Obálendé, ni ó túmọ̀ sí Ibi tí Ọba lé wa dé"[1] jẹ́ àdúgbò kan tí ó wà ní àárín ìlú Èkó ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Etí-Ọ̀sà, tí ó súnmọ́ Lagos Island. Etí-Ọ̀sà yí ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó pín sí abẹ́ ìjọba ìbílẹ́ onídagbà-sókè , èyí tí Ìkòyí- Ọbáléndé wà nínú rẹ̀. [2][3] Ọbáléndé ni ó ní àwọn ilé-ẹ́kò bíi: Holy Child College Ọbáléndé, St Gregory's College, Aunty Ayo International School àti ilé-ẹ̀kọ́ Girls Secondary Grammar School. Àwọn bárékè ti ilé-iṣẹ́ ọlópàá ati Bárékè ti àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà ni wọ́n wà lẹ́nu odi Ọbáléndé. Àwọn ọ̀gọ̀tọ̀ èrò tí wọ́n gbé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ìlú Ọbáléndé ni ó jẹ́ kí ìlú náà ó fún.pinpin, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ayè rárá bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ látàrí àpọ̀jù ènìyàn. Lára ohun tí ó jẹ́ kí Ọbáléndé ó gbajúmọ̀ gidi ni títà ati rírà ọjà alẹ́, tí ó dà bí ẹni wípé tọ̀sán tòru ni wọ́n fi ń nájà níbẹ̀. Inú ìlú Ọbáléndé ni ibùdókọ̀ kan wà tí wọ́n ń pè ní Ibùdókọ̀ Súyà.

Ọbáléndé
Adúgbò
Road sign for Ikoyi Road and Obalende Road
Road sign for Ikoyi Road and Obalende Road
Lua error in Module:Location_map at line 464: Unable to find the specified location map definition. Neither "Module:Location map/data/Nigeria Lagos" nor "Template:Location map Nigeria Lagos" exists.
Coordinates: 6°26′41″N 3°25′3″E / 6.44472°N 3.41750°E / 6.44472; 3.41750Coordinates: 6°26′41″N 3°25′3″E / 6.44472°N 3.41750°E / 6.44472; 3.41750
Country Nigeria
StateLagos State
CityLagos
LGAEtí-Ọ̀sà
Time zoneUTC+1 (WAT)

Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ìlú Ọbáléndé

àtúnṣe

Ajọ [Royal West African Frontier Force]] (RWAFF) tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ ẹ̀yà Hausa tí pàgọ́ sí orí ilẹ̀ kan ní ìlú [Èkó]] ni ìkàn lára àọỌba ilẹ̀ Èkó lásìkò náà pàṣẹ fún Gómìnà orí oyè lásìkò náà wípé kí ó kó àwọn tí wọ́n oàgọ́ sí orí ilẹ̀ kan tí òun dẹ́ lò, kí kó wọn lọ sí ibòmírà. Ibi tí ọba wá fún láti máa gbélẹ́yìn tí ó lé qọn kúrò níbi àkọ́kọ́ ni ó di ìlú Ọbálédé lónìí. [4] [1]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Dike, Kingsley (May 31, 1997). "A people pursued". The Guardian (Nigeria). 
  2. Àdàkọ:Google maps
  3. Àdàkọ:Cite map
  4. "Daily Trust". Daily Trust (in Èdè Ruwanda). Retrieved 2020-12-11. 

Àdàkọ:Lagos-stub Àdàkọ:LagosNG-geo-stub

 
ILUBIRIN, Obalende