Afeez Owó
Afeez Abíọ́dún tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé àti sinimá, olùgbéré-jáde àti adarí eré Yorùbá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n fun ní ìnagijẹ rẹ̀ Ọwọ́ látàrí bí ó ṣe jẹ́ ọlọ́wọ́-ọ̀rmtún àti ọ̀rẹ́ tímọ́ tímọ́ gbajú-gbajà òṣèré orí-ìtàgé kan Yẹmí Ayébọ̀. [1]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Afeez ní Ìlú Ìsẹ́yìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó lọ sí ilé- ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ti St. paul ní ìlú Ìdírókò ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, ó sì tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama Faramọ́ra ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀, ó lọ sí ìlú Èkó láti wá bí igbé ayé yóò ṣe rọrùn ní àsìkò ọdún 1980.[2]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré
àtúnṣeAfeez ti bẹ̀rẹ̀ ṣiṣẹ́ eré-ìtàgé láti lásìkò tí ó ti wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama nígbà tí ó kọ eré kan tí ó pè ní Kọ́kọ́rọ́ ayé, tí àwọn olùkọ́ àti akẹgbẹ́ rẹ̀ sì gbóríyìn fun fún iṣẹ́ ọpọlọ rẹ̀. Affe dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré ní ilẹ̀ Nàìjíríà pẹ́lú ìrànwọ́ Razaq Ọláyíwọlá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Òjòpogogo. Afeez ti kópa nínú sinimá ọlọ́kan-ò-jọkan bíi:
- Ẹ̀gàn
- Ọmọge Lekki
- Ìṣípayá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bákan náà ni ó ti gbé àwọn eré oríṣiríṣi jàde tí ó sì tún darí àwọn eré bí:
- Ìfẹ́ Owó
- Ẹ̀kanẹ̀ ṣoṣo
- Gbẹ́rẹ́ Méje
- Yọ́nú sími
- Ẹ̀jẹ̀ tútù
- Àbùsí Èdùmàrè
- Adúrótolúwa
- Ìpinnu mi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeAfeez ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Midé Fúnmi Martins tí ó jẹ́ gbajú-gbajà òṣèré sinimá Yorùbá tí ó tún jẹ́ ọmọ òṣèré tí ó ti papò dà ní ọdún 2002, ìyẹn Fúnmi Martins.[3] Wọ́n sì bí ọmọ obìnrin ìbejì.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Actor Afeez Owo: Biography And Net Worth". Ken Information Blog. 2020-04-09. Retrieved 2020-10-25.
- ↑ Editorial, TLP. "Afeez Owo Biography, Age, Wife-Mide Martins, Movies, Net Worth". TLP. Archived from the original on 2020-10-28. Retrieved 2020-10-25.
- ↑ Okanlawon, Taiwo (2020-07-08). "Why I married Afeez Owo – Nollywood actress Mide Martins reveals". P.M. News. Retrieved 2020-10-25.