Tóyìn Abraham

òṣèré orí ìtàgé
(Àtúnjúwe láti Toyin Abraham)

Toyin Abraham[3] tàbí Olutoyin Aimakhu; ni wọ́n bí ní (September 5, 1984). Ó jẹ́ òṣèré orí ìtàgé , olùgbéré-jáde àti adarí eré, ọmọ rílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[4][5][6][7]

Toyin Abraham
Toyin Abraham at AMVCA 2020
Ọjọ́ìbí5 Oṣù Kẹ̀sán 1980 (1980-09-05) (ọmọ ọdún 44)
Auchi, Edo, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • actress
  • filmmaker
  • producer
  • director
Ìgbà iṣẹ́2003–present
Olólùfẹ́Kolawole Ajeyemi[1][2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bi ní ìlú Auchi, tí ó jẹẹ́ ìlú kan ní town in ìpínlẹ̀ Ẹdó ní orílẹ̀-èdẹ Nàìjírìà. Àmọ́ ṣá, ó bẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn, tí ó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó gba ìwé ẹ̀rí HND (Higher National Diploma) ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe ìlú Ìbàdàn ìyẹn (Ibadan Polytechnic), lásìkọ́ yí, ó jẹ́ akẹgbẹ́ pẹ̀lú Dibie, C.B.N aka x7, Tóyìn Abraham ti fara hàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré, tí ó sì tún ṣẹ̀ṣẹ̀ kópa nínú sinimá àgbéléwò aré tí orúkọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Black Val.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Tóyìn bẹ̀rẹ̀ eré orí ìtàgé rẹ̀ nígbà tí gbajú-gbajà òṣèré orí-ìtàgé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bukky Wright, wá sí ìlú Ìbàdàn láti yàwòrán eré kan .Ó ti darí, kópa àti gbé eré jáde fúnra rẹ̀, lára rẹ̀ ni Àlání Bàba Làbákẹ́ àti d Èmi ni. Wọ́n yàán gẹ́gẹ́ bí òṣèré amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin tó dára jùlọ (Best Supporting Actress) nínú eré orí ìtàgé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Ẹ̀bi mi ni" nínú àmì ẹ̀yẹ 2013 Best of Nollywood Awards , bákan náà ni wọ́n yan Jọkẹ́ Múyìwá fún Best Lead Actress nínú eré tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ayítakẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú ló ti pèé láti bá wọn polongo ètò ìdìbò fún Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ tí ó jẹ́ adíje dupò sí orí àpèrè Ààrẹ ìyẹn Goodluck Ebele Jonathan ní ọdún 2015. Tóyìn pàá pàà só wípé òun lè kú torí ẹgbẹ́ òṣèlú People Democratic Party (PDP) kú[8] tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí adíje dupò náà ti ń díje. Àmọ́ ṣá, ó padà yí gbólóhùn rẹ̀ padà wípé òun bẹ àwọn olólùfẹ́ òun wípé kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹnikẹni sílẹ̀ lásìkò ìdìbò.

Àwọn eré ìtàgé rẹ̀

àtúnṣe
  • Okafor's Law (2016)
  • Love is in the Hair (2016)
  • Àlàní Bàbá Làbákẹ́ (2013)
  • Ẹ̀bi mi ni (2013)
  • Alákadá (2013)
  • Ṣọlá fẹ́ pa mí
  • Ghost and the tout (2018)

Àwọn fíìmù rẹ̀ tí a yàn

àtúnṣe

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

àtúnṣe
Ọdún Àmì-ẹ̀yẹ Ìsọ̀rí Iṣẹ́ Èsì Ìtọ́ka
2010 Best of Nollywood Awards Best Indigenous Actress in a Lead Role (Yoruba) Awa Obinrin Yàán
2011 Best of Nollywood Awards Best Indigenous Actress in a Lead Role (Yoruba) Ikudoro Yàán
2012 Yoruba Movie Academy Awards Best Actress in Leading Role Yàán
2013 Yoruba Movie Academy Awards Best Cross Over Actress Jejeloye Yàán
Best of Nollywood Awards Best Actress in a Lead Role –Yoruba film Alani Baba Labake Yàán
2016 Best of Nollywood Awards Best Actress in a Lead Role(Yoruba) Metomi Gbàá
2017 Five Continents International Film Festival Best Supporting Actress Feature Film Hakkunde Gbàá [12]
Best of Nollywood Awards Best Supporting Actress –English Tatu (film) Wọ́n pèé [13]
2018 Africa Magic Viewers' Choice Awards Best Supporting Actress Tatu Yàán
Africa Movie Academy Awards Best Actress in a Supporting Role Esohe Yàán
2020 Africa Magic Viewers' Choice Awards Best Actress in a Drama Elevator Baby Gbàá [14]
Best Actress in a Comedy Bling Lagosians Wọ́n pèé
Best Actress in a Comedy Kasanova Wọ́n pèé
Best of Nollywood Awards Best Actress in a Lead role –English Elevator Baby Wọ́n pèé [15]
NET Honours Most Popular Actress Yàán
2023 Legit.ng's Readers Choice Awards Best Actress Yàán
NET Honours Most Popular Actress Yàán
2024 Legit.ng Entertainment Awards Best Actress Yàán

Ẹ tún le wo

àtúnṣe
  • List of Nigerian film producers

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Fans claim Toyin Abraham is expecting another child - NewsWireNGR". NewsWireNGR. May 3, 2022. Retrieved May 29, 2022. 
  2. Adebayo, Segun (January 23, 2022). "My husband not living off my money, he works hard —Toyin Abraham". Tribune Online. Retrieved May 29, 2022. 
  3. "Nollywood Star, Aimakhu Now To Be Called Toyin Abraham". Channels Television. https://www.channelstv.com/2016/12/29/nollywood-star-aimakhu-now-to-be-called-toyin-abraham/. Retrieved 30 December 2016. 
  4. Mix, Pulse (May 27, 2022). "Purit unveils Toyin Abraham as brand ambassador for 30 years anniversary". Pulse Nigeria. Retrieved May 29, 2022. 
  5. Obinna, Chioma (April 15, 2022). "Toyin Abraham soars higher!". Vanguard News. Retrieved May 29, 2022. 
  6. Bada, Gbenga (May 27, 2022). "Toyin Abraham, Odunlade rejoice as Bamidele Onalaja celebrates with widows - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper. Retrieved May 29, 2022. 
  7. "Toyin Abraham and Lizzy Anjorin: Wetin cause dia gbas-gbas - BBC News Pidgin". BBC News Pidgin. May 26, 2021. Retrieved May 29, 2022. 
  8. "I am ready to die for PDP-Toyin Aimakhu". Gistmaster. Archived from the original on 2018-07-26. https://web.archive.org/web/20180726071955/http://niyitabiti.net/2015/03/i-am-ready-to-die-for-pdp-toyin-aimakhu/. Retrieved 2018-01-03. 
  9. "Toyin Abraham, Rita Dominic return to set for The Therapist". The Nation. 2 September 2020. Retrieved 6 April 2021. 
  10. Augoye, Jayne (2022-07-26). "Toyin Abraham, Bimbo Akintola, Akin Lewis star in new romantic-comedy 'The Stranger I Know'". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-23. 
  11. "Damilare Kuku, Toyin Abraham, Sandra Okunzuwa Star in – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Archived from the original on 2022-08-23. Retrieved 2022-08-23. 
  12. "Toyin Abraham". IMDb. Retrieved 10 October 2020. 
  13. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named auto
  14. "AMVCA 2020: Full list of winners". Pulse Nigeria. 14 March 2020. Retrieved 10 October 2020. 
  15. Augoye, Jayne (2 December 2020). "2020 BON: Here are 5 nominees for 'Best Kiss' category". Premiumtimesng.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 October 2021. 

Àwọn ìjásóde

àtúnṣe
  • Toyin Abraham on IMDb