Làmídì Adédibú

Olóṣèlú

Olóyè Làmídì Aríyíbí Àkànjí Adédibú ni a bí ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kẹwàá, ọdún1927 (24-10-1927 sí 11-6-2008) jẹ́ alẹ́nulọ́ agbara alẹ́nulọ́rọ̀, apàṣẹ-wàá ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “bàbá" fún ẹgbẹ́ òṣèlú "PDP". [1][2]

Ìbí àti ẹbí rẹ̀ àtúnṣe

A bí Olóyè Adédibú ní agbègbè Ọjà Ọba ní ìlú Ìbàdàn. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ oyè láti ìdílé Ọba Olúpòyí.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olóṣèlú àtúnṣe

Adédibú dara pọ̀ mọ́ ìṣèlú ní ọdún 1950, nígbà tí ó di ọmọ ẹgbẹ́ Peole's Party, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlti Action Group lábẹ́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ . Lẹ́yìn náà, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú National Party of Nigeria (NPN) , ẹgbẹ́ tí ọ̀gbẹ́ni Àdìsá Akinloyè àti Richard Akínjíde . Ó di onípò pàtàkì nínú òṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà ní àkókò ìjọba ológun Ọ̀Ọ̀gágun Ibrahim Babangida, lákòókò yí ni ẹgbẹ́ òṣèlú NPN lo ànfàní ètò ìdìbò ojúmitó (Open ballot) láti ṣe màdàrú. Ọ̀nà tí a lè gba ṣàpèjúwe ìlànà òṣèlú tirẹ̀ ni lílo àwọn ọmọ gànfé , àti fífi ipá mú ọmọ ayo rẹ̀ tàbí alátakò rẹ̀ ṣe oun tí ó bá fẹ́ tí ó sì ma ń mú jàgídí-jàgan lọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà.

A gbọ́ wípé kò fẹ́rẹ̀ sí olóṣèlú kan tí ó goróyè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí kò gbàṣẹ gbòntẹ̀ Adédibú kí ó tó dépò àṣẹ. Èyí ló fàá tí wọ́n fi ń pèé ní Òpómúléró òṣèlú ilẹ̀ Ìbàdàn . Wọ́n yan ọmọ rẹ̀ kan , Kamorudeen Adékúnlé Adédibú , gẹ́gẹ́ bí Aṣojú -ṣòfin sílé Aṣòfin àgbà fún ẹkùn Ọ̀yọ́ South ní oṣùKẹ́rin ọdún 2007 . Senator Teslim fọlárìn , í wọ́n dìbò yàn sílé Aṣòfin àgbà gẹ́gẹ́ bí Senator fún ẹkùn Àrin-gbùngbùn Ọ̀yọ́ (Oyo Central) ni ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ lẹ́yìn Adédibú .Ẹ̀wẹ̀, Olóyè Rasheed Ládọjà tí ó jẹ Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní oṣù Karùún ọdún 2003, náà tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ lẹ́yìn rẹ̀. Àmọ́ òun àti Adédibú padà di oje ọrọ́ àti ojú tí wọn kìí fẹ́ rí ara wọn lórí tani yòó yàn sí.àwọn ipò Kọmíṣọ́nà ní ọdún 2004.

Ikú rẹ̀ àtúnṣe

Adédibú kú ní ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kẹfà, ọdún 2008 sí ilé ìwòsàn University College tí ó wà ní ìlú Ìbàdàn , nígbà tí ó wà ní ipò Ẹ̀karún ti ilẹ̀ Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí ipò tí ẹbí rẹ̀ wà sí ti Olúbàdàn ti Ilẹ̀ Ìbàdàn.[3]

Awọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Fabowale, Yinka (2018-06-02). "‘My love life with Lamidi Adedibu’". The Guardian Nigeria News. Retrieved 2019-10-26. 
  2. Omobowale, Ayokunle Olumuyiwa; Olutayo, Akinpelu Olanrewaju (2007-07-16). [/core/journals/journal-of-modern-african-studies/article/chief-lamidi-adedibu-and-patronage-politics-in-nigeria/67421109C8158C573FA0CB7C9374B16A "Chief Lamidi Adedibu and patronage politics in Nigeria - The Journal of Modern African Studies"]. The Journal of Modern African Studies 45 (3): 425–446. doi:10.1017/S0022278X07002698. ISSN 1469-7777. /core/journals/journal-of-modern-african-studies/article/chief-lamidi-adedibu-and-patronage-politics-in-nigeria/67421109C8158C573FA0CB7C9374B16A. Retrieved 2019-10-26. 
  3. "Inside Lamidi Adedibu’s deserted Ibadan ‘palace’, crumbling political dynasty". Premium Times Nigeria. 2018-02-10. Retrieved 2019-10-26.