Tade Ogidan
Akíntádé Ògìdán, aka Tádé Ògìdán tí a bí ní osù Keje,ọdún 1960), jẹ́ òsèré, o ǹ kọ̀tàn, olùgbéjáde àti olùdarí eré oníse ti ilẹ̀ Nàìjíríà .
Tádé Ògìdán | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oṣù keje, Ọdún 1960 Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ |
|
Notable work | Family on Fire Dangerous Twins |
Parent(s) | Akinolá àti Rachael Ògìdán |
Awards | Nollywood Awards tí ódára jù ti ẹ̀ka olùdarí |
ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí ayé
àtúnṣeA bíi sí ìlú Èkó ní ilẹ̀ Nàìjíríà, sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni Akinọlá àti Rachael Ògìdán. Ó dàgbà ní Sùúrùlérè, agbègbè ti Ìpínlẹ̀ Èkó ní ilẹ̀ Nàìjíríà.
Ẹ̀kọ́
àtúnṣeÓ lọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀óbẹ̀rẹ̀ ní àárín ọdún 60s sí 70s ní Government Demonstration School àti Sùúrùlérè Baptist School, tí méjèèjì wà ní Sùúrùlérè, Lagos. Láàríń ọdún 1972 sí ọdún 1974, ó lọ sí ilé ìwé girama ní Èkìtì Parapọ̀ College, Ìdó-Èkìtì, o si jáde ní Maryland Comprehensive Secondary School, Ikeja, Lagos, ní ọdún 1978. Láti ọdún 1979, Ògìdán lọ sí Eastern New Mexico University ni Portales, NY, USA. Ó parí ìgbà díẹ̀ ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ ti New York, ní Buffalo, NY, USA.
TV
àtúnṣeLáti ọdún 1982 sí ọdún 1983, Tádé Ògìdán parí ètò ìsìnlú ìjọba ti lẹ̀ Nàìjíríà (National Youth Service Corp) ní Nigerian Television Authority (NTA) ti Ìpínlẹ̀ Èkó. Lẹ́yìn náà, ó di Olùgbéjáde / Olùdarí pátápátá ní NTA Channel 10, áti Olùkéde Ìtẹ̀síwájú pẹ̀lú NTA 2 - ìkànnì 5, lápapọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ilẹ̀ Nàìjíríà. Ògìdán lo ọdún mẹ́jọ pẹ̀lú Ilé-iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ilẹ̀ Nàìjíríà, (NTA 10, NTA 2 - Channel 5 àti NTA National Network Service and projects).
Ní NTA, ó ṣe àgbéjáde/darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré orí ìtàgé kéékèèké bíi PLAY OF THE WEEK, TELE THEATER, LEGAL ANGLE, VILLAGE HEADMASTER àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn DRAMA pátàkì lórí NTA National Network. Ó di olokiki gẹ́gẹ́ bíi olùgbéjáde / olùdarì àwọn eré orí ìtàgé kéékèèké bíi Blinking Hope, The Boys Next Door, and To Save a Falling Angel. Ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ àkànṣe eré orí ìtàgé tí ó siṣẹ́ lé lórí nígbà náà,THE REIGN OF ABIKU, tí Sola Osofisan kọ, gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ púpọ̀ ní Nigerian Festival of Television Programmes, NIFETEP 1986.
Ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìfihàn ìwé ìròyìn, SUNNY SIDE OF LIFE, tí Patrick Ityohegh jẹ́ olóòtú rẹ̀, àti àwọn iṣẹ́ àkànṣe mìíràn tí Peter Igho ati Chris Ebie jẹ́ aláṣẹ Olùgbéjáde.
Sinimá
àtúnṣeTádé Ògìdán fi ilé iṣẹ́ NTA sílẹ̀ fún iṣẹ́ aládàáni ní ọdún 1990 ó sì gbé ilé iṣẹ́ OGD PICTURES, LTD. OGD jẹ́ fífà yọ láti orúkọ ìkẹyìn rẹ̀, OGIDAN. Láti ìgbà náà ni ó ti ń kọ, gbéjáde àti darí àkànṣe Sinimá bíi Hostages, Owo Blow, Diamond Ring, Out Of Bonds, Raging Storm, 7 – 12, Playing Games, Saving Alero, Dangerous Twins, Madam Dearest, Ayo Mi Da Family On Fire and Gold Statue tí èyí tí ó pọ̀ nínú rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó gba àmì ẹ̀yẹ nínú àti lẹ́yìn odi ilẹ̀ Nàìjíríà.
Àkànṣe iṣẹ́ amóhùnmáwòrán mìíràn
àtúnṣeTádé Ògìdán àti ẹgbẹ́ OGD PICTURES ti ṣiṣẹ́ lórí àwọn iṣẹ́ àkànṣe mìíràn fún ìgbóhùnsáféfé lórí amóhùnmáwòrán, bíi BEHIND THE SIEGE seasons 1 & 2 ti Tosin James Atega (I Am James) kọ (eré orí ìtàgé kéékèèké kan tí a ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ FHI / USAID), CRIME FIGHTERS (pẹlu BI COMMUNICATIONS), the TEJU BABYFACE SHOW, THE INTERN (Entrepreneurial Reality TV show, tí Ofem Ofem ṣe àgbéjáde rẹ̀), ati The Next Titani (an Entrepreneurial Reality TV show with Mide Akinlaja, FICOMMS LTD. )
Gbígbéjáde àwọn ìkéde TV
àtúnṣeTádé Ògìdán àti ẹgbẹ́ rẹ̀ ní OGD PICTURES ṣiṣẹ́ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn TVC fùn àwọn ilé-iṣẹ́ ìpolówó bíi Prima Garnet, Verdant Zeal, Lintas, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, apoti TVCs fun Crystal Bank, First Bank, FCMB, ABC Wax, Nigeria Export Processing Zone, Nigeria Airways, Royco, Maggi, Ajinomoto Seasoning, Pade Toothpaste, Arik Air, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì lórí ẹ̀rọ ayé lukára
àtúnṣeÀmì ẹ̀yẹ ètò ẹ́kọ́ ti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lọ́dún 2013 ni ẹgbẹ́ OGD tí Tádé Ògìdán darí. ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan fún ṣíṣe àfihàn orin láàrín ọgọrun le àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama ti ìjọba ní ìlú èkó pẹ̀lú àwọn gbajúgbajà òṣèré ilẹ̀ Nàìjíríà bíi Femi Adebayo, Bello, Iya Awero, Yomi Fash Lanso, Sola Sobowale, Ireti Osayemi, Gideon Okeke, àti Faithia Balogun.
Tádé Ògìdán tún ṣètò àpéjọ ayẹyẹ àmì ẹ̀yẹ ètò ẹ́kọ́ ti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 2014, eré orin kíkọ tí ó ṣe àfihàn àwọn ọmọ ilé-ìwé girama ti ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tí ó ju igba lọ pẹ̀lú àwọn gbajúgbajà òṣèré bíi Bimbo Manuel, Sola Sobowale, Patience Ozokwor, Hafiz Oyetoro (Saka), Yinka Akanbi, Femi Adebayo, Gloria Young, Lepacious Bose, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ .
Àkànṣe isẹ́ àgbése orin fún Gbogbo gbajúgbajà onítàn ti OGD
àtúnṣeNí àkókò tí iṣẹ́ n lọ lórí ohùn orin Madam Dearest (Aya Mi ọ̀wọ́n), eré oníṣe tó lágbára, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré ati awọn irawọ TV, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin ati awọn fidio tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní OGD ALL STARS jáde. Àkọ́kọ́ irú rè ní ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sàfihàn ìràwọ̀ òṣèré Richard Mofe-Damijo, Stella Damasus Aboderin, Ramsey Nouah, Segun Arinze, Yinka Akanbi, Akin Lewis, Sola Sobowale, Deji Adenuga, Lanre Balogun, Lizzy Bariya, Dorin Onasanya, Teju Babyface, Saheed Balogun, Kunle Afolayan, Gabriel Afolayan, Funke Akindele, Akin Oyelola, Ab, Sola Onomor, Precious, Florence Wilkie, Bolu, Keppy Ekpenyong, Tina Mba, Kate Henshaw, Bimbo Akintola, 2-Effects, Remi Oshodi, Bukky Ajayi, Tariah Jnr., Bimbo Manuel, Esse Agesse, Yemi Solade, Ope Ayeola, Shaggy, Shedrack, Tunji Olugbodi, Sunday Afolabi, Wande Coal, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ .
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeTádé Ògìdán ti ní ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ.
Eré oníṣe tí ó ti ṣe
àtúnṣeOdun | Akọle | Oludari | |
---|---|---|---|
Ọdun 1995 | Owo Blow | Tade Ogidan | |
Ọdun 1997 | Jade kuro ni Ilẹ | Tade Ogidan | |
Ọdun 1998 | Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ | Tade Ogidan | |
Ọdun 1998 | Oruka Diamond | Tade Ogidan | |
Ọdun 2001 | Nfipamọ Alero | Tade Ogidan | |
Ọdun 2003 | Ayomida | Tade Ogidan | |
Ọdun 2012 | Ti ndun awọn ere | Tade Ogidan | |
Ọdun 2004 | Ewu Twins | Tade Ogidan | |
Ọdun 2005 | Aya mi owo: Madam Dearest | Tade Ogidan | |
Ọdun 2011 | Ebi lori Ina | Tade Ogidan | |
2019 | Gold Ere | Tade Ogidan |
Odun | Eye | Ẹka | Abajade | Ref |
---|---|---|---|---|
2019 | Ti o dara ju ti Nollywood Awards | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé |
Awọn itọkasi
àtúnṣe