Olóyè Abibatu Mogaji, MFR, OON tí wọ́n bí ní ọdún 1917, tí ó sì kú ni oṣù kẹfà ọdún 2013 (October 1917–June 2013) jẹ́ =Pàràkòyí oníṣòwò ọmọ Nàìjíríà àti Ìyálọ̀jà yányán gbogbo Nàìjíríà. [1][2]

Àbíbátù Mọ́gàjí
Ọjọ́ìbí(1916-10-16)16 Oṣù Kẹ̀wá 1916
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Aláìsí15 June 2013(2013-06-15) (ọmọ ọdún 96)
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Iṣẹ́Pàràkòyí oníṣòwò
Àwọn olùbátanBọ́lá Tinúbú (ọmọ rẹ̀)

Ìgbà èwe rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Àbíbátù Mọ́gàjí lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1916 ní Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Ẹbí rẹ̀ àtúnṣe

Olóyè Àbíbátù Mọ́gàjí ni ìyá olórí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress tí ó tún jẹ́ Gómìnà àná Ìpínlẹ̀ Èkó, Olóyè Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinúbú.[3][4] Ọmọ Tinubu, Fọláṣadé Tinúbú-Òjó, ló joyè ìyálọ́jà lẹ́yìn ikú Mọ́gàjí.

Iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Kí ó tó jẹ ìyálọ́jà àwọn ẹgbẹ́ àwọn oǹtajà àwọn obìnrin àti ọkùnrin, Àbíbátù jẹ́ olórí onígboyà àwọn ọlọ́jà ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[5]Ní ipò rẹ̀, ó joyè alágbára Alimotu Pelewura.

Nípa akitiyan rẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́jà, Ìjọba Àpapọ̀ Nàìjíríà fi oyè orílẹ̀ èdè dá a lọ́lá. .[6] Bẹ́ẹ̀ náà, wọ́n fi òye Ọ̀mọ̀wé dá a lólá ní Ahmadu Bello University and the University of Lagos.[7]

Ikú rẹ̀ àtúnṣe

Ìyálọ́jà Mọ́gàjí kú lọ́mọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ní Sátidé, lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹfà ọdún 2013 nílé rẹ̀ tó wà ní Ìkẹjà, olú-ìlú Ipinle Eko. Wọ́n sin in sí ìtẹ́ òkú ti Ikoyi Vaults and Gardens ní Èkó [8][9]

Àwọn àmìn ẹ̀yẹ àtúnṣe

  • Order of the Federal Republic
  • Order of the Niger

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Tinubu’s mother, Abibatu Mogaji, dies at 96". punchng.com. Archived from the original on 2015-02-22. Retrieved 2015-02-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "We’ll miss Mogaji’s motherly role – Traders". punchng.com. Archived from the original on 2015-02-22. Retrieved 2015-02-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "ACN leader, Tinubu’s mum, Abibatu Mogaji, dies at 94 | Newswatch Times". mynewswatchtimesng.com. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2015-02-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Mother of Former Gov. Bola Tinubu Is Dead: Alhaja Abibatu Mogaji Was 96 Years Old | Sahara Reporters". saharareporters.com. Retrieved 2015-02-20. 
  5. "Late Abibatu Mogaji: Mixed feelings over closure of markets - Vanguard News". vanguardngr.com. Retrieved 2015-02-20. 
  6. "Lawmaker’s Wife Becomes Iyaloja General | P.M. NEWS Nigeria". pmnewsnigeria.com. Retrieved 2015-02-20. 
  7. "Mogaji: A tale of politics and commerce | The Nation". thenationonlineng.net. Retrieved 2015-02-20. 
  8. Powered by DMflex WebGen --- www.dmflex.com. "Tinubu’s Mother, Abibatu Mogaji, Dies at 96, Articles | THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2015-02-20. Retrieved 2015-02-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Lagos stands still as Tinubu’s mother, Abibatu Mogaji is buried - Vanguard News". vanguardngr.com. Retrieved 2015-02-20.