T. B. Joshua

(Àtúnjúwe láti T. B. Jóṣúà)

Tèmítọ́pẹ́ Balógun Joshua tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Karùn-ún ọdún 1963 tí ó sì papò da ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ọdún 2021. Jẹ́ Olùṣọ́ àgùtàn oníwàásù televangelist, philanthropist. Òun ni olùdásílẹ̀ ilé-ìjọsìn The Synagogue, Church of All Nations (SCOAN),[3] tí ó jẹ́ Ilé-ìjọsìn tí ó tóbi tí ó sì tún ṣakóso Emmanuel TV tí ó kalẹ̀ sí Ìpínlẹ̀ Èkó. Jóṣúà gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ní ilẹ̀ Áfíríkà ati apá Latin Amẹ́ríkà [4][5] ó ní àwọn olólùlùfẹ́ tí ó tó mílíọ́nù mẹ́rin (4,000,000) lórí ìtàkùn ìkànsíra-ẹni Facebook.[6] ojú òpó YouTube rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Emmanuel TV, ni ó ní tó mílíọ́nù kan ènìyàn tí wọ́n ṣíṣe wo lójúmọ́ fún wàásù ati ìhìn-rere, tí ó sì mu kí ó jẹ́ wípé Oju òpó rẹ̀ yí ni àwọn ènìyàn ń wo jùlọ.[7] slṣáájú kí àwọn aládlṣẹ ojú òpó Youtube to fagilé ojú òpó rẹ̀ ní ọdún 2021 látàrí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé kan tí ó ṣe ìwàádùn lórí rẹ̀ tí ó pè ní "Oprah of Evangelism"[8]. Jóṣúà ni wọ́n gbà wípé ó jẹ́ ajíhìn-rere tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní orí Ìtàkùn Yourube.[9] Wọ́n fún Jóṣúà ní àwọn amì-ẹ̀yẹ oríṣiríṣi bíi: Officer of the Order of the Federal Republic (OFR) láti ọwọ́ ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 2008.[10] Òun ni àjọ Pan-African Media outlet Irohin-Odua dìbò fún gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Yorùbá.[11] Ìwé ìròyìn àtìgbà-dégbà Pan African Magazine tún sọ wípé ó wà nínú àwọn àádọ́ta ènìyàn àkọ́kọ́ tí wọ́n gbajúmọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ nínú agbálọgbábọ̀ tiThe Africa Report àti New African Magazine.[12][13]

T. B. Joshua
Fáìlì:تى بى جوشوا.jpg
Ọjọ́ìbí(1963-06-12)12 Oṣù Kẹfà 1963
Arigidi Akoko, Nigeria
Aláìsí5 June 2021(2021-06-05) (ọmọ ọdún 57)[1]
Lagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́charismatic pastor, televangelist, philanthropist
Net worthUS$10–15 million (Forbes, 2011)[2]
Olólùfẹ́Evelyn Joshua
WebsiteThe Synagogue, Church Of All Nations, Emmanuel TV, YouTube Channel

Títí di 2011, Ilé-iṣẹ́ Forbes, sọ wípé Jóṣúà ni ajíhìn-rere kẹta tí ó lówó jùlọ ní àgbáyé,[14] àmọ́ kíá ni ìjọ náà ti bu ẹnu atẹ́ lu ìkéde tí Forbes ṣe yí.[15] Ìjọba orílẹ̀-èdè Cameroon fagi lé ìjọsín rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè wọn látàrí rúkèrúdò tí wọ́n gbà pe ìwàásù rẹ̀ ń mú bá wọn ní ọdún 2010.[16][17][18]

Synagogue, Church of All Nations (SCOAN)

àtúnṣe

Joshua kọ nínú ìran ọrùn tí ó rí wípé òhun gba àmì òróró àti májẹ̀mú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti dá iṣẹ́ ìránṣẹ́ sílè.[19] Lehin èyí, Joshua dá iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí a mọ̀ sí ìjọ Synagogue ti gbogbo orílẹ̀ (SCOAN). Gẹ́gẹ́ bí ohun tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà sọ, ìjọ náà ni ọmọ ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún meedogun (15,000) tí wọn ń jọ́sìn lọ́jọ́ ìsinmi tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀wò láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.[20] Àwọn olubewo wonyi má ń gbé ní àwọn ibùdó tí ìjọ náà pèsè nínú ọgbà ilé ìjọsìn náà.

Ìwé ìròyìn Guardian kọ ọ́ wípé ilé ìjọsìn náà ni a jọ́sìn ọ̀sẹ̀ ọ̀sẹ̀ tí ó pọ̀ ju olubewo tí wọn ń rí ní ilé Ọba bìnrin Èlísábẹ́tì tí ìlú Gẹ̀ẹ́sì àti ilé ìṣọ́ ìlú London ní àpapò. Ilé ìjọsìn náà ti ṣe okùnfà fún ọ̀rọ̀ ajé àti òwò ilé ìtura.[21][22][23]

The Guardian reported that SCOAN attracts more weekly attendees than the combined number of visitors to Buckingham Palace and the Tower of London.[24] SCOAN's popular services have also resulted in an enormous boost for local businesses and hoteliers.[25]

Pelu wípé Joshua jẹ́ ìlú mọ̀ ká ènìyàn, ẹ̀ka kan péré ni ìjọ rẹ ní sí ìlú Ghana.[26] Ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà wípé kò tíì tó àsìkò láti dá ẹ̀ka sílè káàkiri àgbáyé nítorí wípé yí ó ti pò jù fún ìwà rẹ.

Ìjọ SCOAN ni ìjọ tí ó fa èrò wá sí orílẹ̀ èdè Nigeria jù lọ, ó sì jé ibi tí àwọn a rin ìrìnàjò ṣe ìbẹ̀wò sí jùlọ ni ìwọ̀ oòrùn Afrika pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún lè ní ẹgbẹ̀rún àwọn ará òkè òkun tí wọ́n ń wá jọ́sìn ní ilé ìjọsìn náà ní ọ̀sẹ̀ ọ̀sẹ̀ . Ohùn kà tí ilé iṣẹ́ tí ó ń ṣíṣẹ́ ìrìnàjò ìwọlé àti ìjáde ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sọ ọ́ di mímọ̀ wípé mẹ́fà nínú mẹwa nínú àwọn arin ìrìn àjò wá sí orílè èdè Nàìjíríà ni wọ́n lọ sí ilé ìjọsìn náà tí ilé asòfin ilẹ̀ Zimbabwe fi ìdí rẹ̀ múlè ni ti ipa ètò ìsúná.

Ìwé ìròyìn This Day fi ìdí rẹ̀ múlè pẹ̀lú wípé mílíọ̀nù méjì àwọn arin ìrìnàjò láti òkè òkun àti láti àwọn ìpínlè ní Nàìjíríà ni wọ́n kọjá sí ilé ìjọsìn náà ní ọdún kọ̀ọ̀kan. Òkìkí ilé ìjọsìn náà tí jẹ́ kí àwọn tí wọn wọ ọkọ̀ Òfúrufú lọ sí ìlú Èkó láti gbogbo orílè èdè adúláwò pò sí.

Àwọn iṣẹ́ ìwòsàn àti ìyanu tí ìjọ SCOAN ń polongo pé òun ń ṣe nípa agbára Ọlọ́run

àtúnṣe

Ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ènìyàn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti lókè òkun ló máa ń kún ibi ìjọsìn SCOAN lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀ láti forúkọ sílẹ̀ fún ẹ̀bẹ̀ àdúrà lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan, tí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, T. B. Joshua á sìn máa gbàdúrà fún wọn.[27] Ìjọ SCOAN tí ṣe àtẹ̀jáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ fọ́nrán amóhùnmáwòrán tí wọ́n ti kéde pé wọ́n ṣe ìwòsàn oríṣiríṣi àwọn àìsàn àti àléébù ara ti wọn kò gbóògùn; àwọn àìsàn àti àléébù ara bíi ; àrùn kògbóògùn Éèdì (HIV/AIDS), ojú fífọ́ àti egbò-àdáàjiná. [28][29][30][31]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé ìròyìn ni wọn ti kọ nípa gbankọgbì àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìjọ SCOAN ń ṣe; pàápàá jù lọ, àwọn gbajúmọ̀ ìwé ìròyìn òkè-òkun, Time Magazine, ìròyìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ìwé ìròyìn Associate Press àti ìwé ìròyìn Foreign Policy tí wọ́n sìn tàkùrọ̀ sọ wípé, ìbá dára kí Nàìjíríà kúkú béèrè fún ìrànlọ́wọ́ iṣẹ́-ìyanu fún ètò ìlera orílẹ̀-èdè náà tí ó dẹnukọlẹ̀.

Àríyànjiyàn ńlá ló gbòde kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí bàbá ọmọ ilẹ̀-ìwé kan, Ese Oruru tí wọ́n rí lẹ́yìn tí wọ́n jí i gbé, pinnu pé òun yóò gbé ọmọbìnrin náà lọ sí ìjọ SCOAN kí Wòlíì TB Joshua lè gbàdúrà fún un. Bákan náà, ìròyìn kan tí ó yọ́ jáde wípé Mínísítà àná fún Epo-lọ̀bí, Arábìnrin, Diezani Alison-Madueke yóò lọ fún ìwòsàn àrùn-jẹjẹrẹ ọyàn tí ó ń bá a fínra ni ìjọ SCOAN fa àríyànjiyàn láàárín àwọn ènìyàn nígbà náà. [32][33]

Omi Mímọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n ti jẹ́rìí pé wọ́n gba ìwòsàn nípa lílo 'omi mímọ́ tí wòlíì TB Joshua gbàdúrà sí, tí wọ́n sìn fi ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n kò lè wá síbi ìpàdé àdúrà tí wọ́n ṣe nílé ìjọsìn wọn nílùú Èkó. Bákan náà, ọ̀pọ̀ jẹ́rìí pé wọ́n ní ìdáàbòbò lọ́wọ́ ìjàmbá ikú nítorí pé wọ́n ní omi náà lọ́wọ́.

Lọ́dún 2013, ènìyàn mẹ́rin ló kú nínú ìjàmbá ìtẹranimọ́lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ni ẹ̀ka ilé ìjọsìn TB Joshua lórílẹ̀ èdè Ghana lákòókò ìsìn kan, tí wọ́n kò wulẹ̀ kéde rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń pín omi mímọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, tí wọn pọ̀ bàbì ju agbára ènìyàn tí ilé ìjọsìn náà lè gbà lọ ya bó wọ́n ni Accra, Olú-ìlú orílẹ̀ èdè Ghana. Ẹsẹ̀ kò gbèrò, lọ́jọ́ tí à ń sọ yìí.

Nígbà kan, ọ̀pọ̀ ìwé-ìròyìn ló gbé ìròyìn nígbà tí Wòlíì TB Joshua kéde wípé omi mímọ́ òun lè ṣe ìwòsàn àrùn aṣekúpani Ebola. Lẹ́yìn èyí, ó fi ìgò omi mímọ́ yìí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin pẹ̀lú owó ilẹ̀ okere, $50,000 ránṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè Sierra Leone tí àjàkálẹ̀ àrùn Ebola tí ń jà rànhìnrànyìn nígbà náà. Èyí wáyé lẹ́yìn tí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera Ìpínlẹ̀ Èkó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó kéde pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ wá sí ilé ìjọsìn rẹ̀ fún ìwòsàn àrùn Ebola. Lẹ́yìn èyí, òṣèlú kan láti orílẹ̀ èdè Sierra Leone jẹ́rìí pé omi mímọ́ náà ṣe ìwòsàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ awon tí àrùn náà ń bá jà, tí sìn dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn náà lórílẹ̀ èdè náà.

[34]

Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Prophet T.B. Joshua is dead at 57". Peoples Gazette. 6 June 2021. Retrieved 6 June 2021. 
  2. "The Five Richest Pastors In Nigeria". Forbes. 6 July 2011. Retrieved 16 July 2015. 
  3. "Prophet TB Joshua". Scoan.org. Retrieved 16 July 2015. 
  4. Olawunmi, Akintola (11 November 2017). "TB Joshua: Christianity Needs A Human Face". Nigerian Tribune. Archived from the original on 13 April 2019. https://web.archive.org/web/20190413234615/https://www.tribuneonlineng.com/119091/. 
  5. "Popular Nigerian megachurch preacher T.B Joshua dies after Church program". Daily Post (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-06. Archived from the original on 2021-06-06. Retrieved 2021-06-07.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. Mpamugoh, Simeon (26 December 2017). "T.B. Joshua: Boosting Tourism With Religion". Daily Sun (Nigeria). https://www.sunnewsonline.com/t-b-joshua-boosting-tourism-with-religion/. 
  7. Olowookere, Dipo (27 October 2018). "TB Joshua's Emmanuel TV Hits 1m YouTube Subscribers, 387m Views". Business Post (Nigeria). https://businesspost.ng/2018/10/27/tb-joshuas-emmanuel-tv-hits-1m-youtube-subscribers-387m-views/. 
  8. Palet, Laura (18 September 2016). "The Millionaire On God's Payroll". OZY. Archived from the original on 22 August 2017. https://web.archive.org/web/20170822013113/http://www.ozy.com/provocateurs/the-millionaire-on-gods-payroll/69198. 
  9. Oshin, Tope (27 September 2016). "TB Joshua Honoured In Peru After Crusade In South America's Largest Stadium". Signal (Nigeria). http://www.signalng.com/t-b-joshua-honoured-peru-crusade-south-americas-largest-stadium/. 
  10. Umem, James (23 December 2008). "Adeboye, TB Joshua Absent At National Awards". Vanguard. http://allafrica.com/stories/200812230193.html. 
  11. "Awo, Soyinka, TB Joshua listed as Yoruba icons". Nigerian Tribune. 20 February 2015. http://www.tribune.com.ng/news/news-headlines/item/30003-awo-soyinka-tb-joshua-listed-as-yoruba-icons/30003-awo-soyinka-tb-joshua-listed-as-yoruba-icons. 
  12. "The 50 Most Influential Africans". The Africa Report. 30 September 2012. http://www.theafricareport.com/west-africa/the-50-most-influential-africans-t-b-joshua.html. 
  13. "2012: 100 Most Influential Africans". New African Magazine. 26 December 2012. http://www.newafricanmagazine.com/special-reports/other-reports/2012-100-most-influential-africans/religion-traditional. 
  14. "Pentecostalism in Africa: Of prophets and profits". The Economist. 4 October 2014. https://www.economist.com/news/middle-east-and-africa/21621885-collapsed-building-highlights-international-reach-nigerias. 
  15. Makhaya, Trudi (17 September 2014). "Malaysian Flight MH370: Prophecy Video Emerges Dated July 28". ENCA (South Africa). Archived from the original on 8 June 2021. https://web.archive.org/web/20210608134123/https://www.enca.com/evangelical-wealth. 
  16. Ateba, Simon (30 September 2010). "Cameroon Blacklists TB Joshua". PM News (Nigeria). http://www.pmnewsnigeria.com/2010/09/30/cameroon-blacklists-t-b-joshua/. 
  17. "Zimbabwe Churches Say TB Joshua Not Welcome". Zambia Watchdog (Zambia). 18 May 2012. http://www.zambiawatchdog.com/zimbabwe-churches-say-tb-joshua-not-welcome/. 
  18. "Inside TB Joshua's broken temple" (in en). News24. https://www.news24.com/Africa/News/Inside-TB-Joshuas-broken-temple-20140921. 
  19. Gaffey, Conor (12 February 2016). "Who Is TB Joshua, Nigeria's Mega Preacher Accused Of Criminal Negligence". Newsweek (Europe). http://europe.newsweek.com/who-tb-joshua-nigerias-mega-preacher-accused-criminal-negligence-426036. 
  20. "Celebrity Priests". The Economist. 7 July 2012. http://www.economist.com/node/21558298. 
  21. "The Synagogue Church of All Nations in Lagos, Nigeria; Travel report of my visit to the Synagogue Church – March 13–22, 2007". Vergadering.nu. Retrieved 16 July 2015. 
  22. "Report on TB Joshua, the man in the Synagogue". Bennier.tripod.com. Retrieved 16 July 2015. 
  23. "revivalinpower". revivalinpower. Archived from the original on 11 March 2016. Retrieved 16 July 2015. 
  24. Mark, Monica (1 September 2013). "Lagos Businesses Cash In On Lure Of Super Pastor TB Joshua". The Guardian (UK). https://www.theguardian.com/world/2013/sep/01/lagos-businesses-superpastor-joshua. 
  25. Ben-Nwankwo, Nonye (17 August 2013). "TB Joshua's Neighbours Convert Homes To Hotels". The Punch (Nigeria). Archived from the original on 22 February 2014. https://web.archive.org/web/20140222172909/http://www.punchng.com/feature/super-saturday/tb-joshuas-neighbours-convert-homes-to-hotels/. 
  26. Umoren, Comfort (21 September 2010). "3 Jailed For Robbing T.B. Joshua's Church In Ghana". This Day. Archived from the original on 16 March 2012. https://web.archive.org/web/20120316214815/http://www.thisdaylive.com/articles/3-jailed-for-robbing-tb-joshua-s-church-in-ghana/78374/. 
  27. "TB Joshua now releases videos of his early days miracles". Zambian Eye. 23 October 2012. Archived from the original on 10 August 2014. https://web.archive.org/web/20140810120518/http://zambianeye.com/archives/1728. 
  28. "Prophet TB Joshua Heals A Man Who Has AIDS". Nigeria Films. 2 February 2014. http://www.nigeriafilms.com/news/25317/64/prophet-tb-joshua-heals-a-man-who-has-aids.html. 
  29. "People 'healed' of HIV-AIDS after visiting Nigerian Prophet TB Joshua". Harare24. 2012. Archived from the original on 2019-08-02. https://web.archive.org/web/20190802120638/http://harare24.com/index-id-news-zk-12869.html. 
  30. "Prophet T.B.Joshua & The Synagogue". The Remnant. 1 February 2008. Archived from the original on 2 August 2019. https://web.archive.org/web/20190802120632/http://www.theremnant.com/08-02-01.html. 
  31. Zaimov, Stoyan (12 April 2017). "Blind Man Shouts 'I Can See!' at Controversial Pastor TB Joshua's Healing Service". Christian Post. https://www.christianpost.com/news/blind-man-shouts-i-can-see-at-controversial-pastor-tb-joshuas-healing-service-180264/. 
  32. Kluger, Jeffrey (12 February 2009). "Spiritual Healing Around The World". Time Magazine. Archived from the original on 3 August 2013. https://web.archive.org/web/20130803025639/http://www.time.com/time/photogallery/0,29307,1878443_1842216,00.html. 
  33. Petesch, Carley (19 April 2014). "Nigeria Preacher: Healer Or Controversial Leader". Associated Press. Archived from the original on 2 May 2014. https://web.archive.org/web/20140502032709/http://bigstory.ap.org/article/nigeria-preacher-healer-or-controversial-leader. 
  34. Jacobs, Bamikole (16 December 2022). "Prophet T.B Joshua Biography, Wikipedia, Net-worth, Age, And Ministry". Nobelie.com. Archived from the original on 15 March 2023. Retrieved 1 March 2023.