó súgà tí ó tó 50 kg (110 lb), nígbà tí àwọn olùgbé ilẹ̀ adúláwọ̀ lè jẹ tó 20 kg (44 lb) niyen tí kò tó ti àwọn olùgbé Amẹ́ríkà.[1]
Iṣẹ́ rẹ̀ nínú ara
àtúnṣeṢúgà jíjẹ bẹ̀rẹ̀ ní inú ọdún 20th century, àmọ́ ṣá, àwọn oníwádí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ wá ń ṣe ìwádí ìyàtọ̀ tó wà láàrín jíjẹ ṣúgà lásán àti àwọn súgà tí wọ́n ti tún ṣe agbélẹ̀rọ rẹ̀ kò léwu fún ìlera ọmọnìyàn. Wọ́n wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àpọ̀jù ṣúgà jíjẹ ní ìpalára tó lágbára fún ìṣẹ̀mí ọmọnìyàn nítorí wípé ó lè fa àwọn àìsàn bíi: ara sísan àsanjù, itọ̀ ṣúgà, àárẹ̀ inú iṣan, àrùn jẹjẹrẹ àti ìjẹrà eyín àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2] Nínú ọdún 2015, àjọ World Health Organization fi léde wípé kí tọmọdé tàgbà ni ó yẹ kí wọ́n dín jíjẹ ṣúgà wọn kù ní ìwọ̀n ìdá mẹ́wàá tàbí kí wọ́n dinkù ní ìdá márùn ún.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "OECD-FAO Agricultural Outlook 2020–2029 – Sugar" (PDF). Food and Agriculture Organization. 2019. Archived from the original on 17 April 2021. Retrieved 15 February 2021.
- ↑ Huang, Yin; Chen, Zeyu; Chen, Bo; Li, Jinze; Yuan, Xiang; Li, Jin; Wang, Wen; Dai, Tingting et al. (2023-04-05). "Dietary sugar consumption and health: umbrella review" (in en). BMJ 381: e071609. doi:10.1136/bmj-2022-071609. ISSN 1756-1833. PMC 10074550. PMID 37019448. https://www.bmj.com/content/381/bmj-2022-071609. Retrieved 27 April 2023.