Thomas Yayi Boni (ọjọ́ìbí 1 July 1952) jẹ́ gbajúmọ̀ onímọ̀ ìfowópamọ́ àti òṣèlú àti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Benin láti ọdún 2006 sí 2016. Ó gba ìjọba lẹ́yìn tí ó wọlé nínú ìdìbò Ààrẹ ti orílẹ̀-èdè Benin lọ́dún 2006. Bẹ́ẹ̀ náà, lótún wọlé lẹ́ẹ̀kan si lọ́dún nínú ìdìbò Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà lọ́dún 2011. Ní àkókò yìí, òun ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí Alága àjọ àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwò, African Union láti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 2012 sí ojo kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 2013.

Thomas Boni Yayi
Boni in 2012
7th President of Benin
In office
6 April 2006 – 6 April 2016
Alákóso ÀgbàPascal Koupaki
Lionel Zinsou
AsíwájúMathieu Kérékou
Arọ́pòPatrice Talon
Chairperson of the African Union
In office
29 January 2012 – 27 January 2013
AsíwájúTeodoro Obiang Nguema Mbasogo
Arọ́pòHailemariam Desalegn
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Thomas Yayi Boni

1 Oṣù Keje 1951 (1951-07-01) (ọmọ ọdún 72)
Tchaourou, Dahomey (now Benin)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúIndependent
(Àwọn) olólùfẹ́Chantal Boni Yayi
Àwọn ọmọ5
Alma materNational University of Benin
Cheikh Anta Diop University
University of Orléans
Paris Dauphine University

Ni Oṣu Kẹsan ọdun 2021, Patrice Talon ati Thomas Boni Yayi, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn olóṣèlú kẹ̀yìn sí ara wọn, tí wọ́n sì di ọ̀tá nítorí òṣèlú. Nígbà kan tí wọ́n pàdé nínú ààfin Marina ní Cotonou láti jíròrò ìtẹ̀síwájú ìlú wọn, ìmọ̀ wọn kò jọ rárá lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìṣèjọba, pàápàá jùlọ ọ̀rọ̀ lórí ìtúsílẹ̀ àwọn òṣèlú tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n.

Ìgbésí ayé rẹ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ àti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ilé-ìfowópamọ́

àtúnṣe
 
Raymond Gilpin, Mahamadou Issoufou, Alpha Conde, Tara Sonenshine, Alassane Ouattara, Boni Yayi, and David Smock in 2011

Wọ́n bí Thomas Boni Yayi ní àgbègbè Tchaourou, ní ìjọba-ìbílẹ̀ Borgou Department lápá ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Benin, tí a mọ̀ nígbà kan rí ní orílẹ̀ èdè Dahomey. Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ olú-ìlú àgbègbè náà, Parakou kí ó tó tẹ̀síwájú láti kàwé gboyè ìkejì nínú imọ̀ ètò ọ̀rọ̀-ajé ní National University of Benin.[1] Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti tún kàwé gboyè kejì òmíràn nínú imọ̀ imọ̀ ètò ọ̀rọ̀-ajé bákan náà ní Cheikh Anta Diop UniversityDakar, lórílẹ̀ èdè Senegal, ó kàwé gboyè dókítà nínú imọ̀ ètò ọ̀rọ̀-ajé àti òṣèlú ní University of Orléans, lórílẹ̀-èdè France àti ní Paris Dauphine University lọ́dún 1976.[1]

Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀, Boni ṣiṣẹ́ nílé ìfowópamọ́ fún ìgbà pípẹ́. Láti ọdún 1975 sí 1979, ó ṣiṣẹ́ ní Benin Commercial Bank kí ó tó dára pọ̀ mọ́ Central Bank of West African States (BCEAO) gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ láti ọdún 1977 sí 1989.[2] Láti ọdún 1992 sí 1994, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùgbaninímọ̀ràn sí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Benin lásìkò náà, Nicéphore Soglo. Lọ́dún 1994, ó fi ipò náà sílẹ̀ láti di Ààrẹ ilé-ìfowópamọ́ West African Development Bank (BOAD).[2]

Ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni ọjọ́ kẹfà oṣù kẹrin ọdún 2006. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n tú yáyá tú yàyà nínú ìdìbò náà tí gbogbo ènìyàn gbà pé kò sí àbòsí nínú rẹ̀.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Houngnikpo, Mathurin C.; Decalo, Samuel (2013). Historical Dictionary of Benin. Lanham, MD: Scarecrow Press. 
  2. 2.0 2.1 "The Presidency". Benin Embassy to the United States of America. Archived from the original on 13 December 2014. Retrieved 12 December 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Freedomhouse