Ọjà
Ọjà jẹ́ àwùjọ kékeré tàbí ńlá tí ètò kárà-kátà tàbí ìdókowò pọ̀ láàrín olùtajà àti olùrajà ti ma ń wáyé, yàlà ní àrín ìlú ni tàbí lẹ́yìn odi.[1]
Oríṣi Ọjà tó wà
àtúnṣeNí aye àtijọ́, ọjà pin sí oríṣi méjì.
- Ọjà ìlú
- Ọjà oko
Ọjà ìlú tàbí Ọjà Ọba
àtúnṣeni ibi tí Kárà-kàtá lórí oríṣiríṣi lórí ohun kóhun tí ènìyàn bá fẹ́ ra ti ń wáyé nípa lílé ọjà síléẹ̀ fún títà. Látorí gbogbo ohun tí ẹnu ń jẹ bi ata ẹ̀fọ́ gàrí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tí ara ń wọ̀ bí bàtà, fìlà, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Irúfẹ́ ọjà yí ma ń sábà wà ní iwájú Afin Ọba.[2]
Ọjà Oko
àtúnṣeÈyí ni ọjà tí ó dá lórí ohun Ire oko lásán. Irè oko yí lè jẹ́ ẹ̀fọ́, ata, iṣu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ọjà wọ̀nyí ni wọ́n ma ń kò wà láti ta ní inú ọjà àárín ìlú.
Ọjà Igbá-lódé
àtúnṣeÈyí jẹ́ ọjà tí wọ́n ma ń ra lá orí ẹ̀rọ aye-lu-jára láti inú ilé ẹni. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n tún ma ń kọ́ àwọn àgbàọ́ kan lọ́nà ará ọ́tọ̀ tí wọn yóò sì pàtẹ ọjà tí wọ́n fẹ́ ta síbẹ̀, àwọn ọjà wọ̀nyí ma ń yàtọ̀ sí Irúfẹ́ ọjà tí a lè bá pàdé ní ọjà ìlú tàbí ọjà Ọba, nítorí àwọn ọjà tí oo bá pàdé níbeẹ̀ kii ṣe ọjà àtoko wà, bí kìí ṣe àwọn ọjà inú ọ̀rá (nylon) tàbí ọjà inú Ike tí wọn kii lé sílẹ̀ lásán.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "What is Markets? Definition of Markets, Markets Meaning". The Economic Times. Retrieved 2020-01-30.
- ↑ "Market - economics". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2020-01-30.