Iyán

Iyan je onje okele ti ama n fi isu gun pelu obe adidun ti ibile nje

Iyán jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá tó gbajúmọ̀ jùlọ. Iṣu funfun ló dára jù fún iyán gúngún. A lè fi iyán jẹ ọbẹ̀ ẹ̀fọ́, ẹ̀gúsí tàbí ilá. Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n tí máa ń jẹ iyán ṣùgbọ́n iyán jíjẹ wọ́pọ̀ jùlọ láàárín àwọn Ìjẹ̀ṣà, Òndó àti Èkìtì.[1][2] [3]

Iyán àti ọbẹ̀ ẹ̀fọ́

Tún Wò

àtúnṣe

Àwọn èròjà iyán gúngún

àtúnṣe

Iṣu ni ọba èròjà tí wọ́n máa ń fi gúnyán. Lẹ́yìn iṣu, a nílò odó, ó orí-odó àti omi.

Bí a ṣe lè gúnyán

àtúnṣe
 • A yóò bẹ iṣu
 • A yóò fọ iṣu náà tónítóní
 • À yóò dáná láti se iṣu
 • A yóò bu omi ní ìwọ̀nba tí ó lè se iṣu náà jiná sínú ìkòkò tàbí apẹ tí a fẹ́ fi se iṣu náà
 • A yóò kó iṣu tí a ti fọ̀ ní àfọ̀mọ́ sínú ìkòkò tí a gbé kaná
 • A yóò se iṣu náà títí yóò fi jiná dáradára.
 • Lẹ́yìn tí iṣu bá ti jiná, a yóò wà á sínú odó tí a ti fọ̀ kalẹ̀.
 • A yóò wá fi omorí odó fi gún un títí yóò fi lẹ̀ dáadáa.
 • A yóò wá kọ ọ́ sínú abọ́ tàbí àwo tó mọ́ tónítóní fún jíjẹ.[4]

Àwọn ọbẹ̀ tí a fi lè jẹ iyán

àtúnṣe

Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, "Iyán loúnjẹ, ọ̀kà logùn, àìrí rárá là ń jẹ̀kọ" Yorùbá gbádùn iyán púpọ̀, oríṣiríṣi ọbẹ̀ ni wọ́n fi ń jẹ iyán. Àwọn ni;

 • Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́
 • Ọbẹ̀ ègúsí
 • Ọbẹ̀ àpọ̀n
 • Ọbẹ̀ ata díndín
 • Ọbẹ̀ ilá abbl.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
 1. "Pounded Yam (Fufu) Recipe - Side Dish Recipes - PBS Food". PBS Food. 2011-09-12. Retrieved 2019-12-13. 
 2. "Pounded Yam". All Nigerian Recipes. 2019-03-25. Retrieved 2019-12-13. 
 3. "Iyan - Pounded Yam". My Guide Nigeria. 2014-02-12. Retrieved 2019-12-13. 
 4. "Pounded Yam". How To Pound Yam in Nigeria. Retrieved 2019-12-13.