Adékọ̀yà Òkúpè Agbọ́nmágbẹ

Olóògbé Adékọ̀yà Òkúpè Agbọ́nmágbẹ tàbí Mathew Adékọ̀yà Òkúpè Agbọ́nmágbẹ jẹ́ pàràkòyí oníṣòwò àti Ayánilówó tí ìjọba fọwọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan tí ọmọ rẹ̀, Doyin Òkúpè kọ lórí ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́, Facebook, [1]Òun ni olùdásílẹ̀ Ilé Ìfowópamọ́ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́, Ilé Ìfowópamọ́ Agbọ́nmágbẹ Agbọ́nmágbẹ Bank lórílẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún 1945. Òun bàbá tó bí Doyin Òkúpè, gbajúmọ̀ Òṣèlú, Mínísítà-ana àti agbaninímọ̀ràn àgbà Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àná, Goodluck Jonathan .

Ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

Kí Oloye Mathew Adékọ̀yà Òkúpè tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Agbọ́nmágbẹ tó di olóògbé lọ́jọ́ kìíní oṣù kọkànlá ọdún 1984, ó jẹ́ pàràkòyí oníṣòwò àti Ayánilówó tí ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí. Okowò rẹ̀ tóbi débi pé ó jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ Ilé Ìfowópamọ́ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́, Agbọ́nmágbẹ Bank lórílẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún 1945. Nígbà náà, ilé Ìfowópamọ́ Agbọ́nmágbẹ ni ẹ̀ka méje. Àwọn ẹ̀ka náà tẹ̀dó sí èbúté mẹ́ta, Muṣin, Ifọ̀, ṣàgámú, Àgọ́-Ìwòyè, Ìjẹ̀bú-igbó àti Zaria. Ilé Ìfowópamọ́ Agbọ́nmágbẹ láyé ìgbà náà máa ń yà àwọn oníṣòwò ńláǹlà káàkiri gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà lówó fún okowò wọn. Ilé Ìfowópamọ́ Agbọ́nmágbẹ Bank ní ó wá di Ilé Ìfowópamọ́ Wema Bank láyé òde òní.[2] [3] [4] [5] [6]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Doyin Okupe". Facebook. 1984-11-01. Retrieved 2020-01-08. 
  2. Salako, Femi (2018-03-22). "Tribute to a doyen of patriotism – Daily Trust". Daily Trust. Archived from the original on 2018-03-22. Retrieved 2020-01-08. 
  3. "Our History". Wemabank. 2017-12-14. Retrieved 2020-01-08. 
  4. "Okupe faults Subomi Balogun’s claims of being first indigenous banker - Vanguard News". Vanguard News. 2018-01-13. Retrieved 2020-01-08. 
  5. "3PLR – AGBONMAGBE BANK LTD V. C.F.A.O. – Judgements". Judgements – Law Nigeria. 2018-06-13. Retrieved 2020-01-08. 
  6. "Indigenous Banks in Colonial Nigeria on JSTOR". JSTOR. Retrieved 2020-01-08.