Samuel Ladoke Akintola

Olóṣèlú
(Àtúnjúwe láti Sámúẹ́lì Ladoke Akintola)

Samuel Ladoke Akintola (July 6, 1906 - January 15, 1966) je oloselu omo orile ede Naijiria lati eya Yoruba ni apa ila oorun. A bi ni ojo kefa osu keje odun 1906 ni ilu Ogbomosho.

Samuel Ladoke Akintola
Premier of Western Nigeria
In office
October 1, 1960 – January 15, 1966
AsíwájúObafemi Awolowo
Arọ́pòNone
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOṣù Keje 6, 1906(1906-07-06)
Ogbomosho, Nigeria
AláìsíOṣù Kínní 15, 1966 (ọmọ ọdún 55)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAction Group
OccupationLawyer

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Sámúẹ̀lì sínú ìdílé Akíntọ̀lá ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, bàbá rẹ̀ ni Akíntọ̀lá Akínbọ́lá nígba tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Àkànkẹ́ Akíntọ̀lá. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò tí ó jáde wá láti inú ẹbí oníṣòwò.[1] Nígbà tí ó kéré jọjọ, àwọn ẹbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Minna tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Naija lónìí. Ó kàwé léréfèé nílé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́rẹ̀ Church Missionary Society. Ní ọdún 1922, ó padà wá sí Ògbómọ̀ṣọ́ láti wá bá bàbá bàbá rẹ̀ gbé tí ó tún tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Oníyẹ̀tọmi ṣáájú kí ó tún tó tẹ̀ síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ Kọlẹ́ẹ̀jì ti onítẹ̀bọmi ní ọdún 1925. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Akádẹmì Onítẹ̀bọmi láàrín ọdún 1930 sí 1942, lẹ́yìn èyí ni ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ àjọ tó mójú tó ìrìnà Rélùwéè ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Lásìkò yí, ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú H.O. Davies, tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò àti olóṣèlú, ó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Nigerian Youth Movement níbi tí ó ti ṣàtìlẹyìn fún Ikoli láti di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣojú Ìpínlẹ̀ Èkò tako yíyàn tí wọ́n yan Samuel Akisanya, ẹni tí Nnamdi Azikiwe fara mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò dépò náà. Akíntọ́lá tún dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́, tí ó sì di olóòtú fún.iwé ìròyìn náà ní ọdún 1953 pẹ̀lú àtìlẹyìn Akinọlá Májà tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olówó ìwé-ìròyìn náà tí ó sì rọ́pò Ernest Ikoli gẹ́gẹ́ olóòtú. Akíntọ̀lá náà sì dá Ìwé-ìròyìn Yorùbá tí wọ́n ń fi èdè Yorùbá gbé kalẹ̀ ní ojojúmọ́. Ní ọdún 1945, ó tako ìgbésẹ̀ ìdaṣẹ́ sílẹ̀ tí ẹ́gbẹ́ òṣèlú NCNC tí Azikiwe àti Michael Imoudu, fẹ́ gùn lé, èyí sì mu kí ó di ọ̀dàlẹ̀ lójú àwọn olóṣèlú bíi Anthony Enahoro.[1] Ní ọdún 1946, Akíntọ̀lá rí ìrànwọ́ ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ gbà láti kàwé ọ̀fẹ́ ní U.K, níbi tí ó ti parí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ òfin, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò lórí òfin tí ó jẹ mọ́ ìlú. Ní ọdún 1952, òun àti Chris Ògúnbanjọ,olóyè Bọ̀dé Thomas àti Michael Ọdẹ́sànyà kóra jọ pọ̀ di ọ̀kan.



  1. 1.0 1.1 ""Akintola: Remembering a controversial politician"". The Nation Online. Retrieved 18 January 2016.