Ẹkáàbọ̀! àtúnṣe

Ẹpẹ̀lẹ́ o, Mir koks,ẹkáàbọ̀ sí Yòrùbá Wikipedia!! Adúpẹ́ fún àfikún yín. Mo lérò wípé ẹ nífẹ́ sí kí ẹ wà níbí. Ẹwo àwọn oun tí a ṣètò sí ìsàlẹ̀ yìí bóyá ó lè wúlò fun yín:

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí fi òǹtẹ̀ tẹ oun tí ẹ bá kọ sí ọ̀rọ̀ ojú ewé pẹ̀lú igun mẹ́rin (~~~~); èyí máa gbé orúkọ yín àti déètì jáde. Bí ẹ bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ ẹ kàn sí mi, +/-, mo sì máa ràn yín lọ́wọ́, ẹkáàbọ̀!

Èsì ọ̀rọ̀ àtúnṣe

Ẹ nlẹ́ níbẹ̀ yẹn oníṣẹ́ Mir koks, inú mi dùn sí ìfẹ̀hónúhàn yín. N jẹ́ ẹ mọ̀ wípé iṣẹ́ yín kò fẹsẹ̀ múlẹ̀, bẹ̀ẹ́ ni kò sì bá ìlànà àkọtọ́ Yorùbá òde òní mu bí ó ti wù kí ó mọ. Oun tí a ń pè ní Ìwé Ìmò-ọ̀fẹ́ Yorùbá gbọ́dọ̀ dùn ún kà láì ní ìṣòro kan kan, àwọn àyọkà tí àwa oníṣẹ́ bá ń dá sílẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe àlékún ìmọ̀ àwọn ònkàwé ni, kìí ṣe kí ó ṣòro fún wọn láti kà rárá. Pèlú gbogbo àwọn àyọkà yín tí mo ti kà sẹ́yìn, ẹ ṣe àgbéyẹwò àwọn àyọkà yín tí ẹ ti kọ tẹ́lẹ̀ bóyá ó wà ní ìbámu pẹ̀lú wọn.

Ó jẹ́ ohun tí ó yà mí lẹ́nu láti rí ìṣọwọ́ kọ Yorùbá yín sí irí ìkanì yí, tí ó sì jẹ́ kí n máa rò wípé bóyá ni ẹ tilẹ̀ gbọ́ èdè Yorùbá rárá? Tàbí bóyá ni ẹ mọ̀ọ́ kọ bí ẹ bá tilẹ̀ gbọ́ èdè náà? Àbí ẹ̀yin kìí ka ohun tí ẹ bá kọ sílẹ̀ rárá ni? Ìṣọwọ́ kọ Yorùbá yí ń kọni lóminú gidi-gidi. Ẹ wo díẹ̀ lára iṣẹ́ yín kí ẹ lè fi mò wípé ìṣọwọ́ kọ̀wé yín kò dunjú rárá. Àpẹẹrẹ

  1. Bimbo Ademoye,
  2. Eniola Badmus,

Ẹ wo iṣẹ́ àti ìṣọwọ́ kọ̀wé àwọn oníṣẹ́ mìíràn sórí ìkanì yí. Àpẹẹrẹ:

  1. Fòpin sí SARS
  2. Samuel Akínsànyà àti
  3. Adéwálé Ẹlẹ́ṣọ̀ọ́.
Bí ẹ bá wo àwọn iṣẹ́ àwọn oníṣẹ́ yí sí àwọn iṣẹ́ tiyín lẹyọ kọ̀ọ̀kan, ẹ ó ri wípé ìṣọwọ́ kọ àyọkà yín kò bójú mu. Mi ò ṣìsọ rárá. 

Ẹ̀wẹ̀, a kò fẹ́ kí Olóòtú àgbà @T Cells: ó pa àwọn iṣẹ́ yín rẹ̀ láì jẹ́ kí ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni mo ṣe jẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ìgbéyẹ̀wò lórí iṣẹ́ yín àti ti ẹni kejì. N kò fẹ́ kí wàhálà yín ó já sófo ni. Yorùbá Wikipedia kìí ṣe àkìtàn. Agbalagba (ọ̀rọ̀) 07:23, 21 Oṣù Kẹ̀wá 2020 (UTC)Reply