New Money Owó Tuntun (2018 film)
New Money (Owó Tuntun) jẹ́ eré ìtàgé apanilẹrìín tí a gbé jáde ní ọdún 2018 ni orile-ede Nàìjíríà Tọpẹ Ọṣhin ni Oludari ere náà nígbàtí ilé isẹ́ Inkblot Productions àti FilmOne gbé e jade[1] Fíìmù na só ìtàn ọmọbìnrin kan ti o n ba ni ta'jà ti o ni èròngbà láti di aránṣọ ti o wá ṣàdédé rí ìpín tirẹ̀ gbà nínú ogún bàbá rẹ̀ ti o ti fi ìgbàkan kúrò ní'lé. Àwon òṣèré tí ó kó'pa nínú fíìmù naa ni Jemima Osunde, Kate Henshaw, Dakore Akande, Wale Ojo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, pẹ̀lú Falz d Bahd Guy tí ó dẹrin pani jọjọ nínú fíìmù naa.[2] Ni ọjọ́ kẹtà-lé-lógún òṣu kẹta ọdún 2018 ni a gbe fíìmù naa jade ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Inkblot ati FilmOne tún pa'wọ́ pọ ṣe fíìmù lẹẹkan si lẹ́yin tí wọ́n ṣe fíìmù The Wedding Party 2.[4]
New Money | |
---|---|
Adarí | Tope Oshin Ogun |
Olùgbékalẹ̀ | Kene Okwuosa Zulumoke Onuekwusi Chinaza 'Naz' Onuzo Isioma Osaje |
Òǹkọ̀wé | Chinaza 'Naz' Onuzo |
Àwọn òṣèré | Jemima Osunde Kate Henshaw Dakore Akande Wale Ojo |
Ìyàwòrán sinimá | Idowu Adedapo Pindem Lot |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Inkblot Productions FilmOne |
Déètì àgbéjáde | 23 March 2018 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
Àgbékalẹ̀ eré
àtúnṣeNew Money (Owó Tuntun) sọ ìtàn ọmọ ọdún mẹtà-lé-lógún kan ti a ń pè ọrukọ rẹ̀ ní Toun (Jemima Osunde), ti o ṣ'àdédé ba ara rẹ ni ààrin gbùngbùn ọrọ̀ nigbati baba rẹ (Kalu Ikeagwu) fi ilé iṣẹ́ rẹ ti o níye lori to ọ̀pọ̀lọpọ̀ bilionu sílẹ̀ fún un nínú ìwé ìpìngún rẹ̀. Èròngbà tirẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ ni láti di ránṣọ-ránṣọ. Ó gbọ́ ìtàn lẹ́nu ìyá rẹ̀, Fatima (Kate Henshaw) wípé ìgbéyàwó alárédè ni òun ṣe pẹ̀lú bàbá rẹ̀, Ifeanyi (Kalu Ikeagwu); ṣùgbọ́n, nítorí ìlòdì sí àwọn ẹbí Ifeanyi, wọ́n tú ìgbéyàwó naa ka. Ifeanyi wá tún ìgbéyàwó miran ṣe pẹ̀lú Ebube (Dakore Akande), eleyi ti ko sì sí ọmọ kankan laarin wọn. Toun kọ eti'kun sí ìyá rẹ̀, o si bẹrẹ si ni gbé igbe aye afẹ́ ti arakunrin baba rẹ̀, Chuka (Wale Ojo) ati ọmọ rẹ̀, Patrick (Adeolu Adefarasin) gbiyanju lati bajẹ mọ lọ́wọ́. Ìpinnu rẹ̀ yii so ile iṣẹ na sinu ọpọlọpọ ìṣòro, eleyi ti o si mu ki àwọn eniyan ri Toun gẹ́gẹ́ bi oludari ti ko kún ojú òsùwọ̀n.[5]
Àwọn Òsèré tí o kó'pa níbẹ̀
àtúnṣe- Jemima Osunde gẹ́gẹ́ bi Toun Odumosu
- Kate Henshaw gẹ́gẹ́ bi Fatima
- Dakore Akande gẹ́gẹ́ bi Ebube
- Wale Ojo gẹ́gẹ́ bi Chuka
- Wofai Fada gẹ́gẹ́ bi Binta
- Adeolu Adefarasin gẹ́gẹ́ bi Patrick
- Daniel Etim Effiong gẹ́gẹ́ bi Ganiyu Osamede
- Osas Ighodaro gẹ́gẹ́ bi Angela
- Blossom Chukwujekwu gẹ́gẹ́ bi Joseph
- Falz gẹ́gẹ́ bi Quam
- Kalu Ikeagwu gẹ́gẹ́ bi Ifeanyi
- Femi Branch
- Bikiya Graham-Douglas
- Rita Edwards gẹ́gẹ́ bi Móníjà
- Yolanda Okereke
Àgbéjáde ní Tíátà
àtúnṣeA gbé fiimu yi jáde fún ìgbà àkọ́kọ́ ni ile Sinima Imax tí ó wà ní àdúgbò Lẹ́kí, ní ìlú Èkó Lagos lati ọwọ́ awon ilé iṣẹ́ méjì tí ó ńgbé eré jade, Inkblot Productions àti FilmOne Distribution ni ọjọ́ kẹtà-lé-lógún oṣù kẹ́ta ọdún 2018.[6][7]
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ .
- ↑ .
- ↑ .
- ↑ .
- ↑ Izuzu, Chidumga (2018-03-18). "The women of upcoming Nollywood movie, "New Money"". Pulse.ng. Archived from the original on 2018-07-01. Retrieved 2018-11-24.
- ↑ .
- ↑ .