The White Handkerchief
The White Handkerchief | |
---|---|
Adarí | Tunde Kelani |
Olùgbékalẹ̀ | Tunde Kelani |
Òǹkọ̀wé | Tunde Kelani Akinwunmi Isola |
Àwọn òṣèré | Yemi Komolafe Yemi Shodimu Khabirat Kafidipe |
Orin | Beautiful Nubia |
Ìyàwòrán sinimá | Tunde Kelani |
Olóòtú | Kehinde Aje Moji Bamtefa |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Mainframe Film and Television Productions |
Olùpín | Mainframe Film and Television Productions |
Déètì àgbéjáde | 1998 |
Àkókò | 17 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
The White Handkerchief jẹ́ fíìmù Nàìjíríà kékeré kan tó jáde ní ọdún 1998, èyí tí Tunde Kelani jẹ́ olùdarí rẹ̀, tí ó sì ṣàfihàn àwọn òṣèré bí i Yemi Komolafe, Yemi Shodimu, àti Khabirat Kafidipe.[1] Fíìmù yìoí jẹ́ àyọkúrò ìwé ìtàn-àròsọ ti Bayo Adebowale, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ The Virgin.[2][3]
Àhunpọ̀ ìtàn ní ṣókí
àtúnṣeFíìmù náà dá lórí ìtàn ọ̀dọ́bìnrin abúlé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Awero, tí Sola Asedeko ṣe, tí ó pàdánù ipò wúńdíá rẹ̀ látàrí ìfipábánilòpọ̀ kí ó tó pàdé olólùfẹ́ ìgbà èwe rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odejimi, ẹni tí ó pinnu láti fẹ́ ẹ. Odejimi gbọ́dọ̀ lo aṣọ funfun, kí ó ba lè dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé ó bá Àwèró ní wúńdíá ní alẹ́ ìgbéyàwó wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣà ilẹ̀ náà. Inú Odejimi bàjẹ́ nígbà tí kò sí ẹ̀jẹ̀ lórí aṣọ funfun náà, èyí sì fa ogun láàárín àwọn ará abúlé Àwẹ̀ró àti Odejimi.[4][5]
Àwọn akópa
àtúnṣe- Sola Asedeko
- Idowu Philips
- Khabirat Kafidipe
- Yemi Shodimu
- Akinwunmi Isola
- Yemi Komolafe
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "At 66, Tunde Kelani produces 18th movie". Nigerian Entertainment Today - Nigeria's Number 1 Entertainment Daily. Retrieved 5 April 2015.
- ↑ "Continual Re-enchantment: Tunde Kelani's Village Films and the Spectres of Early African Cinema". framescinemajournal.com. Archived from the original on 1 November 2020. Retrieved 5 April 2015.
- ↑ "Best of Nigeria's literary adaptations into movies". tribune.com.ng. Retrieved 5 April 2015.
- ↑ "White Handkerchief". African Film Festival Inc. Retrieved 5 April 2015.
- ↑ Griswold, Wendy (19 June 2000). Bearing Witness. ISBN 0691058296. https://books.google.com/books?id=kf7_x8yz430C&q=The+virgin,+Bayo+Adebowale+novel&pg=PA124. Retrieved 5 April 2015.