Orúkọ Yorùbá

(Àtúnjúwe láti Oruko Yoruba)

Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn Yorùbá ń lò jákè-jádò gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Yorùbá bí Ìbíní, Tógò àti Nàìjíríà. Nípaṣe ìṣe àwọn baba ńlá baba àwọ́n Yorùbá, wọ́n ń fún ọmọ wọn lórúkọ níbi ayẹyẹ tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ lẹ́yìn ìbímọ. Àwọn orúkọ àwọn ọmọ jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ifá dídá tí ọ̀pọ̀ Babaláwo bá dá, ṣùgbọ́n ní ayé òde-òní, orúkọ ọmọ tún lè wá láti ọ̀dọ àwọn tí ó bá ní ipò tóga nínú ẹbí pẹ̀lú bàbá, ìyá, òbí àwọn òbí méjéèjì tàbí ẹni tí ó súnmọ́ wọn gbágbá. Ìyá àti bàbá, àti alásùn-ún-mọ́ wọn lè fún ọmọ tàbí àwọn ọmọ ní orúkọ tóbá wù wọ́n. Orúkọ ọmọ sábà máa ń wá láti ọ̀dọ àwọn òbí méjéèjì ìyá àti bàbá ọmọ àti àwọn obí tó bí òbí méjéèjì yí wọ́n bí ọmọ tí wọ́n fẹ́ sọ lórúkọ. Orúkọ ìbílẹ̀ tí a dífá fún láti ọ̀dọ Babaláwo ń ṣe àfihàn òrìṣà tó ń ṣe atọ́nà ọmọ náà wá sáyé, yálà ọmọ náà jẹ́ àtúnbí oònilẹ̀ àti pé kádàrá ọmọ àti nípa ti ẹ̀mí tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí, tí ó máa ran ọmọ lọ́wọ́ láti lè jẹ́ kí ó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ayẹyẹ ìkọ̀kọ̀ àkọ́kọ́ kan tún wà fún ìyá àti bàbá ọmọ nìkan níbi tí orúkọ àti èèwọ̀ yóò ti máa jẹ́ fífún ọmọ àti òbí rẹ̀, àti àbá lórí ohun tí ọmọ náà máa nílò láti fi ṣe àṣeyọrí. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìnáwó àwùjọ tí àsè àti àríyá ti wáyé tí ẹbí àti ojúlùmọ̀ sì ti jẹ́ ìpè àwọn obí ọmọ láti wá báwọn ṣàjọyọ̀ ìbí ọmọ náà.

Àròkọ àti ìwúlò orúkọ

àtúnṣe

Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun tí ènìyàn máa ń sáábà kíyèsí láàrin ọ̀sẹ̀ sáájú ayẹyẹ ìṣọmọ-lórúkọ gẹ́gẹ́ bí i àbójútó ńlá tí ó wà lórí gbígbé e lórí i yíyan orúkọ kan tí kò ní ìrísí lórí èyíkéyìí ìwà tó lòdì tàbí ìwà búburú láàrín àwùjọ̀,ní ọìgbà mííràn yíyan orúkọ tí ó ti ọ̀daràn kan tẹ́lẹ̀ fún ọmọ Yorùbá kan kìí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí èrò ọlọ́gbọ́n (gẹ́gẹ́ bí i ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èrò Yorùbá) lè mú kí ọmọ náà ó di olè tàbí ọ̀daràn lọ́jọ́ iwájú.

Ìpín sí ìsọ̀rí orúkọ Yorùbá

àtúnṣe

Orúkọ àyànmọ́

àtúnṣe

Èyí ni a tún mọ̀ sí orúko àmútọ̀runwá, (orúkọ tí a gbà wí pé àti ọ̀run ni a ti gbé e wá tàbí tí a tí jẹ bọ̀ láti) àpẹẹrẹ ni Àìná, Ìgè, Òjó, Yéwándé, Abọ́ṣẹ̀dé, Taiwo, Kẹ́hìndé, Ìdòwú, Àlàbá, Babatúndé, Jọ́ọ̀ọ́dá, Ájàyí, Abíọ́nà, Dàda, ìdògbé, Yéwándé.

Orúkọ àbísọ

àtúnṣe

Èyí ni (orúkọ tí a fún ọmọ ní ọjọ́ tí ań ṣàjọyọ̀ ìbí rẹ̀, yálà látẹnu àwọn òbí rẹ̀ ni tàbí àwọn alásùn-ún-mọ́ fún un) ni a tún ń pè ní orúkọ àbisọ. Èyí sábà máa ń jẹ mọ́ ipò tí ẹbí tábí àwọn òbí ọmọ náà wà ní àwùjọ. ìwọ̀nyí ni: Ọmọtáyọ̀, Ìbílọlá, Adéyínká, Ọláwùmí, Ọládọ̀tun, ìbídàpọ̀, Ọládàpọ̀, ọlárìndé, Adérónkẹ́, Ajíbọ́lá, Ìbíyẹmí, Morẹ́nikẹ́, Mojísọ́lá, Fọláwiyọ́, Ayọ̀délé, Àríyọ̀, Oyèlẹ́yẹ, Ọmọ́táyọ̀, Fadérera.

Orúkọ oríkì

àtúnṣe

Àwọn orúkọ yìí ni: Àyìnlá, Àjíkẹ́, Àlàó, Àdìó, Àkànmí, Àmọ̀ó, Àríkẹ́, Àgbékẹ́, Àjìún, Àlàkẹ̀, Àwẹ̀ró, Àbẹ̀bí, Àrẹ̀mú, Àlàní, Àyìnké.

Orúkọ àbíkú

àtúnṣe

Èyí ń ṣàfihàn ìmọ̀sílára àwọn Yorùbá àti ìgbàgbọ́ wọn nípa ẹ̀mí àìrì, ikú àti àkúdàáyà. Àpẹẹrẹ orúkọ àbíkú ni: Málọmọ́, Kòsọ́kọ́, Dúrósinmí, Ikúkọ̀yí, Bíòbákú, Kòkúmọ́, Ikúdàísí, Ìgbẹ́kọ̀yí, Àńdùú, Kásìmáawòó, Ọmọ́túndé, Dúrójayé, Kalẹ̀jayé.

Orúkọ ìnagijẹ

àtúnṣe

Orúkọ ìnagijẹ ni orúkó tí wọ́n ma ń fúnni látàrí ìhùwà sí, ìrísí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ ni Eyínfúnjowó, Eyínafẹ́, Ajíláran, Ajíṣafẹ́, Ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, Arikúyẹrí, Agbọ́tikúyọ̀, Awẹ́lẹ́wà, ìbàdíàrán àti bẹ̀ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Méjì nínú orúkọ àmútọ̀runwá Yorùbá tó gbajúmọ̀ jù ni Táíwò (tàbí Táyé) àti Kẹ́hìndé tí wọ́n fún àwọn ìbejì ní pàtàkì. Ó jẹ́ ìgbàgbọ́ pé àkọ́kọ́ nínú ìbejì ni Táíwò (tàbí Táyé) tí ó gbèrò láti kọ́kọ́ jáde wá sáyé láti finmú fínlẹ̀ bóyá agbègbè ibi tí wọ́n fẹ́ wọ̀ dára tàbí kò dára láti wà sínú ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn á tẹ́wọ́ gba ìkejí rẹ̀ Kẹ́hìndé (nígbà mííràn á dá kẹ́hìndé padà) kó ní kó má a bọ̀. Òmíràn pẹ̀lú ẹ̀sìn àbáláyé: àpẹẹrẹ ni Ifáṣọlá-Ifá ṣe àṣeyọrí. Ó ṣeéṣe fífún ọmọ tí wọ́n máa kọ́ gẹ́gẹ́ bí i babaláwo àti iṣẹ́ ifá máa jẹ́ kí ó dọlọ́rọ̀ àti aláṣeyọrí. Àwọn obí onígbàgbọ́ ìgbàlódé fún ìṣe kí wọ́n máa lo orúkọ àbáláyé fún pípáàrọ̀ orúkọ òrìsà fún OLÚ tàbí OLÚWA, ìtumọ̀ olúwa tàbí olúwa mi tí ó ń tọ́ka sí èròǹgbà onígbàgbọ́ nípa ỌLỌ́RUN àti Jésù kírísítì. Fún àpẹẹrẹ Olúwatiṣé-olúwa ti ṣé,àwọn òbí gbàdúrà fún ọmọ olúwa náà sì fún wọn níkan.

Àwọn òbí Mùsùlùmí máa ń fẹ́ fẹ́ fún ọmọ wọn ní orúkọ Lárúbáwá nígbà mííràn pẹ̀lú pípè Yorùbá, Ràfíáh di Ràfíátù. Orúkọ ipaṣẹ̀ tún lè ṣàkàwé ipò tí ìdílé náà wà láwùjọ (àpẹẹrẹ "Adéwálé" orúkọ ìdílé ọba àtàtà) Ó tún lè ṣàkàwé iṣẹ́ abínibí ìdílé kan (àpẹẹrẹ "àgbẹ̀dẹ", àwọn Alágbẹ̀dẹ). Yorùbá tún ní oríkì irú èyí tí àwọn akọ́ríkì máa ń lò láti tẹpẹlẹ mọ́ àṣeyọrí aṣáájú ti oríṣìíríṣìí ìdílé. Oríkì tún lè jẹ́ ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ bì i "Àdúnní"tàbí kí ó jẹ́ ẹṣẹ̀ ìwé tàbí jáǹtìrẹrẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kì í ṣe ipa àtàtà ni ó ń kó nínú orúkọ gidi, oríkì máa ń sábà jẹ́ lílò ní ẹ̀gbẹ́ kan, ó máa ń sábà jẹ́ ohun tí gbogbogbò mọ̀ mọ̀ọ̀yàn ní àkókò kan. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ni àwọn ará ìlú mìíràn lè dámọ̀ kódà ìdílé wọn nípa lílo oríkì okùn ìrandíran won.

Iṣẹ́ kékeré ni yíyan orúkọ nísìn yìí, nítorí kò sí àkójọpọ̀ orúkọ Yorùbá tó pé. Síbẹ̀síbẹ̀ iṣẹ́ àgbéṣe titun látọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣe gbogbo orúkọ Yorùbá sí kíkọ sílẹ̀ sínú ìwé arídìí ní ti ìlànà onírúurú ọ̀nà ìgbàròyìn.

Oruko Yoruba naa ni iwe yii da le. O soro nipa jije oruko, eto ikomojade, oruko amutorunwa, oruko abiso ati oruko mti won n fun abiku, iyato laarin oruko ati alaje ki o to wa fi orile pari re. Ibeere wa ni opin iwe fun idanrawo. Awon itumo awon oro ti ta koko naa si wa pelu.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  • C.L. Adeoye (1982), Oruko Yoruba. Ibadan, Nigeria: University Press ltd. Oju-iwe = 129'