Fish Oil (Òróró Ẹja)


Òróró ẹja jẹ́ ìran òróró kan tí wọ́n ma ń rí láti ara àwọn ẹja tí wọ́n lọ́ràá. Òróró ẹja yí ma ń ní àwọn èròjà aṣaralóore Flomega-3 tí ó ma ma ń fún ara ní ọ̀rá tí ó péye. Lára àwọn aṣaralóore yí ni eicosapentaenoic acid (EPA) à, docosahexaenoic acid (DHA) àti eicosanoids tí ó tyn jẹ́ èròjà kannpàtàkì tí ó ma ń mú àdínkù bá àrùn jẹjẹrẹ nínú àgọ́ ara ọmọ ènìyàn tí ó sì tún ma ń dẹ́kun àwọn ohun tí wọ́n ma ń rú jẹjẹrẹ sókè ní àgọ́ ara, bákan náà ni ó ma ń mú àlékún bá èròjà hypertriglyceridemia nínú ara.[1][2] Oríṣiríṣi ariyanjiyan ni ó ti wáyé látẹnu àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ònímọ̀ ìlera lórí ànfaní òróró ẹja nípa ṣíṣe ìwòsàn fún àìsàn ọkàn . Púpọ̀ nínú wọn ni wọ́n fara mọ wípé òróró ẹja ọlọ́ràá dára fún ìwòsàn àìsàn ìdádúró ọkàn.[3] Wọ́n ti ṣe ìwádí siwájú si lórí òróró ẹja ọlọ́ràá àti Omega-3 pẹ́lú agbára rẹ̀ láti ṣe ìwòsàn fún ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,[4][5] ìbẹ̀rù,[6][7][8] àrùn jẹjẹrẹ, àwọn iṣan ara tó ń daaẹ́ sílẹ̀ nínú agọ́ ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọn kò tí ì wípé fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé òróró sha lè yanjú àwọn ìpèníjà ara tí ati mẹ́nu bá lókè wọ̀nyí.

Àwọn ẹja tí wọ́n jẹ́ ẹja ọlọ́ràá tí wọ́n ma ń rí èròjà Omega-3 lára wọn yàtọ̀ sí àwọn ẹja tí a ń sè jẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹja tí wọ́n ń pèsè èròjà Omega-3 wọ̀nyí ma ń jẹ́ ẹja tó gbé tàbí jẹ irúfẹ́ ẹja tí wọ́n ní ọ̀rá omega-3 fatty acid. Àwọn ẹja bíi ẹja shark swordfish, ẹja tilefish ati ẹja albacore tuna ni wọ́n sábà ma ń ní ọ̀rá Omega-3 lára, àmọ́ látàrí ipò àwọn ẹja wọ́nyí nínú ibú omi wọ́n sábà ma ń jẹ àwọn ẹja míràn tí wọ́n ní májèlé tí wọ́n pè ní biomagnification lára nínú omi látara biomagnification. Fúndí èyí, àwọn àjọ tí wọ́n ń rí sí ìlera ọmọnìyàn United States Environmental Protection Agency gba gbogbo àwọn obìnrin àwùjọ tí wọn ṣì ń ṣabiyamọ ní imọ̀ran láti yẹra fún jíjẹ irúfẹ́ àwọn ẹja bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà nítorí àpọ̀jù àwọn májèlé bí mecury tí ó pò ní ara àwọn ẹja tí a ti mẹ́nu bà ṣáájú.[9]

Amọ ni nkan bi ọdun 2019, àjọ Food and Drug Administration (FDA) fọwọ́ sí àwon oògùn kan bíi Lovaza, Omtryg (àtiomega-3 acid ethyl esters), Vascepa (ethyl eicosapentaenoic acid), pẹ̀lú Epanova (omega-3 carboxylic acids).[10] gẹ́gẹ́ bí oògùn àtọwọdá tí ó dára tí wọ́n pèsè gẹ́gẹ́ bí òróró ẹja àgbélẹ̀rọ tí ó sì ní àwọn èròj̀à ásíìdì tí ó wúlò fún ara.

Àwọn ìtọ́ka sí àtúnṣe

  1. Moghadasian, Mohammed H. (2008). "Advances in Dietary Enrichment with N-3 Fatty Acids". Critical Reviews in Food Science and Nutrition 48 (5): 402–10. doi:10.1080/10408390701424303. PMID 18464030. 
  2. Cleland, Leslieg; James, Michaelj; Proudman, Susannam (2006). "Fish oil: What the prescriber needs to know". Arthritis Research & Therapy 8 (1): 679–81. doi:10.1186/ar1876. PMC 1526555. PMID 16542466. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=1526555. 
  3. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named half full
  4. Su, Kuan-Pin; Huang, Shih-Yi; Chiu, Chih-Chiang; Shen, Winston W. (2003). "Omega-3 fatty acids in major depressive disorder". European Neuropsychopharmacology 13 (4): 267–71. doi:10.1016/S0924-977X(03)00032-4. PMID 12888186. 
  5. Naliwaiko, K.; Araújo, R.L.F.; Da Fonseca, R.V.; Castilho, J.C.; Andreatini, R.; Bellissimo, M.I.; Oliveira, B.H.; Martins, E.F. et al. (2004). "Effects of Fish Oil on the Central Nervous System: A New Potential Antidepressant?". Nutritional Neuroscience 7 (2): 91–99. doi:10.1080/10284150410001704525. PMID 15279495. 
  6. Green, Pnina; Hermesh, Haggai; Monselise, Assaf; Marom, Sofi; Presburger, Gadi; Weizman, Abraham (2006). "Red cell membrane omega-3 fatty acids are decreased in nondepressed patients with social anxiety disorder". European Neuropsychopharmacology 16 (2): 107–13. doi:10.1016/j.euroneuro.2005.07.005. PMID 16243493. 
  7. Yehuda, Shlomo; Rabinovitz, Sharon; Mostofsky, David I. (2005). "Mixture of essential fatty acids lowers test anxiety". Nutritional Neuroscience 8 (4): 265–67. doi:10.1080/10284150500445795. PMID 16491653. 
  8. Nemets, B.; Stahl, Z; Belmaker, RH (2002). "Addition of Omega-3 Fatty Acid to Maintenance Medication Treatment for Recurrent Unipolar Depressive Disorder". American Journal of Psychiatry 159 (3): 477–79. doi:10.1176/appi.ajp.159.3.477. PMID 11870016. 
  9. Venus Nandi (2020-02-09). "Best fish to eat". Retrieved 9 February 2020. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  10. Skulas-Ray, Ann C.; Wilson, Peter W.F.; Harris, William S.; Brinton, Eliot A.; Kris-Etherton, Penny M.; Richter, Chesney K.; Jacobson, Terry A.; Engler, Mary B. et al. (2019). "Omega-3 Fatty Acids for the Management of Hypertriglyceridemia: A Science Advisory From the American Heart Association". Circulation 140 (12): e673–e691. doi:10.1161/CIR.0000000000000709. PMID 31422671.