Frank Edwards

Olorin ihinrere Naijiria

Frank Ugochukwu Edwards (tí a bí ní 22nd July, 1989) jẹ́ olórin Naijiria, amojú ẹ̀rọ ohùn, akọrin ìjọsìn àti akọrin láti Ipinle Enugu.[1] Oùn ni olùdásílẹ̀ àti Aláṣẹ ilé ilé-isé akọrin Rocktown Records, èyí tí ó jẹ́ ilé iṣẹ̀ fún àwọn oṣere bíi Edwards funrararẹ̀, Gil Joe, King BAS, Nkay, Dudu àti, láàrin àwọn mìíràn. O ń gbé ní Lagos, Nigeria.

Frank Edwards
Background information
Orúkọ àbísọFrank Ugochukwu Edwards
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiFrankRichboy
Ọjọ́ìbí22 Oṣù Keje 1989 (1989-07-22) (ọmọ ọdún 35)
Ìbẹ̀rẹ̀Enugu State, Nigeria
Irú orin
Occupation(s)
Instruments
  • Vocals
  • piano
  • drums
  • guitar
Years active2007–present
LabelsRocktown
Websitefrankincense.world

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Frank Ugochukwu Edwards ni a bí sínú ìdílé ènìyàn méje ní Ìpínlẹ̀ Enugu ni Naijiria. Ó ní àwọn arákùnrin márùn-ún. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ní ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó sì kọ́ bí a ṣe ń lu dùrù láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé.[2][3] Nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ́langba, ó di àtúnbí Kìrìsìtẹ́nì.[4][5] Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwo-orin ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orin kọlu ní orúkọ rẹ̀. Ó ti fi ara rẹ̀ mulẹ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan nínú olorin ìhìnrere tí ó dára jùlọ ní Nàìjíría.[6][7][8]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórin

àtúnṣe

Edwards jẹ́ olórin tó máa ń gbé orin jáde pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ sì ni ó mọ bí wọ́n ti ń lo oríṣiríṣi ohun èlò orin. Ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí atẹ-dùrù tí ó sì tún jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ àkọrin ti ìjọ Pásìtọ̀ Chris Oyakhilome ti Christ Embassy. Àwo-orin rẹ̀ àkọ́kọ́ ni The Definition tó jáde ní ọdún 2008. Ó jẹ́ àwo olórin mẹ́rìnlá, èyí tí ilé-iṣẹ́ Honesty Music gbé jáde.[9] Àwo-orin rẹ̀ kejì ni Angels on the Runway, tó jáde ní ọdún 2010, pẹ̀lú àwo-orin rẹ̀ kẹta Unlimited, tó jáde ní ọdún 2011. Tagjam jáde ní oṣù Kọkànlá ọdún 2011. Ní ọdún 2013, ó farahàn níbi ayẹyẹ Sinach, fún fọ́nrán orin "I know who I am". Ó gbajúmọ̀ fún ohùn rẹ̀ tó já geere. Yàtọl sí pé ó jẹ́ olórin tó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin, ó sì tún máa ń ṣagbátẹrù orin, tí á tún gbé wọn jáde. Òun ni ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Rocktown Records, tí ó sì ní àwọn olórin bí i Gil Joe, King BAS, Divine, Nkay, Soltune, David àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ilé-iṣẹ́ náá̀.[10][11] Ní ọdún 2016, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbajúgbajà olórin ilẹ̀ America kan, ìyẹn Don Moen, lóri àwo-orinGrace. Àwo-orin rẹ̀, ìyẹn Frankincense jáde ní ọdún 2016.[12] Ní ọdún 2018, ó gbé àwo-orin mìíràn jáde, ìyẹn Spiritual Music Season, níbi tí ó ti kọ àwọn orin bí i "Miyeruwe" (Mo máa yin orúkọ rẹ̀), "You are Good", "Who dey run things" àti "Praise Your Name". Ní ọdún 2018 bákan náà, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Nathaniel Bassey, fún orin (Thy Will Be Done) àti Jeanine Zoe, fún orin (I'm in Love with You).

Ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kìrìtẹ́ẹ́nì

àtúnṣe

Edwards (tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Frankrichboy) jẹ́ ọmọ-ìjọ Christ Embassy ní Nàìjíríà àti LoveWorld Music Ministry pẹ̀lú àwọn olórin bí i Moses Bliss, Ada Ehi, Sinach, Eben, Joe praize.[13]

Àwọn àwo orin

àtúnṣe
  • Definition (2008)
  • Release Singles (2015)
  • Frankincense (2016)
  • Birthday EP (2016)
  • Born in July (2017)
  • Unlimited – Verse 1 (2017)
  • I'm Supernatural (2018)
  • In Love With You (2018)
  • Unlimited – Verse 2 (2018)
  • Born in July (2019)
  • Believers Anthem (2020)
  • No One Like You (2020)
  • Melody Album (2022)

Àṣàyàn fídíò orin

àtúnṣe
Ọdún Akọ́lé Olùdarí Ìtọ́ka
2010 Beautiful
2010 You Too Dey Bless Me feat. TB1 Gbenga Salu
2011 Oya Moshman
2011 Oghene Doh Moshman
2011 This Love Patrick Elis
2014 Okaka Lawrence Omo-Iyare [14]
2014 Hallelujah Frank Edwards
2015 Onye St. Immaculate [15]
2016 Grace Don Moen & Frank Edwards
2017 Here to Sing feat. Chee Frank Edwards
2019 If Not For You[16] H2O Films
2020 Believers Anthem[17] H2O Films
2020 Suddenly[18] H2O Films
2020 No Other Name Frank Edwards
2020 Logo[19] Frand Edwards
2020 Opomulero[20] H2O Films
2020 ME[21] H2O Films

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ

àtúnṣe

Ní oṣù Karùn-ún ọdún 2011, wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ olórin ẹ̀mí tó dára jù lọ ní Nàìjíríà, níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards (NEA) ẹlẹ́ẹ̀kẹfà. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Gospel Rock artiste.[22][23] Bẹ́ẹ̀ sì ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ west Africa best male vocalist ní ọdún 2012/ best hit single ní Love World Awards 2012, àti àmì-ẹ̀yẹ mẹ́ta mìíràn ní Nigeria Gospel Music Awards (male artiste of the year, song of the year and best male vocal).[24][25] Àwo-orin rẹ̀, ìyẹn Frankincense, níbi tí ó ti ṣe àfihàn Micah Stampley àti Nathaniel Bassey, wà lórí àtẹ iTunes, ní èyí tó kọja àwo-orin Beyoncé and àti ti Adele lọ.[26]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Empty citation (help) 
  2. mogbeni (2015-04-01). "SPOTLIGHT: Frank Edwards - The Future". Xclusive Gospel (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 16 August 2024. Retrieved 2023-11-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Odinaka (2016-02-01). "Women are Putting me Under Pressure - Gospel Singer, Frank Edwards Opens Up". Tori.ng (in English). Archived from the original on 8 November 2023. Retrieved 2023-11-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "#MCM- Frank Edwards- My Story – The Inspire Series by Glory Edozien" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 November 2023. Retrieved 2023-11-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Sesan (2016-07-30). "No rivalry between Frank Edwards and me –Joe Praize". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 November 2023. Retrieved 2023-11-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Frank Edwards". Genius (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 November 2023. Retrieved 2023-11-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "Frank Edwards' Frankincense drops April 25 - The Nation Newspaper". Archived from the original on 8 November 2023. Retrieved 8 November 2023.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "Frank Edwards awards top graduands from MTNF-Mus". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-07-22. Archived from the original on 16 August 2024. Retrieved 2023-11-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Nigeria: The Emergence of Love World Records". allafrica.com. Archived from the original on 28 September 2013. Retrieved 2 August 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. Olujobi, Debbie (14 October 2012). "The soul speaks". Vanguard. Lagos, Nigeria. Archived from the original on 5 July 2019. Retrieved 5 June 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  11. Nkem-Eneanya, Jennifer (24 June 2013). "Frank Edwards; the Young, Gifted Gospel Artiste Taking Africa for God". Konnectafrica.net. Konnect Media. Archived from the original on 3 June 2014. Retrieved 5 June 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named frankie62
  13. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named LOV
  14. "Gospel Artiste, Frank Edwards Release New Video, Okaka • Connect Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 4 February 2014. Archived from the original on 8 August 2016. Retrieved 5 August 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  15. "Frank Edwards Singer shares his life story in 'Onye' [Video]". Pulse.com.gh. Joey Akan. 23 July 2015. Archived from the original on 12 March 2016. Retrieved 22 February 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  16. "Frank Edwards - IF NOT FOR YOU #frankedwards #rocktown #gospelmusic #ifnotforyou - YouTube". 7 November 2019. Archived from the original on 19 January 2021. Retrieved 6 January 2021 – via YouTube.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  17. "Frank Edwards - BELIEVERS ANTHEM #frankedwards #rocktown #gospelmusic #anthem - YouTube". 14 January 2020. Archived from the original on 1 October 2020. Retrieved 6 January 2021 – via YouTube.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  18. "Frank Edwards - Suddenly - #frankedwards #rocktown #gospelmusic Rocktown Music 2020 - YouTube". 20 March 2020. Archived from the original on 30 November 2020. Retrieved 6 January 2021 – via YouTube.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  19. "Frank Edwards - LOGO OFFICIAL VIDEO #frankedwards #rocktown #gospelmusic - YouTube". Archived from the original on 18 January 2021. Retrieved 6 January 2021 – via YouTube.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  20. "Frank Edwards - OPOMULERO #frankedwards #rocktown #gospelmusic - YouTube". 14 June 2020. Retrieved 6 January 2021 – via YouTube. 
  21. "ME - FRANK EDWARDS #frankedwards #rocktown #gospelmusic - YouTube". July 2020. Archived from the original on 6 November 2020. Retrieved 6 January 2021 – via YouTube.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  22. "Nigeria Entertainment Awards nominees 2011.". museke.com. Archived from the original on 10 August 2011. Retrieved 2 August 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  23. "NEA Awards 2011 Nomination Party, Themed: Casino Celebrity Night". connectnigeria.com. Archived from the original on 18 June 2011. Retrieved 2 August 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  24. "Frank Edwards emerges Best Male Gospel Artiste". Mydailynewswatchng.com. 13 July 2013. Archived from the original on 5 June 2014. Retrieved 5 June 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  25. Arinze, Ada (8 July 2013). "Frank Edwards Bags Best Male Gospel Artiste Award". Connectnigeria.com. Archived from the original on 6 June 2014. Retrieved 5 June 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  26. "Frank Edwards Songs, Videos, Lyrics and Bio". zionlyrics.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 24 February 2021. Retrieved 28 May 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)