Kainji National Park jẹ́ pápá ìṣeré ní Ìpínlẹ̀ Niger àti Kwara, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n da kalẹ̀ ní ọdún 1978, ó gba ilẹ̀ tí ó tó 5,341 km2 (2,062 sq mi). Ó pín sí apá mẹ́ta: apá ti Adágún Kainji níbi tí wọn ò ti gba iṣẹ́ apẹja láyè, igbó Borgu tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn adágún náà, àti Igbó Zugurma.[1]

Nítorí àìsí àbò tó péye ni àgbègbè náà, àwọn àjọ pápá ìṣeré ní Nàìjíríà dáwọ isẹ́ àti ìwádìí dúró ní pápá ìṣeré Kainji National Park ní ọdún 2021; wọ́n tún dáwọ isẹ́ dúró ní Chad Basin National Park àti ní Kamuku National Park.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named UNEP
  2. Adanikin, Olugbenga. "Kainji National Park, two others suspend operations over insecurity". International Centre for Investigative Reporting. Retrieved 27 October 2021.