Babajide Sanwo-Olu
Babájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú (ọjọ́-ìbí - ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, oṣù June, ọdún 1965)[1][2][3][4] jẹ́ olóṣèlú àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó tó wà lórí àléfà lọ́wọ́lọ́wọ́. Wọ́n dìbò yàán gẹ́gẹ́ bí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 2019 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Lẹ́yìn tí Gómìnà àná, Ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Àḿbọ̀dẹ́ ìjákulẹ̀ nínú ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ All Progressive Congress. [5] [6] [7] [8]
Babajide Olusola Sanwo-Olu | |
---|---|
Babajide Sanwo-Olu | |
15th Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó | |
In office 29 Oṣù Kàrún 2015 – seronja | |
Deputy | Femi Hamzat |
Asíwájú | Akinwunmi Ambode |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
Education | University of Lagos Lagos Business School John F. Kennedy School of Government London Business School |
Occupation | Banker, Politician |
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeSanwó-Olú ní Ìwé-ẹ̀rí Bsc àti MBA láti ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì ìlú Èkó, àti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ bíi London Business School, Lagos Business School àti ilé-ẹ̀kọ́ John F. Kennedy School of Government[9]. Ṣáájú kí ó tó díje dupò Gómìnà, òun ni alákòóso àgbà àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ (CEO) Lagos State Property Development Corporation (LSPDC).[10][11] Ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ Chartered Institute of Personnel Management (CIPM), àti ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ Nigeria Institute of Training and Development (NITAD).[12]
Isẹ́ rè
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ìfowó-pamọ́
àtúnṣeBabájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú ni ó jẹ́ akápò owó fún ilé-iṣẹ́ ìfowó-pamọ́ Lead Merchant Bank tẹ́lẹ̀ rí láàrín ọdụ́n 1994 - 1997, lẹ́yìn èyí ni ó dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìfowó-pamọ́ UBA gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà ní ẹ̀ka ìdókòwò owó ilẹ̀ òkèrè. Lẹ́yìn èyí ni ó gbéra lọ sí ilé-iṣẹ́ ìfowó-pamọ́ First Inland Bank, Plc tí ó ti di (First City Monument Bank) ní sìín gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọ̀gá àgbà àti adarí fún ilé ìfowó-pamọ́ náà ní àwọn ẹsẹ̀ kùkú. Òun ni alága fún ilé-iṣẹ́ Baywatch Group Limited àti First Class Group Limited.
Ìṣiṣẹ́ sìnlú rẹ̀
àtúnṣeBabájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa nínú ìṣèlú ní ọdún 2003, nígbà tí wọ́n yàn-án sí ipò Olùbádá-mọ̀ràn pàtàkì lórí àwọn ọ̀rọ̀ abẹ́nú sí igbákejì gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Èkó nígbà kan rí Fẹ́mi Pedro. Wọ́n fi Babájídé ṣe adelé sí ipò Kọmíṣọ́nà fún Economic Planning and Budget títí di ọdún 2007 tí wọ́n yàn-án sí ipò kọmíṣọ́nà okòwò àti àwọn ilé-iṣẹ́ lábẹ́ ìṣèjọba gómìnà ìgbà náà olóyè Bọ́lá Tinubu. Lẹ́yìn ìdìbò gbogbo gbò tí ó wáyé ní ọdún 2007, wọ́n yan Babájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú sí ipò kọmíṣọ́nà fún Ètò ìdásílẹ̀, Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti Ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ọba lábẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó amòfin Bábátúndé Fáshọlá. Babájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú tún di Adarí àgbà fún ilé-iṣẹ́ Lagos State Development and Property Corporation (LSDPC) lábẹ́ ìṣèjọba gómìnà Akinwunmi Ambode ní ọdún 2016.[10][13]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedBabajide
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedOlusola
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedSanwo-Olu
- ↑ "2023 Presidency: Sanwo-Olu mobilises APC leaders, communities for Tinubu". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-11. Retrieved 2022-03-05.
- ↑ Adekunle (3 October 2018). "Breaking: Ebri’s panel declares Sanwo-Olu winner of Lagos APC primary". Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2018/10/breaking-clement-ebri-declares-sanwo-olu-winner-of-lagos-apc-primary/amp/. Retrieved 3 October 2018.
- ↑ Opejobi (2 October 2018). "Tinubu ‘anointed’ candidate, Sanwo-Olu defeats Ambode in Alausa". Daily Post. https://www.dailypost.ng/2018/10/02/tinubu-anointed-candidate-sanwo-olu-defeats-ambode-alausa/amp/. Retrieved 3 October 2018.
- ↑ Nwafor (12 September 2018). "Babajide Sanwo-Olu: the cool, calm, dynamic technocrat who wants to unseat Ambode". Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2018/09/babajide-sanwo-olu-the-cool-calm-dynamic-technocrat-who-wants-to-unseat-ambode/amp/. Retrieved 2 October 2018.
- ↑ Olasupo (2 October 2018). "Ambode’s deputy declares support for Sanwo-Olu". Guardian. https://guardian.ng/news/ambodes-deputy-declares-support-for-sanwoolu/amp/. Retrieved 3 October 2018.
- ↑ Olafusi, Ebunoluwa (13 September 2018). "CLOSE-UP: Ex-UBA official, UNILAG graduate… meet Sanwo-Olu, Ambode's challenger". The Cable Nigeria. https://www.thecable.ng/close-up-ex-uba-official-unilag-graduate-meet-sanwo-olu-ambodes-challenger/amp. Retrieved 2 October 2018.
- ↑ 10.0 10.1 Nwafor, Polycarp (12 September 2018). "Babajide Sanwo-Olu: the cool, calm, dynamic technocrat who wants to unseat Ambode". Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2018/09/babajide-sanwo-olu-the-cool-calm-dynamic-technocrat-who-wants-to-unseat-ambode/amp/. Retrieved 2 October 2018.
- ↑ Olasupo, Abisola (2 October 2018). "Ambode's deputy declares support for Sanwo-Olu". Guardian. https://guardian.ng/news/ambodes-deputy-declares-support-for-sanwoolu/amp/. Retrieved 3 October 2018.
- ↑ Lawal, Nurudeen; Omotayo, Joseph (11 March 2019). "14 facts you should know about Lagos governor-elect". legit.ng. https://www.legit.ng/amp/1196017-14-facts-babajide-sanwo-olu-lagos-governor-elect.html. Retrieved 26 March 2019.
- ↑ Egbas, Jude (13 September 2018). "7 Things to know about the man who could become the next Governor of Lagos". Pulse Nigeria. https://www.pulse.ng/news/politics/7-things-to-know-about-sanwo-olu-who-could-become-lagos-gov-id8849848.html. Retrieved 3 October 2018.