Ìpínlẹ̀ Ebonyi
Ipinle Ebonyi State nickname: Salt of the Nation | ||
Location | ||
---|---|---|
Statistics | ||
Governor (List) |
Martin Elechi (PDP) | |
Date Created | 1 October 1996 | |
Capital | Abakaliki | |
Area | 5,530 km² Ranked 33rd | |
Population 1991 Census 2005 estimate |
Ranked N/A N/A 4,339,136 | |
ISO 3166-2 | NG-EB |
Ìpínlẹ̀ Ebonyi (Igbo: Ȯra Ebonyi) jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè gúúsù-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà sí àríwá àti àríwá-ìlà-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Benue, Ìpínlẹ̀ Enugu sí ìwọ̀-oòrùn, Ìpínlẹ̀ Cross River sí ìlà-oòrùn àti gúúsù-ìlà-oòrùn, àti Ìpínlẹ̀ Abia sí gúúsù-ìlà-oòrùn. Wọ́n fún un orúkọ fún àwọn ará Abonyi (Aboine) River—apá kan tó gbòòrò ní ẹkù gúúsù ìpínlẹ̀ náà—Wọ́n ṣẹ̀da Ìpínlẹ̀ Ebonyi látara àwọn apa kan Ìpínlẹ̀ Abia àti Ìpínlẹ̀ Enugu ní ọdún 1996 tí olú-ìlú rẹ̀ sì jẹ́ Abakaliki.
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n kéré láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Ebonyi jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlélọ́gbọ̀n tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kọkàndínlọ́gbọ̀n ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́tadín-ní-ọgọ́rùn-kan-ẹgbẹ̀rún gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún.[1]
Lẹ́yìn òmìnira ní ọdún 1960, agbègbè tí ó wá di Ebonyi báyìí wáà lára agbègbè ìlà-oòrùn tí wọ́n ti ní òmìnira títí di ọdún 1967 nígbàtí ekù náà pín tí agbègbè náà di apá kan ti Ìpínlẹ̀ àáríngbùngbùn ìlà-oòrùn.
Ninu ètò ọrọ̀-ajé, Ìpínlẹ̀ Ebonyi mú iṣẹ́ ọ̀gbìn lókùnkúndùn, pàápàá iṣu, ìrẹsì, epo pupa, àti ègé.
Ìpínlẹ̀ Ebonyi ní Atọ́ka Ìdàgbàsókè Ènìyàn tí ó ga jùlọ-ọ̀nà-ogún ní orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí ilé-ẹ̀kọ́ gíga.[2]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
àtúnṣe- ↑ "Population 2006-2016". National Bureau of Statistics. Retrieved 21 December 2021.
- ↑ "Human Development Indices". Global Data Lab. Retrieved 15 December 2021.