Jénífà jẹ́ fíìmù apanilẹ́rìn-ín ti ọdún 2008 láti ọwọ́ Funke Akindele. Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́rin ní ọdún 2009 láti ọwọ́ Africa Movie Academy Awards, bí i òṣèrébìnrin tó dára jù lọ, Best Original Soundtrack àti fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà tó dára jù lọ. Akindele gba àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tó dára jù lọ ní ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù yìí.[1][2][3][4]

Jénífà
Fáìlì:Movie poster for Jenifa.jpg
AdaríMuhydeen S. Ayinde
Olùgbékalẹ̀Olatunji Balogun
Àwọn òṣèréFunke Akindele
Iyabo Ojo
Ronke Odusanya
Eniola Badmus
Mosunmola Filani
Ireti Osayemi
Tope Adebayo
OrinFatai Izebe
Ìyàwòrán sinimáMoroof Fadairo
OlóòtúAbiodun Adeoye
Ilé-iṣẹ́ fíìmùScene One Productions
OlùpínOlasco Films Nig. Ltd.
Déètì àgbéjáde
  • 2008 (2008)
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèYoruba

Fíìmù yìí jẹ́ àgbéjáde àkọ́kọ́ tó wá padà gbajúmọ̀ ní Nàìjíríà. Apá kejì rẹ̀ jáde ní ọdún 2011, wọ́n sì tún ṣe àgbéjáde eré kúkurú irú rẹ̀ ní ọdún 2014.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe