Funlola Aofiyebi-Raimi

Òṣéré orí ìtàgé

Àdàkọ:DMCÀdàkọ:Merge partner

Funlola Aofiyebi-Raimi
Aofiyebi-Raimi ni odun 2010
Ọjọ́ìbíAbibat Oluwafunmilola Aofiyebi
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Orúkọ mírànFAR
Iṣẹ́Osere Itage
Gbajúmọ̀ fúnTinsel

Fúnlọ́lá Aòfiyèbí-Ràímì tí a àbísọ rẹ̀ jẹ́ Abibat Olúwafúnmilọ́lá Aòfiyèbí ṣùgbọ́n tí a mọ̀ pẹ̀lú ìnagijẹ gẹ́gẹ́ bi FAR, jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà. Ó ti ní ìfihàn rédíò fún ìgbà pípẹ́. Ó farahàn nínu fiimu The Figurine, Tinsel àti MTV Shuga.

Ìgbé ayé rẹ

àtúnṣe

Fúnlọ́lá ni ọmọ ìkẹhín àwọn ọmọ méje ti àwọn òbi rẹ̀. ìnagijẹ rẹ̀ wá lẹ́hìn tí ó ṣe ìgbeyàwó. ìnagijẹ náà sì ti di ìbuwọ́lù rẹ̀. FAR ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ lóri ìpele àti tẹlifíṣọ̀nù, pẹ̀lú àntí rẹ̀ Tẹ́ní Aòfiyèbí, ògbólògbó òṣèré kan.[1] Ó jẹ́ aya aṣiṣẹ́ ìkéde, Oláyínká Ràímì.

Iṣẹ́-ìṣe

àtúnṣe

FAR kẹ́ẹ̀kọ́ eré tẹlifíṣọ̀nù ṣíṣe ní Westminster College, àti ní Ilé-ìṣiṣẹ́ àwọn òṣèré ní Bunkinghamshire. Ó tún ní BSc nínu Soṣiọ́lọ́jì láti University of Lagos ni Nàìjíríà.[1] Àkọ́kọ́ ìṣàfihàn FAR nínu fiimu wáyé níbi fiimu Violated ti Amaka Igwe[2] pẹ̀lú àjọsepọ̀ Jókẹ́ Silva, Richard Mofẹ́ Damijo, Ego Boyo àti Kúnlé Bamtefa. Wọ́n yan fún ẹ̀bun THEMA kan fún ti òṣèré tí n bọ̀ tó dára jùlọ ní ọdún 1996. FAR kó ipa asíwájú nínu fiimu Keeping Faith, látọwọ́ olùdarí Steve Gukas. wọ́n tún ti yan FAR fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa àtìlẹyìn ti AMMA fún eré The Figurine ti olùdarí rẹ̀ jẹ́ Kúnlé Afọláyan[3] ṣááju kí ó tó hàn níbi eré tẹlifíṣọ̀nù Tinsel ti M-net tó sì kó ipa Brenda.[4] FAR ti ṣe ìfihàn nínu àwọn eré ḿiràn bi Doctors Quarters, Solitaire, àti Palace.[5] FAR ti ṣiṣẹ́ lóri ìpele nínu eré Sing That Old Song For Me àti The MansionRasheed Badamusi kọ, àti The Vagina Monologues.[6]

Ó ní ìfihàn rédíò tí a pè ní Touch of Spice fún ọdún mẹ́rìnlá (bẹ̀rẹ̀ ní Oṣù Kẹẹ̀jọ ọdún 1999).[1] FAR hàn nínu “MTV Shuga” ní ọdún 2019 àti 2020,[7] ipa àtìlẹyìn rẹ̀ ti “Mrs Olutu” sì wà nínu eré nígbàtí eré náà dínkù sí kékeré tí àkoọ́lé rẹ̀ jẹ́ MTV Shuga Alone Together láti ṣe àfihàn àwọn ìṣòro Coronavirus ní 20 Osù Kẹẹ̀rin Ọdún 2020. Túndé Aladese ló kọ eré náà tó s̀i n jẹ́ gbígbéjáde lọ́sẹ̀ẹ̀sẹ̀ - àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ pẹ̀lú United Nations.[8] Eré náà dá lóri Nigeria, South Africa, Kenya àti Côte d'Ivoire àti pé ìtán tẹ̀síwájú nípa lílo àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lóri ẹ̀rọ ayélujára. Gbogbo yíya àwòrán eré náà wá látọwọ́ àwọn òṣèré fúnralárawọn.[9] láwọn tí n ṣe Lerato Walaza, Mamarumo Marokane, Jemima Osunde, Folu Storms àti FAR.

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • The Figurine (2009)
  • Tinsel (2008–Present)
  • Grey Dawn (2015)
  • Entreat (2016)

Àwọn àmì ẹ̀yẹ

àtúnṣe

Wọ́n yáàn níbi Africa Movie Awards Academy (AMAA) fún òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa àtìlẹyìn (eré Figurine) Ọdún 2010

Wọ́n yáàn níbi Nigeria Entertainment Awards, New York (NEA) fún òṣèré tí ó dára jùlọ nínu eré tẹlifíṣọ̀nù (eré Tinsel) Ọdún 2010

Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Celebrity Takes 2 (Ìdíje ijó fún àwọn gbajúmọ̀ Nàìjíríà) Ọdún 2007 [10]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 Suleiman, Yemisi (30 August 2009). "I've always wanted to educate and entertain people - Funlola Aofiyebi-Raimi". Vanguard. Retrieved 29 September 2013. 
  2. Baba Aminu, Abdulkareem (5 January 2013). "Nigeria: Catching Up With Funlola Aofiyebi-Raimi". Daily Trust. Retrieved 29 September 2013. 
  3. "Funlola Aofiyebi Rami - nlist | Nollywood, Nigerian Movies & Casting". nlist.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-29. 
  4. weeklytrust.com.ng
  5. Iyanda, Olumide (12 April 2001). "Nigeria: Spice Girl". Retrieved 30 September 2013. 
  6. "Funlola Aofiyebi-Raimi, actor". Mandy Actors. Retrieved 29 September 2013. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  7. "Funlola Aofiyebi". IMDb. Retrieved 2020-08-03. 
  8. "Every Woman Every Child partners with the MTV Staying Alive Foundation to Tackle COVID-19". Every Woman Every Child (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-04-16. Archived from the original on 2021-10-09. Retrieved 2020-04-30. 
  9. Akabogu, Njideka (2020-04-16). "MTV Shuga and ViacomCBS Africa Respond to COVID-19 with "Alone Together" Online Series". BHM (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-04-30. 
  10. actors.mandy.com