Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Afijió

Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
(Àtúnjúwe láti Agbegbe Ijoba Ibile Afijio)

Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè ìjọb a ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní Nàìjíríà. Olú-ìlú rè wà ní Jobele.[1][2]

Afijio
Ese Oloja hill in ilora, Afijio LGA
Ese Oloja hill in ilora, Afijio LGA
Country Nigeria
StateOyo State
Government
 • Local Government Chairman and the Head of the Local Government CouncilSunday Akindele Ojo (PDP)
Population
 (2010)2010 estimated population size of 152,193 using a growth rate of 3.2% from 2006 census figures.
 • Total152,193
Time zoneUTC+1 (WAT)
WebsiteAfijio

Ó ní ìwọ̀n ilẹ̀ tó tó 722 km2 àti iye ènìyàn tó tó 134,173 ní ìka orí tó wáyé ní ọdún 2006.

Kóòdù ìfìwéránṣẹ́ ìlú náà ni 211.[3]

Ní ọdún 1989, ìjọba àpapọ̀ ológun ìgbà náà pinnu láti pín agbègbè ìjọba ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ìgbà náà sí ẹ̀ka, èyí ló sì bí agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio.

Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio tí jẹ́ dídásílẹ̀ nígbà mẹ́tà ọ̀tọ̀tọ̀. Wọ́n ṣèdásílẹ̀ Afijio Provisional Authority ní ọdún 1964. Ẹ̀kejì ní ọdún 1981, wọ́n sì da gbogbo agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ̀ pọ̀ ní oṣù May ọdún 1989, lábẹ́ orúkọ Afijio, èyí tó jẹ́ àékúrú tí orúkọ rẹ̀ ní kíkún jẹ́ Awe, Akinmoorin, Fiditi, Ilora, Imini, Jobele, Iware, Iluaje, Oluwatedo, àti Ojutaye, tí wọ́n jẹ́ ìlú ńlá tẹ́lẹ̀.[4]

Àwọn Yorùbá ló sábà máa ń ṣàkóso agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio, àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà mìírà wà ní ìlú náà, tí wọ́n ń gbé káàkiri ibẹ̀.[4] Ẹ̀sìn ìlú náà ní ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́ẹ̀nì àti Ìsìlámú. The indigenous peoples' primary religions are Christianity and Islam. Àwọn oníṣẹ̀ṣe ò sàìmá sì ní agbègbè náà, tí wọ́n sì ń ṣẹ̀sin wọn pẹ̀lú àlàáfíà.

Ètò ọrọ̀-ajé

àtúnṣe

Àwọn ọmọ ilú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ yìí mú iṣẹ́ àgbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò, wọ́n sì máa ń gbin àwọn ohun ọ̀gbìn bí i àgbàdo, iṣu, ẹ̀gẹ́, ẹ̀pà, èso, kòkó àti ẹyìn[5]

Ẹ̀ka-ìdìbò ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio

àtúnṣe

Alága kan ṣoṣo tí wọ́n yàn ló ń ṣàkóso agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ náà, tí àwọn káńṣẹ́lọ̀ mẹ́wàá sì ń ṣàkóso ẹ̀ka-ìdìbò mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó wà níbẹ̀.

Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio pín sí mẹ́wàá, àwọn ni: Ilora I, Ilora II, Ilora III, Fiditi I, Fiditi II, Aawe I, Aawe II, Akinmorin/Jobele, Iware àti Imini.

Àwọn ìlú tó gbajúgbajà ní Afijio

àtúnṣe
  • Aawe[6]
  • Fiditi
  • Ilora
  • Iware
  • Jobele
  • Ore lope

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Afijio Local Government Area". www.manpower.com.ng. Retrieved 2022-03-05. 
  2. "List of Local Government Areas (LGA), and City of Ibadan in Oyo State, Nigeria, Maps and Street Views, Geographic.org". geographic.org. Retrieved 2022-12-29. 
  3. "Post Offices- with map of LGA". NIPOST. Archived from the original on 7 October 2009. Retrieved 2009-10-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. 4.0 4.1 "Afijio Local Government – Oyo State Government" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-05. 
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :12
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02