Gbémi Ọlátẹ́rù Ọlágbẹ́gi

Gbemi Olateru Olagbegi je olugbohunsafefe Naijiria ni The Beat 99.9 FM[1] (o fise sile ni osu kejila 2021[2]), otaja ati olubagbesafefe “Off-Air with Gbemi & Toolz” adarọ ese[3]. Gbemi ni omoomo Olowo ti Owo tele Sir Olateru-Olagbegi II KBE. Ni 2008, Gbemi yege gege bii eniyan lori afẹfẹ ti ọdun naa ni Future Awards Africa[4]. Ni 2015, Gbemi da Gbemisoke shoes sile[5]. Laini bata ti a ṣẹda fun awọn obinrin ti o ni awọn iṣoro lati ra iwọn bata to tọ. Ni igbejade karun ti ọsẹ Arise Fashion Week, Eko ni ọdun 2018, Gbemi rin fun FIA Factory. Ni ọdun 2019, Gbemi di ọkan ninu awọn oju lati Megalectrics Ltd fun Remy Martin[6].

Gbemi Olateru Olagbegi
in 2019
Ọjọ́ìbíGbemi Olateru Olagbegi
18 Oṣù Keje 1984 (1984-07-18) (ọmọ ọdún 40)
Surulere, Lagos, Nigeria
Iléẹ̀kọ́ gígaPan-African University, Lagos (MSc, Media & Comm), Oakland University, Rochester (BA, Comm)
Iṣẹ́Media personality
Ìgbà iṣẹ́2005–present
Olólùfẹ́
Femisoro Ajayi (m. 2018)
Àwọn olùbátanBukunyi Olateru-Olagbegi

Igbesi aye ibẹrẹ

àtúnṣe

A bi Gbemi ni Oṣu Keje ọjọ kejidinlogun, ọdun 1984, fun Banke ati Yemi Olateru-Olagbegi ni Ile-iwosan St. Nicholas, Eko. Ó lọ sí ile-iwe Pampers Private, Surulere, The Ile-iwe girama Nigerian Navy, Ojo laarin 1993 si 1997 lẹhinna, o tẹsiwaju ẹkọ girama rẹ ni Queens College, Yaba nibiti o ti pari ni ọdun 2000. O gba B.A. ninu imo ibaraẹnisọrọ ni Oakland University, Rochester ati MSc. ninu imo oun igberohinjade ati ibaraẹnisọrọ lati Pan-Atlantic University, Eko .

Iṣẹ igbohunsafefe

àtúnṣe

Lẹhin ile-iwe, Gbemi ṣiṣẹ gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ ti awọn ọdọ ni Nigerian Television Authority, NTA 2 ikani karun, Victoria Island ṣaaju ki o to lọ si Cool FM, Naijiria ni 2005 nibi ti o ti gbalejo eto Good Morning Nigeria pẹlu Oloogbe Dan Foster fun ọdun kan. Ni 2006, Gbemi gbalejo Midday Oasis titi di 2009 nigbati o kuro ni Cool Fm losi The Beat 99.9 FM. Gbemi je igbakeji oludari eto ni Beat FM lati 2011 titi di 2016 ati Oludari Eto ni ile-iṣẹ-arabinrin, Naija FM 102.7 lati 2011 di 2017. O fi redio silẹ ni Oṣu kejila ọdun 2021.

Iṣẹ iṣowo

àtúnṣe

O je otaja tẹlentẹle. Ni ọdun 2015, Gbemi ṣe ipilẹ laini bata rẹ, Gbemisoke Shoes, erongba ti o jade lati inu iriri re nigbati o ba n ra bata[7].

Iṣẹ ori itage

àtúnṣe

Gbemi kopa ninu ere agbelewo fun igba akoko ni 2017, ninu ere telentele ayelujara ti a mo si Our Best Friend's Wedding[8]. O kopa gege bii Kemi ninu ere ololufe lati owo The Naked Convos in Collaboration with RedTv. Oreka Godis, Adebola Olowu, Chris Attoh ni awon onsere pataki ti o wa ninu ere naa ti won se fun saa meji. Ni 2020, o sere ninu ere agbelewo kukuru miran lati owo The Naked Convos ti akori re je Heaven Baby[9].

Lẹhin ti Gbemi Olateru-Olagbegi kuro ni redio ni ọjọ 24 ti Oṣu kejila, ọdun 2021. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ àti olùpilẹ̀ṣẹ̀ aláṣẹ ti ọ̀kan lára àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ eré ìnàjú ní Áfíríkà, TNC Africa. TNC Africa jẹ telifisan ti o ni idojukọ oni-nọmba ati ile-iṣẹ iṣelọpọ fiimu. Osu kini odun 2021 ni Olawale Adetula ati Daniel Aideyan se igbekale re[10].

Igbesi aye ara ẹni

àtúnṣe

Gbemi je ara idile oba Olagbegi ti Owo, Ipinle Ondo . Oni arakunrin meta, Olatokunbo Olateru-Olagbegi, Bukunyi Olateru-Olagbegi ati Adenola Olateru-Olagbegi, o si ti igbeyawo aladun pelu Femisoro Ajayi.

The Future Awards 2008 - "Eniyan ori afefe ti Odun". Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ Dynamix fún Olùgbékalẹ̀ Redio ti ọdún 2008. Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ “Green Awards for Excellence” fún ẹ̀ka redio lọ́dún kan náà. Ni ọdun 2009, o gba aami-eye “Iyaafin Alarinrin ti Odun” fun “Olufohunsi redio obinrin ti o dara julọ” ati ni ọdun 2010, won tun yan lẹẹkansi fun “The Future Awards”. O gba ami eye City People & The Nigerian Media Merit ni 2016 fun Olugbohun safefe ti odun.

Akoko Ise

àtúnṣe
  • 2005-2006: Good Morning Nigeria Show, Cool FM Nigeria Olubagbalejo
  • 2006-2009: Midday Oasis, Cool FM Nigeria Olugbalejo
  • 2009–di oni: Drive Time Show, The Beat 99.9 FM, Eko Olugbalejo
  • 2011-2017: Adari eto - Naija FM 102.7, Eko
  • 2011-2016: Igbakeji Adari Eto - <i>The Beat 99.9 FM</i> Eko

Ere Ori Itage

àtúnṣe
  • Our Best Friend's Wedding (2017)
  • Heaven Baby (2020)

Awọn ifọrọwanilẹnuwo pataki

àtúnṣe

Ami eye ati yiyan

àtúnṣe
Odun Ami Eye Ẹka Abajade Ref
2021 Net Honours Eniyan Midia Gbajumo julọ (obirin) won yan [15]

Awon Itokasi

àtúnṣe
  1. "Gbemi Olateru-Olagbegi - Social Media Week Lagos 2020". www.smwlagos.com. Social Media Week Lagos.
  2. "Gbemi Olateru-Olagbegi Goes Down Memory Lane as She Announces Her Last Day on Radio". www.bellanaija.com. Bella Naija.
  3. "Another Exciting Episode Of The "Offair Show" With Gbemi & Toolz is Here. Watch". www.bellanaija.com. Bella Naija.
  4. "The Future Awards 2008". www.bellanaija.com. Bella Naija.
  5. "Gbemi Olateru Olagbegi Launches Gbemisoke Shoe Line". www.thecable.ng. The Cable.
  6. "Remy Martin Partners Chris Ubosi On New Campaign". thenationonlineng.net. The Nation.
  7. "Gbemisoke Shoe An Idea Born From Her Own Personal Experience". www.briefessentials.com. The Brief.
  8. "Our Best Friend's Wedding" 10 things that happened on season 1 finale". www.pulse.ng. Pulse NG.
  9. "Oreka Godies, Ibrahim Suleiman give riveting performance in Heaven Baby". www.vanguardngr.com. Vanguard.
  10. "Gbemi Olateru-Olagbegi Joins TNC Africa as Co-Founder and Executive Producer". www.bellanaija.com. BellaNaija. Retrieved 2 March 2022.
  11. "Davido expecting baby number two with American-Based lover". www.premiumtimesng.com. Premium Times NG.
  12. "Davido talks "A Better Time" Album, #BBNaija & New Music "Fem" on The Beat 99.9Fm #DriveTimeShow". www.bellanaija.com. Bella Naija.
  13. "'I Can't Be Faithful To One Woman' Pop star admits". www.pulse.ng. Pulse NG.
  14. "Download and listen to Kim Kardashian's Interview with Beat FM Lagos". www.36ng.ng. 36ng.
  15. "Net Honours - The Class of 2021". Nigerian Entertainment Today. Retrieved 2021-09-07.