Folasade Ogunsola
Folasade Tolulope Ogunsola OON (ni a bí ní ọdún 1958) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ òògùn microbiology ní orile- ede Naijiria, àti Gíwá Yunifásitì Èkó . Ó ṣe àmọ̀jaá ni ìṣàkóso àrùn, pàápàá HIV/AIDS . Ògúnṣọlá jẹ́ provost ti College of Medicine Yunifásitì Èkó àti obìnrin àkọ́kọ́ tí ó di ipò náà mú. Ó tún jẹ́ ìgbákejì Gíwá (Isẹ́ Ìdàgbàsókè) Yunifásitì náà láàárín ọdún 2017 ati 2021. [2] [3] Arábìnrin náà jẹ́ àdèlé Gíwá Yunifásitì náà fún ìgbà díẹ̀ ní ọdún nígbà tí Yunifásítì náà ń la aáwọ̀ kọjá èyí tí ó yọrí sí yíyọ Gíwá àkókò náà nípò.
Folasade Ogunsola | |
---|---|
13th Vice Chancellor of the University of Lagos | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 12 November 2022 | |
Asíwájú | Oluwatoyin Ogundipe |
Deputy Vice Chancellor (Development Services), University of Lagos | |
In office 2017–2021 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Folasade Tolulope Mabogunje 1958 (ọmọ ọdún 65–66) |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Alma mater | College of Medicine, Unilag (Masters in Medical microbiology) College of Medicine, University of Wales, Cardiff (Doctor of Philosophy in Medical microbiology) |
Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti Ẹ̀kọ́
àtúnṣeÌlé ìwé Yunifásitì Ìbàdàn ni Fọláṣadé Ògúnṣọlá dàgbà sí níbi tí bàbá, Akin Mabogunje ti jẹ́ olùkọ́. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọdé, ó máa ń sín àwọn onímọ̀ ògùn jẹ nípa lílo àwọn ọmọlangidi gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣàìsàn tí yóò sì máa ṣe bí ẹni pé ó ń tọ́jú wọn. Queen's College, Lagos ni ó ti ka ẹ̀kọ́ girama. [4] Láàárín 1974 àti 1982, ó gba oyè àkọ́kọ́ rẹ̀ láti Yunifásitì of Ifè . [5] àti oyè másítáàsì láti College of Medicine, Yunifásitì Èkó, lẹ́yìn ìtẹ̀síwájú fún oyè Ph.D. rẹ̀ ní University of Wales láàárín 1992 àti 1997.
Iṣẹ́-ṣíṣe
àtúnṣeÒgúnṣọlá j àdèlé Gíwá Yunifásitì Èkó fún ìgbà díẹ̀ lọ́dún 2020 nígbà ti Yunifásítì náà wọ inú wàhálà látàrí bí ìgbìmọ̀ Yunifásitì wọn ṣe yọ Gíwá Yunifásitì Èkó ní àkókò náà. Arábìnrin náà tún jẹ́ ìgbákejì Gíwá fún (iṣẹ́ ìdàgbàsókè) kí ó tó di àdèlé Gíwá Yunifásitì náà. [6] Ṣáájú kí ó tó jẹ́ Gíwá, ó jẹ́ alákóso College of Medicine, University of Lagos, àti olórí ẹka ẹ̀kọ́ ti Microbiology Medical, College of Medicine, Yunifásitì Èkó. Agbègbè ìwádìí rẹ̀ dálé ìṣàmójútó àti ìṣàkóso àwọn àrùn bíi HIV . Ó jẹ́ olórí olùṣèwádìí ní Ètò Ìdènà Àrùn Kògbóògùn Èédì ní Nàìjíríà (APIN) ní Yunifásitì Èkó. Ó tún ti jẹ́ alága ìgbìmọ̀ ìdarí ìkápá àrùn àkóràn ti ilé ìwòsàn ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Yunifásítì Èkó . Ní àfikún, ó jẹ́ alága ti National Association of Colleges of Medicine ní Nàìjíríà láti 2014 - 2016. [7]
Ní ọdún 2018, ó sọ̀rọ̀ sókè nípa kùdìẹ̀kudiẹ ti ìdènà àti ìṣàkóso àrùn ní Nàìjíríà. Ó tọ́ka sí àìní ìmọ́tótó àti ìlòkulò òògùn apakòkòrò gẹ́gẹ́ bíi àtìlẹ́yìn fún atakò-oògùn apakòkòrò. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ, ó sàlàyé pé “ìbójútó Ìdènà Àrùn àti Ìṣàkóso àrùn (IPC) nípa kíkọ́ àwọn amáyédẹrùn àti ṣíṣe àwọn ètò yẹ kí ó wà ní àyíká pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà, kíkọ́, ìṣàmójútó, àti lílo àwọn ìlànà multimodal fún ìmúṣe IPC, ìbójútó àti ìgbéléwọ̀n láàárín àwọn mìíràn”. Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ lákòkò ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn oníròyìn, ó sàlàyé pé ojútùú láti dínkù òṣùwọ̀n àìníṣẹ́ 58% ni fún àwọn àkókò jáde ilé-ìwé gíga Nàìjíríà láti máa ṣe ohun tuntun tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ayé ẹ̀dá láwùjọ. Ó tún ṣàkíyèsí pé ìmọ̀ fúnra rẹ̀ kò tó, ṣùgbọ́n ìlò rẹ̀ lọ́nà yíyẹ láti mú kí ìdàgbàsókè bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn láwùjọ ni ohun tí ó yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ bìkítà fún.
Arábìnrin náà wà lára àwọn olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Àwùjọ Nàìjíríà fún ìṣàkóso àrùn ní ọdún 1998 àti ọmọ ẹgbẹ́ ti Global Infection Prevention and Control Network [8]
Wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí àdèlé Gíwá Yunifásítì ti Èkó ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2020. Ó di obìnrin àkọ́kọ́ láti jẹ́ Gíwá Yunifásitì Èkó nínú ìtàn ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà.
Ní Oṣù Karùn-ún ọdún 2023, ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ìgbàkan Muhammadu Buhari yẹ́ Ògúnṣọlá sí nípa bíbu ọlá fun gẹ́gẹ́ bi Oṣiṣẹ ti aṣẹ ti Niger.
Àwọn àtẹ̀jáde
àtúnṣe- Ìyípadà ti Ọna Ribotyping PCR kan fun Ohun elo gẹgẹbi Eto Titẹ Iṣe deede fun Clostridium difficile , 1996 [9]
- Awọn akoran ti o ṣẹlẹ nipasẹ awọn eya Acinetobacter ati ifaragba wọn si awọn egboogi 14 ni Lagos University Teaching Hospital, Lagos, 2002 [10]
- Awọn iwa ti Awọn Olupese Itọju Ilera si Awọn eniyan Ngbe pẹlu HIV/AIDS ni Ipinle Eko, Nigeria, 2003 [11]
- Extended-Spectrum β-Lactamase Enzymes ni Ile-iwosan Isolates of Enterobacter Species lati Lagos, Nigeria, 2003 [12]
- Awọn okunfa ewu fun oyun ectopic ni Lagos, Nigeria, 2005 [13]
- Awọn italaya fun ilera ibalopo ati gbigba awujọ ti awọn ọkunrin ti o ni ibalopọ pẹlu awọn ọkunrin ni Nigeria, 2007 [14]
- Awọn okunfa ewu ti o ni ibatan ati pulsed field gel electrophoresis ti awọn isolates imu ti Staphylococcus aureus lati ọdọ awọn ọmọ ile-iwe iṣoogun ni ile-iwosan giga ni Lagos, Nigeria, 2007 [15]
- Imudara ti gelulose sulfate abẹ inu fun idena ti ikolu HIV: awọn abajade ti idanwo Ipele III ni Nigeria, 2008 [16]
- Awọn ipa ti itọju ailera antimicrobial lori vaginosis kokoro-arun ni awọn obirin ti kii ṣe aboyun, 2009 [17]
- Alailagbara egboogi ati awọn serovars ti Salmonella lati awọn adie ati awọn eniyan ni Ibadan, Nigeria, 2010 [18]
- Awọn iwa ti methicillin-ni ifaragba ati staphylococci-sooro ni ile-iwosan: iwadi ile-iṣẹ pupọ ni Nigeria, 2012 [19]
- Idena ikolu ti o ni ipa ti agbegbe ati ọna iṣakoso si Ebola, 2015 [20]
Àwọn Ìtọ́kasí ìta
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Times, Premium (2023-05-29). "FULL LIST: Special Nigeria National Honours Awards 2023". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-01.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "QC unveils Hall of Fame, solar water project". December 15, 2016. https://www.vanguardngr.com/2016/12/qc-unveils-hall-of-fame-solar-water-project/.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ O'Neill, G. L.; Ogunsola, F. T.; Brazier, J. S.; Duerden, B. I. (1996-08-01). "Modification of a PCR Ribotyping Method for Application as a Routine Typing Scheme for Clostridium difficile" (in en). Anaerobe 2 (4): 205–209. doi:10.1006/anae.1996.0028. ISSN 1075-9964. https://www.sciencedirect.com/science/article/pii/S1075996496900281.
- ↑ Iregbu, K. C.; Ogunsola, F. T.; Odugbemi, T. O. (2002). [free "Infections caused by Acinetobacter species and their susceptibility to 14 antibiotics in Lagos University Teaching Hospital, Lagos"] (in en). West African Journal of Medicine 21 (3): 226–229. doi:10.4314/wajm.v21i3.28036. ISSN 0189-160X. free.
- ↑ Adebajo, Sylvia Bolanle; Bamgbala, Abisola O.; Oyediran, Muriel A. (2003). "Attitudes of Health Care Providers to Persons Living with HIV/AIDS in Lagos State, Nigeria". African Journal of Reproductive Health 7 (1): 103–112. doi:10.2307/3583350. ISSN 1118-4841. https://www.jstor.org/stable/3583350.
- ↑ Aibinu, I. E.; Ohaegbulam, V. C.; Adenipekun, E. A.; Ogunsola, F. T. (2003-05-01). [free "Extended-Spectrum β-Lactamase Enzymes in Clinical Isolates of Enterobacter Species from Lagos, Nigeria"] (in en). Journal of Clinical Microbiology 41 (5): 2197–2200. doi:10.1128/JCM.41.5.2197-2200.2003. ISSN 0095-1137. free.
- ↑ Anorlu, Rose I.; Oluwole, Ayodeji; Abudu, Olalekan Olantunji; Adebajo, Sylvia (February 2005). "Risk factors for ectopic pregnancy in Lagos, Nigeria: Risk factors for ectopic pregnancy in Lagos" (in en). Acta Obstetricia et Gynecologica Scandinavica 84 (2): 184–188. doi:10.1111/j.0001-6349.2005.00684.x. http://doi.wiley.com/10.1111/j.0001-6349.2005.00684.x.
- ↑ Allman, Dan; Adebajo, Sylvia; Myers, Ted; Odumuye, Oludare (2007-03-01). "Challenges for the sexual health and social acceptance of men who have sex with men in Nigeria". Culture, Health & Sexuality 9 (2): 153–168. doi:10.1080/13691050601040480. ISSN 1369-1058. https://doi.org/10.1080/13691050601040480.
- ↑ Adesida, Solayide A.; Abioye, Olusegun A.; Bamiro, Babajide S.; Brai, Bartholomew I. C. (February 2007). [free "Associated risk factors and pulsed field gel electrophoresis of nasal isolates of Staphylococcus aureus from medical students in a tertiary hospital in Lagos, Nigeria"]. Brazilian Journal of Infectious Diseases 11 (1): 63–69. doi:10.1590/S1413-86702007000100016. ISSN 1413-8670. free.
- ↑ Halpern, Vera; Ogunsola, Folasade; Obunge, Orikomaba; Wang, Chin-Hua (2008-11-21). [free "Effectiveness of Cellulose Sulfate Vaginal Gel for the Prevention of HIV Infection: Results of a Phase III Trial in Nigeria"] (in en). PLOS ONE 3 (11): e3784. doi:10.1371/journal.pone.0003784. ISSN 1932-6203. free.
- ↑ Oduyebo, Oyinlola O; Anorlu, Rose I; Ogunsola, Folasade T (2009-07-08). "The effects of antimicrobial therapy on bacterial vaginosis in non-pregnant women" (in en). Cochrane Database of Systematic Reviews (3): CD006055. doi:10.1002/14651858.CD006055.pub2. http://doi.wiley.com/10.1002/14651858.CD006055.pub2.
- ↑ Kayode, F.; Folasade, O.; Frank, M. A.; Rene, S. H. (2010-05-05). "Antimicrobial susceptibility and serovars of salmonella from chickens and humans in ibadan, nigeria" (in en). Journal of Infection in Developing Countries. ISSN 1972-2680. https://ir.unilag.edu.ng/handle/123456789/7015.
- ↑ Shittu, Adebayo; Oyedara, Omotayo; Abegunrin, Fadekemi; Okon, Kenneth (2012-11-02). [free "Characterization of methicillin-susceptible and -resistant staphylococci in the clinical setting: a multicentre study in Nigeria"] (in en). BMC Infectious Diseases 12 (1): 286. doi:10.1186/1471-2334-12-286. ISSN 1471-2334. free.
- ↑ Marais, Frederick; Minkler, Meredith; Gibson, Nancy; Mwau, Baraka (2016-06-01). [free "A community-engaged infection prevention and control approach to Ebola"] (in en). Health Promotion International 31 (2): 440–449. doi:10.1093/heapro/dav003. ISSN 0957-4824. free.