Fisáyọ̀ Ajíṣọlá
Fisáyọ̀ Ajíṣọlá, tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí Freezon,[1]jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ṣeré ìtàgé, model àti akọrin. Ó di ìlú mọ̀ọ́ká látàrí ipa tí ó kó nínú eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Jenifa's Diary, pẹ́lú Fúnkẹ́ Akíndélé. Ó tún ma ń kópa nínú eré ọ́lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ This Life, Nectar, Shadows, Burning Spear, Circle of Interest àti The Story of Us ní orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán.[2] Ó kẹ́kọ́ gboyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Biochemistry láti ilé-ẹ̀kọ́ Federal University of Agriculture, Abẹ́òkúta (FUNAAB), ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.[1]
Fisáyọ̀ Ajíṣọlá | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Olúwáfisáyọ̀ Ajíbọ́lá Ajíṣọlá Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Òṣèré, Akọrin, àti Model |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011 – present |
Website | jef.org.ng |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Fisáyọ̀ ní Ìlú Èkó, àmọ́ ọmọ bíbí Ìlú Ayédùn ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì ni àwọn òbí rẹ̀. òun sì ni àbíkẹ́yìn àwọn ọmọ mẹ́tin tí àwọn òbí rẹ̀ bí.[3]Fisáyọ̀ bẹ̀rẹ̀ eré-ìtàgé láti ìgbà tí ó ti wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama Federal Government College (FGC) Òdoògbólú, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn . Ó dara pọ̀ mọ́ Ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́ni ní eré ìtàgé ti Wale Adénúgà ( PEFTI School) ní inú oṣè kéje ọdún 2010, níbi tí ó ti kọ́ nípa eré orí-ìtàgé.[3]Eré tí ó kọ́kọ́ sọọ́ di ìlú mọ̀ọ́ká ni Nnena and Friends Show, nínú oṣè Kẹjọ ọdún 2010.[3] Ó dá àjọ kan sílẹ̀ nígbà tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì tí ó pè ní Jewel Empowerment Foundation pẹ̀lú èrò láti mú Ìdàgbà-sókè bá àwọn ọ̀dọ́ langba àti àwọn ògo wẹẹrẹ.[4]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré-ìtàgé ní pẹrẹu ní ọdún 2011, tí ó sì kòpa ribiribi nínú àwọn eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ bí: Tinsel, Burning Spear àti Circle of interest. Ó sinmi díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ fúngbà díẹ̀ láti lè gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ nígbà tí ó wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ní ọdún 2011. Ó bẹ̀rẹ̀.sí ń gbé eré tirẹ̀ ná .jáde ní ọdún 2016, nígba tí ó kọ́kọ́ gbé eré sinimá bí [1] Road to Ruin,[5] pẹ́lú ìrànlọ̀wọ̀ àj9 rẹ̀ tí ó dá sílẹ̀. Ó gbé eré yí jáde láti lè ta ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jí kí eọ́n lè ma pèsè iṣẹ́ gidi fún àwọn ọ̀dọ́ langba tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmò ìjìnlẹ̀ gbogbo. [3][6][5]
Àwọn eré àgbéléwò rẹ̀
àtúnṣeEré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀
àtúnṣeỌdún | Àkòrí eré | Ipa rẹ̀ | Olùgbéré-jáde àti Adarí eré | Notes |
---|---|---|---|---|
2011 | Tinsel | Co-star | Tope Oshin Ogun | Mnet TV series |
2011 | Burning Spear | Lead | Akin Akindele | TV Drama Series |
2011 | Circle of Interest | Co-star | Kalu Anya | TV Series |
2012 | Shadows | Lead | Tunde Olaoye | TV Series |
2014 | Nectar | Co-star | Sola Sobowale | TV Series |
2015 | This Life | Supporting Role | Wale Adenuga | TV Series |
2016 | Jenifa's Diary | Co-star | Funke Akindele | Sitcom |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Fisayo Ajisola To Consolidate On Acting Career In 2016". Leadership. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ Amu, P (25 April 2016). "I Like Playing Crazy and Sexy Roles". AM Update. Archived from the original on 18 September 2016. https://web.archive.org/web/20160918042239/http://amupdate.com/2016/04/25/i-like-playing-crazy-and-sexy-roles-fisayo-ajisola/. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 Ebere, P (25 April 2016). "Meet Fisayo Ajisola a young Humanitarian, intelligent, pretty and excellent Actor...". Nigeria Films. https://www.nigeriafilms.com/movie-news/105-upcoming-celebrities/18879-meet-fisayo-ajisola-a-young-humanitarian-intelligent-pretty-and-excellent-actor. Retrieved 30 September 2016.
- ↑ Ogun, Tade (10 February 2016). "How I cope with male admirers - Fisayo Ajisola". Encomium Magazine. http://encomium.ng/how-i-cope-with-male-admirers-actress-fisayo-ajisola/. Retrieved 30 September 2016.
- ↑ 5.0 5.1 "Nollywood actress, Fisayo, produces first movie ‘Road To Ruin’". Nigerian Tribune. 11 September 2016. http://tribuneonlineng.com/nollywood-actress-fisayo-produces-first-movie-road-ruin/. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ "Fisayo Ajisola out with new movie". New Telegraph. 18 September 2016. Archived from the original on 24 September 2016. Retrieved 23 September 2016.