M. K. O. Abíọ́lá

Olóṣèlú

Moshood Káṣìmawòó Ọláwálé Abíọ́lá (August 24, 1937 - July 7, 1998) tí ó túmọ̀ sí M.K.O Abíọ́lá jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. A bi ní ìlú Abẹ́òkútaÌpínlẹ̀ Ògùn. Ó jẹ́ oníṣòẁò,òǹtẹ̀wé, olóṣèlú àti olóyè ilẹ̀ Yorùbá Ẹ̀gbá pàtàpátá.[2] Ó díje sípò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1993, òun náà sì ni gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ tí wọ́n sì fẹnukò sí jákè-jádò orílẹ-èdè Nàìjíríà wípé ó jáwé olúborí nígbà tí olóri ìjọba ológun ìgbà náà Ibrahim Babangida kò kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olúborí ètò ìdìbò náà tí ó sì fi ẹ̀sùn àìṣòtítọ́ àti àìṣòdodo ètò ìdìbò yàn náà. M.K.O kú ní ọdún 1998. [3][4]

Moshood Abiola
Ọjọ́ìbí(1937-08-24)24 Oṣù Kẹjọ 1937
Abeokuta
Aláìsí7 July 1998(1998-07-07) (ọmọ ọdún 60)
Abuja
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Orúkọ mírànM.K.O Ab́iọ́lạ́
Iṣẹ́Okowo, Oloselu, Oluranilowo.
Gbajúmọ̀ fúnBeing arrested following a Presidential election in Nigeria which he won/Philanthropy
Olólùfẹ́Simbiat Atinuke Shoaga
Kudirat Olayinka Adeyemi
Adebisi Olawunmi Oshin
Doyinsola Abiola Aboaba
Modupe Onitiri-Abiola [1]
Remi Abiola
(+other women)
Àwọn ọmọAbdulateef Kola Abiola
Dupsy Abiola
Hafsat Abiola
Rinsola Abiola
Khafila Abiola
(+other children)

Igbesi Aye re àtúnṣe

Moshood Abíọ́lá ni àkọ́bí  bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìkúnlẹ̀ ọmọ kẹtàlélógún, ìdí èyí ní ó fàá tí wọ́n fi dúró títí di ẹ̀yìn ọdún mẹ́ẹ̀dógún (15 years) kí àwọn òbí rẹ̀ tó fún lórúkọ rẹ̀ “Kasimawo”[5] . Moshood fakọyọ nínú ìmọ̀ ìdágbálé (entrepreneur) láti ìgb̀a èwe rẹ̀, ó bẹ̀rè iṣẹ́ igi-ṣíṣẹ́ tà láti ọmọ ọdún mẹ́sàán. Ó ma ń jí ní ìdájí lọ sóko igi láti wági tí yóò tà ṣáájú kí ó tó lọ sị́ ilé-ìwé kí òun àti bàbá rẹ̀ tó ti rúgbo pẹ̀lú àwọn àbúrò rẹ̀ kó lè rówó ná. Nígb̀a tí ó t́o ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún (15 years), ó dá ẹgbẹ́ eré kan kalẹ̀ tí wọ́n ma ń kọrin kiri láti lè rí óúnjẹ jẹ níbi ìnáwo èyíkéyìí tí wọ́n bá lọ. Láìpẹ́, ó di gbajú-gbajà níbi orin rẹ̀ tó ń kó kiri, ó sì di ẹni tí ó ń bèrè fún owó iṣẹ́ kí wọ́n tó kọrin lóde ìnáwó kòkan. Àwọn owó tí ó ń rí níbi eré rẹ̀ yìí nị́ ó fi ń ran ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́ tí ó sì ń san owó ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí ìjọ Onítẹ̀bọmi tí ó wà ní Abéòkúta . Abíọ́́lá jẹ́ Olóòtú ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilé-ìwé wọn tí ó ń jẹ́ The TrumpeterOlúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ sì jẹ́ igbákejì rẹ. Ó dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ National Council of Nigeria and the Cameroons ní ìgbà tí ó di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ètò òṣèlú àwa arawa lábẹ́ àsíá Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group.[6]

Ni odun 1960, Moshood gba sikolashipu ijọba lati ka iwe ni University ti Glasgow ni ilu Scotland ni bii ti o gba oye ni isiro sebe sebe o o je oye oniṣiro iwiregbe. Moshood di Ẹlẹgbẹ ti Institute of Chartered Accountants of Nigeria (ICAN) (ICAN).

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "REMEMBERING ABIOLA, 15 YEARS AFTER". National Mirror. July 6, 2013. Archived from the original on March 27, 2017. https://web.archive.org/web/20170327080631/http://nationalmirroronline.net/new/remembering-abiola-15-years-after/. Retrieved March 26, 2017. 
  2. "Moshood Kashimawo Olawale Abiola | Nigerian entrepreneur and politician". Encyclopedia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-25. 
  3. "‘MKO Was The Winner’ - Buhari Apologises To Abiola Family Over Annulment Of June 12 ’93 Election". Sahara Reporters. 2018-06-12. Retrieved 2018-06-13. 
  4. Aribisala, Femi (2018-06-12). "What June 12 reveals about Nigerian democracy". Vanguard News. Retrieved 2018-06-13. 
  5. Odumakin, Yinka (2018). "June 12 dissemblers". Vanguard News. 
  6. Inyang, Ifreke (2018-06-12). "MKO Abiola: What Falana told Buhari about results of June 12 elections". Daily Post Nigeria. Retrieved 2018-06-13.