Hilda Baci
ẹ̀yà | abo |
---|---|
country of citizenship | Nàìjíríà |
orúkọ àfúnni | Hilda |
orúkọ ìdílé | Effiong Bassey |
ọjó ìbí | 20 Oṣù Òwéwe 1996 |
ìlú ìbí | Akwa Ibom State |
ìyá | Lynda |
languages spoken, written or signed | gẹ̀ẹ́sì |
kẹ́ẹ̀kọ́ ní | Madonna University |
residence | Èkó |
ethnic group | Àwọn ọmọ Áfríkà |
religion or worldview | Ẹlẹ́sìn Krístì |
eye color | dark brown |
hair color | Irun dúdú |
sexual orientation | heterosexuality |
Hilda Effiong Bassey tí ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Hilda Baci (a bi ní Ọjọ́ ogún oṣù Kẹ́sàn-án , ọdun 1996) jẹ́ aláṣè àti òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ-èdè Nàìjíríà.[1] Ní Osù Kẹ́jọ ọdún 2021, o jáwé olúborí nínú idije "Jollof Faceoff”.[2]
Ìpìlẹ̀ àti Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeHilda wá láti ìjọba ìbílẹ̀ Nsit Ubium, Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Nàìjíríà. Wọ́n bi ní ọjọ́ ogún oṣù Kẹsàn-án, ọdún 1996. Ó kàwé gboyẹ̀ pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ nínú ìmò sociology ní Yunifásítì Madonna, Okija.[3] Òun ni olóòtú ètò "Dine on A Budget" ní orí ìkànnì Pop Central TV, Dstv Channel 189.[4]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré
àtúnṣeÈyí ni àtòjọ awọn fíìmù tí o tí kópa
Ọdún | Fíìmù | Ipa rẹ̀ |
---|---|---|
2020 | Dreamchaser[5] | |
2021 | A Walk on Water[6] | Annie |
2023 | Mr & Mrs Robert[7] | Hilda |
Ìgbìyanjú rẹ̀ láti kọjá gbèdéke Guiness Record
àtúnṣeNí oṣù Kẹta 2023, Hilda fí léde pé òun yó gbìyànjú láti wákàtí tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìtàn ọmọ ènìyàn.[8] Ẹni tí ó dáná fún wákàtí[9] tí ó pọ̀ jùlọ tẹ́lẹ̀ ni Lata Tondon ó dáná fún wákàtí ẹ̀ta dín ní àádọ́rùn àti àrún dín ní àádọ́ta ìṣẹ́jú (87 hours 45 minutes) ní ọdún 2019.[10][11]
Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù karùn-ún ọdún 2023, ó bẹ̀rẹ̀ iná dídá náà, ó sì pe àpèlé rẹ̀ ní "Cook-a-thon".[12][13] Ó kọjá gbèdéke tí Lata Tondon gbé kalẹ̀ ní ọjọ́ kẹ̀ẹ́dógún oṣù karùn-ún ọdún 2023, ní dédé ago mẹ́jọ ku ìsẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún àárọ̀ ọjọ́ náà, Hilda fi ìsẹ́jú márùn-ún kọjá gbèdéke Lata.[14]
Hilta ni lọ́kàn láti dáná fún wákàtí mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún(96hrs).[15]
Àwọn òtòkùlú ènìyàn ní Nàìjíríà ni ó ti kàn sí Hilda láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iná dídá, àwọn bi: Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu; Olùṣọ́ àgùntàn àgbà ti ìjọ Harvester International, Bolaji Idowu; àti olórin Tiwa Savage.[16][17]
Ígbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tún pèé lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti gbá níyànjú nígbà tí ó ń dáná lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni ó ti ya wo ọgbà ilé tí ó ń ti dáná láti fi àtìlẹ́yìn wọn hàn, àwọn míràn sì ń kéde rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.[18].
Awọn Itọkasi
àtúnṣe- ↑ Suleiman, Yemisi (2023-03-25). "Hilda Baci: The Rising Star of Nigerian Cuisine". Vanguard Allure. Retrieved 2023-05-15.
- ↑ Anichukwueze, Donatus; Ogunbodede, Bukola (2023-05-14). "Nigerians Cheer As Hilda Baci Inches Closer To Guinness World Cooking Record". Channels Television. Retrieved 2023-05-15.
- ↑ Ibeh, Royal (2023-04-22). "Hilda Baci: Inspiring Women To Follow Their Dreams" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-13.
- ↑ Yaakugh, Kumashe (2023-05-14). "4-day non-stop cooking, 9 other things to know about Hilda Baci and cookathon". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-15.
- ↑ Writer, Staff (2020-02-19). "7 movies and series on Showmax nominated for AMVCAs". Showmax Stories (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-13.
- ↑ Rapheal (2023-04-08). "How I built huge restaurant brand from remote tiny apartment –Hilda Baci, multi-talented actress, TV producer, host, foodprenuer". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-13.
- ↑ "Mr & Mrs Robert (2023)". Radio Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-05-13. Retrieved 2023-05-13.
- ↑ "Firm Plans Longest Cooking Marathon to Break World Record – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-05-13.
- ↑ Sharma, Vikram (20 December 2021). "Chef Lata Tondon | Guinness World Record | First Woman Record Holder". The Global Indian. https://www.globalindian.com/story/art-culture/lata-tondon-the-first-woman-to-set-the-guinness-world-record-for-marathon-cooking/.
- ↑ "Rewa woman on way to cooking up a record". The Times of India. 2019-09-07. ISSN 0971-8257. https://timesofindia.indiatimes.com/city/bhopal/rewa-woman-on-way-to-cooking-up-a-record/articleshow/71019895.cms.
- ↑ "Longest cooking marathon (individual)". Guinness World Records (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-13.
- ↑ "Nigerian chef Hilda Baci goes after world record for longest cooking marathon". TheCable Lifestyle (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-04-20. Retrieved 2023-05-13.
- ↑ Ajayi, Adebola (2023-05-14). "Sanwo-Olu visits Hilda Baci as chef attempts world's longest cooking time record". Peoples Gazette (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-15.
- ↑ Taiwo, Efosa (15 May 2023). "Breaking: Nigerian chef, Hilda Baci breaks Guinness World Record for ‘longest cooking time’". Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2023/05/nigerian-chef-hilda-baci-breaks-guinness-world-record-for-longest-cooking-time/.
- ↑ Nsikak, Nseyen (15 May 2023). "Nigeria’s Hilda Baci breaks Guinness world record for longest cooking time". Dailypost. https://dailypost.ng/2023/05/15/nigerias-hilda-baci-breaks-guinness-world-record-for-longest-cooking-time/.
- ↑ Adelagun, Oluwakemi (2023-05-14). "PHOTOS: Sanwo-Olu visits as Hilda Baci attempts Guinness World Record for longest cook-a-thon". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-15.
- ↑ "tiwa savage visits hilda baci". Bing (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-15.
- ↑ Owolawi, Taiwo (2023-05-15). "Hilda Baci: Tinubu, Tiwa Savage, Burna Boy, others who showed chef support". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-15.