Gàrí
Gàrí ni ohun jíjẹ lẹ́bú-lẹ́bú kan tí ó ma ń ní awọ funfun tabí àwọ̀ órí tí wọ́n ma ń ṣe jáde láti ara ẹ̀gẹ́ tí a tún ń pè ní pákí. Irúfẹ́ oúnjẹ yìí wọ́pọ̀ ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀.[1] Oríṣiríṣi ohun tí wọ́n pèsè láti ara nnkan bíi àgbàdo, ìrẹsì, iṣu tàbí ọkà bàbà tí wọ́n sì sọ di ìyẹ̀fun ni àwọn ẹ̀yà Hausa sábà máa ń pè ní gàrí, tí wọn yóò sì máa fi orúkọ ohun tí wọ́n fi ṣe ìyẹ̀fun náà kun. Àpẹẹrẹ ni: garin dawa, garin masara ati garin alkama' àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Púpọ̀ nínú àwọn olùgbé àwọn orílẹ̀-èdè bíi: Nàìjíríà, Gánà, Togo, Benin Republic, Guinea, Cameroon àti Liberia ni wọ́n sábà ma ń jẹ gàrí gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ nígbà tí wọ́n bá fi gàrí tẹ ẹ̀bà nígbà tí wọ́n bá dà á sínú omi gbígbóná tàbí kí wọ́n wà á mu nígbà tí wọ́n bá dà á sínú omi tútù.
Bí wọ́n ṣe ń ṣe gàrí
àtúnṣeLáti ṣe gàrí oníyẹ̀fun, wọn yóò bẹ ẹ̀gẹ́ ní tútù tí wọn yóò si sì fọ̀ ọ́nù kí wọ́ tó lọ̀ọ́ nínú ẹ̀rọ. Ẹni tí ó bá wù lè ta epo díẹ̀ si kí àwọ̀ rẹ̀ lè yí padà kúrò ní funfun sí rẹ́súrẹ́sú. Lẹ́yìn èyí, wọn yóò ko sínú apò tí wọn yóò sì lọ́ àpò náà ní ẹnu, wọn yóò fikalẹ̀ fún ọjọ́ díẹ̀, lẹ́yìn èyí yóò gbé nnkan ńlá bí òkúta tí ó wúwo lée kí omi rẹ̀ ó le ro dànù láàárín wákàtí kan sí mẹ́ta. Lẹ́yìn tí ó bá tí gbẹmi tán, wọn yóò jọ̀ọ́ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní yan án lórí iná. Lẹ́yìn tí gàrí bá délẹ̀ tán, a lè gbe pamọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ fún lílò ọjọ́ iwájú. [2]
Àwọn ohun tí a lè fi garí ṣe
àtúnṣeA lè fi gàrí tẹ ẹ̀bà nígbà tí wọ́n bá dà á sínú omi gbígbóná tí a sì ròó mọ́ra wọn dára dára kí ó le lẹ̀ lọ́wọ́., bákan náà ni a lè fi ẹ̀bà yí jẹ oríṣiríṣi ọbẹ̀ èyí tí ó bá wù wá. A lè fi garí ṣe kókóró, èyí jẹ́ óunjẹ ìpanu kan tí a ma ń kán jẹ tí ó wọ́pọ̀ ní àwọn ìlú bí Ẹ̀gbá tabí Yewa, Ìpínlẹ̀ Abia, ìpínlẹ̀ Rivers, Ìpínlẹ̀ Anambra àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ma ń fi èlùbọ́ àgbàdo.
Oríṣiríṣi ìrísi ni gàrí ma ń ní, ó lè jẹ́ èyí tí ó kúná, tabí kí ó má kúná, èyíkéyí tí ó bá jè níbẹ̀ ni ó ṣe é jẹ bí ońjẹ.
A lè mu gàrí nínú omi tútù nígbà tí a lè fi ṣúgà, oyin, ẹ̀pà àti mílíkì mu ú. Bá kan náà ni a lè jẹ gàrí lásán láì tẹ̀ ẹ́ lẹ́bà tàbí fomi mu ú.
Oríṣìí garí tó wà
àtúnṣeOríṣìí garí tí ó wà pàá pàá jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni gàrí funfun àti gàrí pupa tàbí gàrí elépo. [3] .
Ẹ tún lè wo
àtúnṣeÀwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Garri – Cassava flakes – What you need to know". Chef Lola's Kitchen. 2022-06-24. Retrieved 2023-06-13.
- ↑ "Garri". African Foods. Retrieved August 6, 2015.
- ↑ "Garri: A Guide to West Africa’s Staple Food". The Wisebaker. Retrieved 2021-06-13.
Àwọn Ìtàkùn ìjásóde
àtúnṣeWikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Gàrí |