Olikoye Ransome-Kuti
A bí Olíkóyè Ransome-Kútì sí Ìjẹ̀bú-Òde ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1927, ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà.[1]
Olikoye Ransome-Kuti | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oṣù Kejìlá 30, 1927 |
Aláìsí | June 1, 2003 | (ọmọ ọdún 75)
Ẹ̀kọ́ | Ransome-Kuti attended Abeokuta Grammar School, University of Ibadan and Trinity College Dublin (1948–54). |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan. |
Iṣẹ́ | paediatrician, activist and health minister of Nigeria. |
Àwọn ọmọ | 3 |
Awards | Leon Bernard Foundation Prize Maurice Pate Award |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Olikoye Ransome-Kuti ní Ijebu Ode ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1927, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà. Ìyá rẹ̀, Olóyè Funmilayo Ransome-Kuti, jẹ́ gbajúgbajà olùpolongo òṣèlú àti ajàfitafita fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin. Bàbá rẹ̀, Rẹ́fẹ̀nì Israel Olúdọ̀tun Ransome-Kútì, mínísítà Protestant àti ọ̀gá ilé-ìwé, ni Ààrẹ àkọ́kó ti Nigeria Union of Teachers.[2] Arákùnrin rẹ̀ Fẹlá jẹ́ olórin olókìkí àti olùdásílè Afrobeat, nígbà tí arákùnrin rẹ̀ mìíran, Beko, jẹ́ dókítà tí ó mọ̀ye lágbàáyé àti ajàfitafita olósèlú. Olíkóyè Ransome-Kuti lọ sí ilé-ìwé Girama Abéòkúta, Yunifásitì ti ìlú Ìbàdàn àti Trinity College Dublin (1948-54).[3]
Iṣẹ́-ṣíṣe rẹ̀
àtúnṣeOlíkóyè Ransome-Kútì jẹ́ oníwòsàn ilé ní Ilé-ìwòsàn Gbogbogbò, Èkó. Ó jẹ́ olùkọ́ni àgbà ni Yunifásitì ìlú Èkó láti ọdún 1967 sí 1970; ó sì di olórí Ẹka ti Àwọn ìtọ́jú ọmọdé láti 1968 sí 1976. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìtọ́jú ọmọdé ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì ti Ìṣègùn, Yunifásítì ti Èkó títí di ìgbà tí ó fẹ̀yìntì ní ọdún 1988. [4] [5] Ó ṣiṣẹ́ bí i òṣìṣẹ́ ilé àgbà ní Ilé-ìwòsàn Great Ormond Street, Lọ́ńdọ̀nù, àti bí i dókítà adele ní Ilé-ìwòsàn Hammersmith ní àwọn ọdún 1960.[6]
Ní àwọn ọdún 1980, ó darapọ̀ mọ́ ìṣèjọba Ọ̀gágun Ibrahim Bàbáńgídá gẹ́gẹ́ bí i mínísítà fún ètò ìlera. Ní ọdún 1983, pẹ̀lú àwọn ọmọ orílèdè Nàìjíríà méjì mìíràn, ṣe ìdásílẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn àjọ aláìwojúèrè-aládàání tó ń rí sí ìlera, èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Society for Family Health Nigeria, léyìí tó ń rí sí ìfètò-sọ́mọ-bíbí àti ètò ìlera àwọn ọmọ. Ó jẹ́ mínísítà di ọdún 1992, nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ World Health Organization gẹ́gẹ́ bí i amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí pátápátá. [7] Ó di ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò ìkọ́ni mú, pẹ̀lú olùkọ́-àbẹ̀wò-sí ní ilé-ẹ̀kọ́ onímọ̀ọ́tótó àti ìlera gbogbogbò Baltimore's Johns Hopkins University. Ó kọ̀wé lọ́pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ìwe-ìròyìn ìṣoògùn àti àwọn àtẹ̀jáde.[8] Ó jẹ ẹ̀bùn Leon Bernard Prize Foundation ní ni 1986 [9] àti àmì ẹ̀yẹ Maurice Pate ní 1990.
Ikú
àtúnṣeOlíkóyè Ransome-Kuti kú ní ọjọ́ kìíní Oṣù Kẹfà ọdún 2003, tí ó sì fi ìyàwó rẹ̀ Sonia ẹni àádọ́ta ọdún àti àwọn ọmọ mẹ́ta sẹ́yìn. [10]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Adenekan, Shola (1 June 2003). "Olikoye Ransome-Kuti". The Guardian (United Kingdom). https://www.theguardian.com/news/2003/jun/10/guardianobituaries.aids. Retrieved 1 March 2015.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Olukoye Ransome-Kuti.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ F. Adewole, Isaac (21 June 2023). "African Journal of Reproductive Health". Mason Publishing, Part of the George Mason University Libraries. 27 (5). https://www.ajrh.info/index.php/ajrh/article/view/3823.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)