Bob-Manuel Udokwu
Bob-Manuel Obidimma Udokwu tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹrin, jẹ́ òṣèré, adarí eré, olùgbéréjáde àti olóṣèlú ọmo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1]Oun ni o gba ami-eye ti Lifetime Achievement ni odun 2014 nibi ayeye 10th Africa Movie Academy Awards.[2][3][4] Wọ́n tún yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ ti Òṣèrékùnrin amúgbálẹ́gbẹ́ tí ó peregedé jùlọ ní bi ayẹyẹ àmì-ẹ̀yẹ ti 2013 Nollywood Movies Awards fún ipa ribi ribi tí ó kó nínú eré Adésuwà.
Bob-Manuel Udokwu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Bob-Manuel Obidimma Udokwu Ogidi, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Iṣẹ́ | Òṣèré àti Adarí eré |
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Obidimma ní ìlú Nkwelle-Ogidi, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá "Idemmili" ní Ìpínlẹ̀ Anambra, ní orílẹ-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Igbo pẹ̀lú.
Ètò èkọ́ rẹ̀
àtúnṣeÓ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti St. Peters, tí ó wà ní Coal Camp ní Ìpínlẹ̀ Enugu, nígbà tí ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Oraukwu Grammer School ni ìpínlẹ̀ kan náà, ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ti ìlú Port Harcourt ní Ìpínlẹ̀ Rivers. Ó kẹkọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Eré Oníṣe, Ó sì gboyè ẹlẹ́kejì nínú ìmọ̀ Ìṣèlú ní ilé-ẹ́̀kọ́ Fásitì ti Ìpínlẹ̀ Èkó.
Òun àti ẹbi rẹ̀
àtúnṣeÓ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú arábìnrin Cassandra Udokwu, tí wọ́n sì bímọ méjì fúnra wọn. Ó sọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ní Garvey Udokwu ní ìfisọrí ọ̀gá rẹ̀ nínú ìṣèlú Marcus Garvey.[5]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣe- Living in Bondage
- Karishika
- The Key for Happiness
- Black Maria
- Heaven after Hell
- A Time to Love
- Cover Up
- Endless Tears
- Naked Sin
- My Time
- Home Apart
- Games Men Play
- Soul Engagement
- Living in Bondage: Breaking Free
Ẹ tún wo
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Bob-Manuel Udokwu joins Gov Obiano’s cabinet". Vanguard (Nigeria). Retrieved 10 August 2014.
- ↑ NONYE BEN-NWANKWO AND KEMI VAUGHAN (July 27, 2013). "Bob-Manuel Udokwu is not happy now". The Punch. Archived from the original on 12 August 2014. Retrieved 10 August 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ NKARENYI UKONU (November 18, 2012). "Ladies warn me not to pick my husband’s call again — Cassandra Udokwu". The Punch. Archived from the original on 29 November 2013. Retrieved 10 August 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ayo Onikoyi (4 May 2014). "How Amaka Igwe made me a star – Bob Manuel-Udokwu". Vanguard (Nigeria). Retrieved 10 August 2014.
- ↑ "Biography, Profile, Movies and Success Story of Bob Manuel Udokwu.". 30 April 2018. Archived from the original on 21 August 2018. Retrieved 24 September 2018. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)