Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Oye
Oye jẹ́ ìlú àti olú-ìlú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Oyẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ní Nàìjíríà. Wọ́n ṣẹ̀dá Oyẹ́ látara apá Àríwá Èkìtì tí wọn ò tí ì pín ní ọjọ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún, ọdún 1989[1].
Oye LGA | |
---|---|
LGA and town | |
Coordinates: 7°47′58″N 5°19′42″E / 7.79944°N 5.32833°ECoordinates: 7°47′58″N 5°19′42″E / 7.79944°N 5.32833°E | |
Country | Nigeria |
State | Ekiti State |
Government | |
• Local Government Chairman and the Head of the Local Government Council | Oluwole Paul |
• Local Government Secretary | Olukayode Mercy |
Population (2006) | |
• Total | over 134,210 |
Time zone | UTC+1 (WAT) |
Website | http://ekitistate.gov.ng/administration/local-govt/oye-lga/ |
Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ọyẹ́ ń pín ààlà pẹ̀lú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje sí apá Àríwa, Irepodun/Ifelodun sí apá Gúúsù,agbègbè Ìkọ̀lé sí apá ìlà-oòrùn àti agbègbè Ido/Osi sí apá Ìwọ̀-oòrùn.
Àwọn ìlú tí ó wà ní Oyẹ́ ni: Oye Ekiti, Ilupeju Ekiti, Ayegbaju Ekiti, Ire Ekiti, Itapa Ekiti, Osin Ekiti, Ayede Ekiti, Itaji Ekiti, Imojo Ekiti, Ilafon Ekiti, Isan Ekiti, Ilemeso Ekiti, Omu Ekiti, Ijelu Ekiti, Oloje Ekiti àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
KÒ sí ẹ̀yà kan ní agbègbè náà tó yàtọ̀ sí ẹ̀yà Yorùba. Gbogbo ará ìlú náà sì ń sọ èdè Yorùbá àti àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ̀.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Oye – Ekiti State Website". Ekiti State Website – Official Website of the Government of Ekiti State. 2019-09-15. Retrieved 2023-01-13.