Robert Peters Tí wọ́n tún máa ń pè ní Roberts O. Peters jẹ́ òṣèré fíìmù àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Naijiria, aṣagbátẹrù eré, olùyàwòrán, àti alóhunlóyìn òṣèré. Ó di gbajúmọ̀ nígbà tí ó ṣagbátẹrù fíìmù kan ní ọdún 2014 tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Breakout[1]30 Days in Atlanta,[2] Shades of Attractions (2015), Boxing Day (2016) àti A trip to Jamaica(2016)[3] àwọn fíìmù yìi ́ni ó ti ṣe àfihàn Ayo Makun, Ramsey Nouah, Richard Mofe Damijo, Vivica Fox, Dan Davies, Lynn Whitfield, Eric Anthony Roberts, Paul Campbell, Funke Akindele, Karlie Redd, Nse Ikpe-Etim, Desmond Elliott, Rasaaq Adoti, Chet Anekwe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Robert Peters
Ọjọ́ìbíRobert Oyimemise Peters
6 Oṣù Kẹfà 1973 (1973-06-06) (ọmọ ọdún 51)
Sabon Gari, Kaduna State, Nigeria
Iṣẹ́actor, movie producer, director, cinematographer, voice-over artist
Ìgbà iṣẹ́1998 – present

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Peter sí ìlú Gari, ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná,[4] apá Àríwá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ-àbíṣìkejì láàrin àwọn ọmọ mẹ́jọ tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Àwọn òbí rẹ̀, Lawrence Adagba àti Comfort Peters wá láti ìlú Ososo, ní Akoko Edo, ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó.

Peter bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní St. Gregory Primary School, ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná, ibẹ̀ sì ni ó ti parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó sì lọ sí ilé-ìwé gíga, Yunifásítì ìlú Jos tí ó wà ní ipinle Jos, níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Geology and Mining.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Peters bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré fíìmù àgbéléwò ní ọdún 1998 níbi tí ó ti kópa nínú fíìmù  Mama Sunday, lẹ́yìn náà, ó kópa nínú fíìmù kan tí wọ́n máa ń ṣe àfihàn rẹ̀ lórí ẹ̀rọ̀ amóhùn-máwòrán lójoojúmọ́, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́  Everyday People, tí Tajudeen Adepetu gbé jáde. Ní ọdún 2004, ó kó kúrò lórílẹ̀-èdè Naijiria láti lọ sí òkè-òkun, ní U.S,[5] níbi tí ó ti gboyè nínú Visual Storytelling, ní New York University. Lẹ́yìn náà, Peters dara pọ̀ mọ́ àwọn òṣèré ní ìlú Atlanta, ibẹ̀ sì ni ó ti rí iṣẹ́ láti máa kọ́ nípa bí a ṣe ń darí fíìmù àgbéléwò. Wọ́n tún mú u ní REDucation, ibí sì ni àwon akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti fún un lẹ́kọ̀ọ́ tó kójú òṣùwọ̀n nípa bí a ṣe ń ya eré lóríṣiríṣi àti bí a ṣe ń lo àwọn ohun èlò kámẹ́rà láti fi yàwòrán dáadáa, tí ó sì kọ́ṣẹ́mọṣẹ́.

Peters bẹ̀rẹ̀ iṣé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olóòtú àti ayàwòrán àti fọ́rán fún fíìmù àgbélewò ní pẹrẹu lọ́dún 2006, ó sì ṣiṣẹ́ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Afirika àti Amerika.[5] . Láàrin ọdún mẹ́wàá, ó ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré ṣiṣẹ́ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan bíi;  Vivica A. Fox, Lynn Witfield, Eric Roberts, Karlie Redd, Paul Cambell, Richard Mofe-Damijo, Neville Sajere, Ayo Makun, Ramsey Nuoah, Desmond Elliott, Majid Michel, Jim Iyke, Chris Attoh, Funke Akindele, Oc Ukeje, Jeta Amata, Van Vicker, Nse Ikpe Etim, Lisa Raye McCoy, Mercy Johnson, Stella Damasus, James Michael Costello, Sulehk Sunman, Yvonne Okoro, Carl Anthony Payne, Joseph Benjamin àti Tangi Miller.

Ní ọdún 2014, ìròyìn jẹ́ ka mọ̀ pé fíìmù àgbéléwò kan tí Peters jẹ́ olùdarí fún, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ 30 Days in Atlanta ló jèrè owó tó pọ̀ jù lọ.[6] Ó sì di àkọsílẹ̀ lọ́dọ àwọn Guiness Book of Records pé fíìmù ọ̀hún ló jèrè owó tó pọ̀ jù lọ láàrin àwọn fíìmù orílẹ̀-èdè Naijiria, India àti Amerika[7]

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ tó gbà

àtúnṣe
Year Award Category Film Result
2010 Nafca Awards Best Cinematography Gbàá
2012 Nafca Awards Best Cinematography Gbàá
2013 Golden Icons Academy Movie Awards Best Director Gbàá
2015 Nafca Awards Best film Gbàá
2015 Golden Icons Academy Movie Awards Best Film Gbàá
2015 Golden Icons Academy Movie Awards Best Director Gbàá
2015 Best of Nollywood Awards Best Comedy Gbàá
2015 African Academy Movie Awards AMAA 2015 Best Comedy Gbàá
2015 Golden Icons Academy Movie Awards Best Comedy Gbàá
2016 2016 AMVCA (Africa Magic Viewers Choice Awards) Best Cinematography style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé
2016 African Academy Movie Awards AMAA Best film made by African living Abroad style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé

Àtòjọ àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe

Feature Films

Year Title Notes Role Type
2009 Black November Directed by Jeta Amata Actor Feature Film
2011 Le Silence Pure French/English Movie Cinematographer/Director Feature Film
2012 Black Money A Vogue entertainment production Director/DP Feature Film
2012 Reflections Directed by Desmond Elliot and shot in Sierra Leone Cinematographer Feature Film
2013 Refugees Yvonne Nelson, Belinda Effah, Diana Yekinni, Sandra Don Dufe, Ross Fleming, David Chin Cinematographer Feature Film, nominated for Best Cinematography at the 2016 AMVCA
2013 Shrink Wrap NBC USA Series (One purpose production) Lead Cinematographer Feature Film
2013 Faces of Love Starring Monica Swaida, Raz Adotti, Syr Law Directed by Robert Peters Feature Film
2013 Knocking on Heaven’s Door' Royal Art Academy Lagos, Production Lead Cinematographer Feature Film
2014 30 Days In Atlanta Starring Ayo Makun, Ramsey Nouah, Richard Mofe Damijo, Vivica Fox, Mercy Johnson, Rachel Oniga, Karlie Redd, Majid Michel and Lynn Whitfield Director Feature Film
2014 Affairs of The Heart "Nevada Bridge Production" Starring Stella Damasus, Joseph Benjamin, Beverly Naya, Monica Swaida Director Feature Film
2015 Carpe Diem DSTV Africa Magic’s Original film Director Feature Film
2015 The Dowry Man DSTV Africa Magic’s Original film Director Feature Film
2015 Boxing Day A Gifted Gift Studios Production; starring Razaaq Adoti, Richard Mofe Damijo, Joseph Benjamin, Yvonne Okoro, Tangi Miller, Wistina Taylor, Carl Payne, Ikenna Obi Director Feature Film
2015 Shades of Attraction Post-production; "Nevada Bridge Production" OC Ukeje, Richard Mofe Damijo, Ernestine Johnson, Desmond Elliott, Van Vicker, Tasia Grant Director Feature Film
2016 A Trip to Jamaica Post-production Director Feature Film
2016 Closure Post-production Director Feature Film
2016 Lagos Blues Pre-production Director Feature Film

Awon Itokasi

àtúnṣe
  1. Ndubuisi, Vincent (20 December 2014). "’30 Days In Atlanta’ is Currently Nollywood’s Highest Grossing Cinema Movie of All Time". Golden Icons (Lagos, Nigeria). http://www.goldenicons.com/30-days-in-atlanta-is-currently-nollywoods-highest-grossing-cinema-movie-of-all-time/. Retrieved 7 June 2016. 
  2. Abdul, Sule (5 August 2014). "30 Days In Atlanta Movie Trailer". Nigerian Watch (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 19 September 2016. https://web.archive.org/web/20160919071502/http://www.nigerianwatch.com/ents/nollywoodwatch/5011-30-days-in-atlanta-movie-trailer. Retrieved 7 June 2016. 
  3. Ezegbu, Tobe (13 November 2015). "New Movie, A Trip to Jamaica (Sequel To 30 Days in Atlanta)". This is Nollywood (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 30 June 2016. https://web.archive.org/web/20160630094409/http://thisisnollywood.com.ng/new-movie-a-trip-to-jamaica-sequel-to-30-days-in-atlanta/. Retrieved 7 June 2016. 
  4. Films, Nigeria (10 August 2009). "Actor Roberts Wedding Photos". Nigeriafilms (Lagos, Nigeria). http://www.nigeriafilms.com/news/5584/6/actor-robert-peters-wedding-album.html. Retrieved 7 June 2016. 
  5. 5.0 5.1 Agbo, Dennis (10 August 2009). "Actor Robert Peter's Wedding Album". Nigeriafilms (Lagos, Nigeria). http://www.nigeriafilms.com/news/5584/6/actor-robert-peters-wedding-album.html. Retrieved 7 June 2016. 
  6. Olehi, Uche (23 December 2014). "Amazing success of 30 Days in Atlanta thrills AY -How the movie grossed N76 million in 42 days!". Encomium Magazine (Lagos, Nigeria). http://encomium.ng/amazing-success-of-30-days-in-atlanta-thrills-ay-how-the-movie-grossed-n76-million-in-42-days/. Retrieved 7 June 2016. 
  7. Izuzu, Chidumga (7 September 2016). ""30 Days in Atlanta" AY Makun's movie enters 2017 Guinness World Record". Pulse NG (Lagos, Nigeria). http://pulse.ng/movies/30-days-in-atlanta-ay-makuns-movie-enters-2017-guinness-world-record-id5466011.html. Retrieved 8 September 2016.