Oṣù Ṣẹ̀rẹ́

(Àtúnjúwe láti Oṣù Kínní)

Àdàkọ:Kàlẹ́ndà31Ọjọ́Bẹ̀rẹ̀NíỌjọ́ Ajé

kalẹnda ti oṣu kini
Osù:| Kínní | Kejì | Kẹta | Kẹrin | Kàrún | Kẹfà | Keje | Kẹjọ | Kẹ̀sán | Kẹ̀wá | Kọkànlá | Kejìlá


Oṣù Ṣẹ̀rẹ́ tàbí oṣù Kìíní jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ nínú Kàlẹ́ńdà Gregory. Ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ó wà nínú oṣù yìí. Ọjọ́ kìíní ti oṣù Ṣẹ̀rẹ́ ni a ṣe ayẹyẹ ọdún títun. Ní ìpíndọ́gba, oṣù yìí sì jẹ́ oṣù tí ó máa ń tutú jù lọ ní ìdajì ayé àríwá (nítorí pé ó jẹ́ oṣù kejì ti ìgbà òtútù níbẹ̀); ó sì jẹ́ oṣù tí ooru máa ń mú jù lọ ní ìdajì ayé gúúsù (nítorí pé ó jẹ́ oṣù kejì ti ìgbà sọ́mà níbẹ̀). Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n pè é ní "January"; orúkọ yìí wá láti ọ̀rọ̀ èdè Látínì "iānuārius" (oṣù ti Janus). Nítorí èyí, ní èdè Yorùbá náà a sì máa ń pe oṣù yìí ní "oṣù Jánúárì" ní ìgbà mìíràn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń wí pé kò yẹ́ kí a lò ó nítorí jíjẹ́ ọ̀rọ̀-àyálò tí ó jẹ́.