Frederick Fáṣeun
Frederick Isiotan Fáṣeun ni wọ́n bí ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kẹsàán ọdún 1935,(21-9-1935 – 1-12-2018) jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó, adarí àti Alága gbogbo gbò fún Ẹgbẹ́ Oòdua (OPC) ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]
Ètò ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onímọ̀ ìṣègùn Òyínbó
àtúnṣeÓ kẹ́kọ́ ní Ilé-ẹ̀kọ́ Blackburn College tí ó sì tẹ̀ síwájú ní Ilé-ẹ̀kọ́ Aberdeen University tí ó jẹ́ Ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn . Ó tún kẹ́kọ́ ní ìlú Liverpool ní ilé-ẹ̀kọ́ alafikún (Postgraduate School),ṣáájú kí ó tó di ọmọ ẹgbẹ́ ní Royal College of Surgeons. Ní ọdún 1976,ó lọ kẹ́kọ́ nípa acupuncture ní ílù China nípasẹ̀ ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí àjọ Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé kalẹ̀ pẹ̀lú ífọwọ́sowọ́pọ àjọ United Nations [1].
Ipa rẹ̀ nínú Ìṣèlú
àtúnṣeNí ọdún 1977, ó gbé ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Acupuncture lọ sí Lagos University Teaching Hospital. Ó kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1978, tó si da Ilé ìwòsàn (Besthope Hospital and Acupuncture Centre) ní ìpílẹ̀ Èkó. Ilé ìwòsàn yí gbayì gẹ́gẹ́ bí àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ó dá Ẹgbẹ́ Oòduà (OPC) sílẹ̀ láti mú ìran ìjáwé olúborí olóògbé Moshood Káṣìmawó Ọláwálé Abiọ́lá, tí ó jẹ́ ọmọ Yorùbá tí ó ja we olúborí nínú ètò ìdìbò Ọjàọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà ọdún 1993. Àmọ́ tí ìjọba ológun tí Ibrahim Babangida dojú ìborí náà délẹ̀. Wọ́n gbé Fáṣeun, wọ́n sì tí mọ́lẹ́ fún oṣù mọ́kàndínlógún láti ọdun 1996-1998, lábẹ́ ìjọba ọ̀gágun Sani Abacha. [2]
Ikú rẹ̀
àtúnṣeFáṣeun dolóògbé ní Ilé ìwòsàn Lagos State University Teaching Hospital, ní ìlú Ikeja, ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Frederick Isiotan Fasehun at 77". ThisDay Live. 23 September 2012. Archived from the original on 18 April 2015. https://web.archive.org/web/20150418154610/http://www.thisdaylive.com/articles/frederick-isiotan-fasehun-at-77/125719/. Retrieved 18 March 2015.
- ↑ Karl Maier. This House Has Fallen: Midnight in Nigeria. ISBN 1-891620-60-6. https://archive.org/details/thishousehasfall00maie.
- ↑ Editor. "BREAKING: OPC founder, Frederick Fasehun, dies at 83". Punch. Retrieved 1 December 2018.