Nọ́mbà tóṣòro
Ninu mathematiki, nọ́mbà aṣòro (complex number) ni awon nomba ti won ri bayi
to je pe a ati b won je Nọ́mbà Gidi, ti i si je ẹyọ tíkòsí pelu idamo bi i 2 = −1. Nọ́mbà gidi a ni a n pè ní apá gidi nọ́mbà tósòro, be sìni nọ́mbà gidi b jẹ́ apá tíkòsi´. A lè sọ pé àwón nọ́mbà gidi je nọ́mbà tósòro pelu apá tíkòsi´ tó jé òdo; eyun pé nọ́mbà gidi a jẹ́ bakanna mọ́ nọ́mbà tósòro a+0i
Fún àpẹrẹ, 3 + 2i jé nọ́mbà tósòro, pẹ̀lú apá gidi to jẹ 3 ati apá tíkòsi´ to jẹ 2. Tí z = a + bi, apá gidi (a) ni a n se àmì rẹ̀ pẹ̀lú Re(z), tàbí ℜ(z), be sìni apá tíkòsi´ (b) ni a n se àmì rẹ̀ pẹ̀lú Im(z), tàbí ℑ(z)
Àwon nọ́mbà tósòro se ròpọ̀, yọkúrò, sọdipúpọ̀ tàbi sèpínpiń gẹ́gẹ́ bi a ti n se fun àwon nọ́mbà gidi, be ni wón sì ní ìdámọ̀ tó lẹ́wà mìíràn. Fún àpẹrẹ, nọ́mbà gidi nìkan kò ní ojúùtú fún ìdọ́gba aljebra alápọ̀ọ́nlépúpọ̀ (polynomial) pẹ̀lú nọ́mbà àfise gidi (coefficient), sùgbọ̀n àwọn nọ́mbà tósòro ní. (Eyi ni òpó àgbàrò aljebra) (fundamental theorem of algebra).
Nínú ìmọ̀ isẹ́-ẹ̀rọ oníná (electrical engineering), níbi ti i ti dúró fún ìwọ́ iná (electric current) àmì tí a n lò fún ẹyọ tíkòsí i ni j, ari bayi pé nigba miran nọ́mbà tósòro se kọ lẹ̀ bayi, a + jb.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |